< איוב 17 >
רוחי חבלה ימי נזעכו קברים לי | 1 |
“Ẹ̀mí mi bàjẹ́, ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú, isà òkú dúró dè mí.
אם-לא התלים עמדי ובהמרותם תלן עיני | 2 |
Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi, ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.
שימה-נא ערבני עמך מי הוא לידי יתקע | 3 |
“Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́; ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi?
כי-לבם צפנת משכל על-כן לא תרמם | 4 |
Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye; nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.
לחלק יגיד רעים ועיני בניו תכלנה | 5 |
Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.
והציגני למשל עמים ותפת לפנים אהיה | 6 |
“Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
ותכה מכעש עיני ויצרי כצל כלם | 7 |
Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́, gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
ישמו ישרים על-זאת ונקי על-חנף יתערר | 8 |
Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí, ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
ויאחז צדיק דרכו וטהר-ידים יסיף אמץ | 9 |
Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú, àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.
ואולם--כלם תשבו ובאו נא ולא-אמצא בכם חכם | 10 |
“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí; èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.
ימי עברו זמתי נתקו-- מורשי לבבי | 11 |
Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá, àní ìrò ọkàn mi.
לילה ליום ישימו אור קרוב מפני-חשך | 12 |
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
אם-אקוה שאול ביתי בחשך רפדתי יצועי (Sheol ) | 13 |
Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi; mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn. (Sheol )
לשחת קראתי אבי אתה אמי ואחתי לרמה | 14 |
Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi, àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
ואיה אפו תקותי ותקותי מי ישורנה | 15 |
ìrètí mi ha dà nísinsin yìí? Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
בדי שאל תרדנה אם-יחד על-עפר נחת (Sheol ) | 16 |
Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú, nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?” (Sheol )