< ירמיה 25 >
הדבר אשר היה על ירמיהו על כל עם יהודה בשנה הרבעית ליהויקים בן יאשיהו מלך יהודה היא השנה הראשנית לנבוכדראצר מלך בבל | 1 |
Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli.
אשר דבר ירמיהו הנביא על כל עם יהודה ואל כל ישבי ירושלם לאמר | 2 |
Nítorí náà, Jeremiah wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti sí àwọn olùgbé Jerusalẹmu.
מן שלש עשרה שנה ליאשיהו בן אמון מלך יהודה ועד היום הזה זה שלש ועשרים שנה היה דבר יהוה אלי ואדבר אליכם אשכים ודבר ולא שמעתם | 3 |
Fún odidi ọdún mẹ́tàlélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.
ושלח יהוה אליכם את כל עבדיו הנבאים השכם ושלח--ולא שמעתם ולא הטיתם את אזנכם לשמע | 4 |
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.
לאמר שובו נא איש מדרכו הרעה ומרע מעלליכם ושבו על האדמה אשר נתן יהוה לכם ולאבותיכם--למן עולם ועד עולם | 5 |
Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Olúwa fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé.
ואל תלכו אחרי אלהים אחרים לעבדם ולהשתחות להם ולא תכעיסו אותי במעשה ידיכם ולא ארע לכם | 6 |
Má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”
ולא שמעתם אלי נאם יהוה למען הכעסוני (הכעיסני) במעשה ידיכם לרע לכם | 7 |
“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.”
לכן כה אמר יהוה צבאות יען אשר לא שמעתם את דברי | 8 |
Nítorí náà, Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,
הנני שלח ולקחתי את כל משפחות צפון נאם יהוה ואל נבוכדראצר מלך בבל עבדי והבאתים על הארץ הזאת ועל ישביה ועל כל הגוים האלה סביב והחרמתים--ושמתים לשמה ולשרקה ולחרבות עולם | 9 |
Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé.
והאבדתי מהם קול ששון וקול שמחה קול חתן וקול כלה--קול רחים ואור נר | 10 |
Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà.
והיתה כל הארץ הזאת לחרבה לשמה ועבדו הגוים האלה את מלך בבל--שבעים שנה | 11 |
Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.
והיה כמלאות שבעים שנה אפקד על מלך בבל ועל הגוי ההוא נאם יהוה את עונם--ועל ארץ כשדים ושמתי אתו לשממות עולם | 12 |
“Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé, Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Babeli àti orílẹ̀-èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Babeli nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé.
והבאותי (והבאתי) על הארץ ההיא את כל דברי אשר דברתי עליה--את כל הכתוב בספר הזה אשר נבא ירמיהו על כל הגוים | 13 |
Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ àní gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremiah ti sọtẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè.
כי עבדו בם גם המה גוים רבים ומלכים גדולים ושלמתי להם כפעלם וכמעשה ידיהם | 14 |
Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀-èdè púpọ̀ àti àwọn ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”
כי כה אמר יהוה אלהי ישראל אלי קח את כוס היין החמה הזאת מידי והשקיתה אתו את כל הגוים אשר אנכי שלח אותך אליהם | 15 |
Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí fún mi: “Gba ago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mo rán ọ sí mu ún.
ושתו והתגעשו והתהללו מפני החרב אשר אנכי שלח בינתם | 16 |
Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí yóò ránṣẹ́ sí àárín wọn.”
ואקח את הכוס מיד יהוה ואשקה את כל הגוים אשר שלחני יהוה אליהם | 17 |
Mo sì gba ago náà lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó rán mi sí mu ún.
את ירושלם ואת ערי יהודה ואת מלכיה את שריה לתת אתם לחרבה לשמה לשרקה ולקללה--כיום הזה | 18 |
Jerusalẹmu àti àwọn ìlú Juda, àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.
את פרעה מלך מצרים ואת עבדיו ואת שריו ואת כל עמו | 19 |
Farao ọba Ejibiti, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
ואת כל הערב ואת כל מלכי ארץ העוץ ואת כל מלכי ארץ פלשתים ואת אשקלון ואת עזה ואת עקרון ואת שארית אשדוד | 20 |
Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjèjì tí ó wà níbẹ̀; gbogbo àwọn ọba Usi, gbogbo àwọn ọba Filistini, gbogbo àwọn ti Aṣkeloni, Gasa, Ekroni àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Aṣdodu.
את אדום ואת מואב ואת בני עמון | 21 |
Edomu, Moabu àti Ammoni;
ואת כל מלכי צר ואת כל מלכי צידון ואת מלכי האי אשר בעבר הים | 22 |
gbogbo àwọn ọba Tire àti Sidoni; gbogbo àwọn ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá Òkun.
ואת דדן ואת תימא ואת בוז ואת כל קצוצי פאה | 23 |
Dedani, Tema, Busi àti gbogbo àwọn tí ń gbé lọ́nà jíjìn réré.
ואת כל מלכי ערב ואת כל מלכי הערב השכנים במדבר | 24 |
Gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn ọba àwọn àjèjì ènìyàn tí ń gbé inú aginjù.
ואת כל מלכי זמרי ואת כל מלכי עילם ואת כל מלכי מדי | 25 |
Gbogbo àwọn ọba Simri, Elamu àti Media.
ואת כל מלכי הצפון הקרבים והרחקים איש אל אחיו ואת כל הממלכות הארץ אשר על פני האדמה ומלך ששך ישתה אחריהם | 26 |
Àti gbogbo àwọn ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jíjìn, ẹnìkínní lẹ́yìn ẹnìkejì; gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé. Àti gbogbo wọn, ọba Ṣeṣaki náà yóò sì mu.
ואמרת אליהם כה אמר יהוה צבאות אלהי ישראל שתו ושכרו וקיו ונפלו ולא תקומו--מפני החרב אשר אנכי שלח ביניכם | 27 |
“Nígbà náà, sọ fún wọn, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí. Mu, kí o sì mú àmuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárín yín.
והיה כי ימאנו לקחת הכוס מידך--לשתות ואמרת אליהם כה אמר יהוה צבאות--שתו תשתו | 28 |
Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba ago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún!
כי הנה בעיר אשר נקרא שמי עליה אנכי מחל להרע ואתם הנקה תנקו לא תנקו--כי חרב אני קרא על כל ישבי הארץ נאם יהוה צבאות | 29 |
Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’
ואתה תנבא אליהם את כל הדברים האלה ואמרת אליהם יהוה ממרום ישאג וממעון קדשו יתן קולו--שאג ישאג על נוהו הידד כדרכים יענה אל כל ישבי הארץ | 30 |
“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn: “‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá, yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà. Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí.
בא שאון עד קצה הארץ--כי ריב ליהוה בגוים נשפט הוא לכל בשר הרשעים נתנם לחרב נאם יהוה | 31 |
Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé, nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí àwọn orílẹ̀-èdè náà, yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn, yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’” ni Olúwa wí.
כה אמר יהוה צבאות הנה רעה יצאת מגוי אל גוי וסער גדול יעור מירכתי ארץ | 32 |
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn; ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”
והיו חללי יהוה ביום ההוא מקצה הארץ ועד קצה הארץ לא יספדו ולא יאספו ולא יקברו--לדמן על פני האדמה יהיו | 33 |
Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.
הילילו הרעים וזעקו והתפלשו אדירי הצאן--כי מלאו ימיכם לטבוח ותפוצותיכם ונפלתם ככלי חמדה | 34 |
Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn, ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran. Nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé, ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye.
ואבד מנוס מן הרעים ופליטה מאדירי הצאן | 35 |
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yóò rí ibi sálọ kì yóò sì ṣí àsálà fún olórí agbo ẹran.
קול צעקת הרעים ויללת אדירי הצאן--כי שדד יהוה את מרעיתם | 36 |
Gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn, àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí agbo ẹran; nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run.
ונדמו נאות השלום מפני חרון אף יהוה | 37 |
Ibùgbé àlàáfíà yóò di ahoro, nítorí ìbínú ńlá Olúwa.
עזב ככפיר סכו--כי היתה ארצם לשמה מפני חרון היונה ומפני חרון אפו | 38 |
Gẹ́gẹ́ bí kìnnìún yóò fi ibùba rẹ̀ sílẹ̀, ilẹ̀ wọn yóò sì di ahoro, nítorí idà àwọn aninilára, àti nítorí ìbínú ńlá Olúwa.