< אסתר 10 >

וישם המלך אחשרש (אחשורש) מס על הארץ ואיי הים 1
Ọba Ahaswerusi sì fi owó ọba lélẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ọba, dé erékùṣù òkun.
וכל מעשה תקפו וגבורתו ופרשת גדלת מרדכי אשר גדלו המלך--הלוא הם כתובים על ספר דברי הימים למלכי מדי ופרס 2
Gbogbo ìṣe agbára àti títóbi rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìròyìn títóbi Mordekai ní èyí tí ọba ti gbé e ga, kò ha wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ọdọọdún ọba ti Media àti ti Persia?
כי מרדכי היהודי משנה למלך אחשורוש וגדול ליהודים ורצוי לרב אחיו--דרש טוב לעמו ודבר שלום לכל זרעו 3
Mordekai ará Júù ni ó jẹ́ igbákejì ọba Ahaswerusi, ó tóbi láàrín àwọn Júù, ó sì jẹ́ ẹni iyì lọ́dọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, nítorí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ìre àwọn ènìyàn an rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ fún àlàáfíà gbogbo àwọn Júù.

< אסתר 10 >