< דברי הימים ב 12 >
ויהי כהכין מלכות רחבעם וכחזקתו עזב את תורת יהוה וכל ישראל עמו | 1 |
Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ìjọba Rehoboamu múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba, tí ó sì ti di alágbára, òun àti gbogbo Israẹli, pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n pa òfin Olúwa tì.
ויהי בשנה החמישית למלך רחבעם עלה שישק מלך מצרים על ירושלם כי מעלו ביהוה | 2 |
Nítorí tí wọn kò ṣọ òtítọ́ sí Olúwa. Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu ní ọdún karùn-ún ti ọba Rehoboamu.
באלף ומאתים רכב ובששים אלף פרשים ואין מספר לעם אשר באו עמו ממצרים--לובים סכיים וכושים | 3 |
Pẹ̀lú ẹgbàá mẹ́fà kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Libia, Sukki àti Kuṣi, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Ejibiti.
וילכד את ערי המצרות אשר ליהודה ויבא עד ירושלם | 4 |
Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Juda, pẹ̀lú wá sí Jerusalẹmu bí ó ti jìnnà tó.
ושמעיה הנביא בא אל רחבעם ושרי יהודה אשר נאספו אל ירושלם מפני שישק ויאמר להם כה אמר יהוה אתם עזבתם אתי ואף אני עזבתי אתכם ביד שישק | 5 |
Nígbà náà, wòlíì Ṣemaiah wá sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Juda tí wọ́n ti péjọ ní Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù Ṣiṣaki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣiṣaki.”
ויכנעו שרי ישראל והמלך ויאמרו צדיק יהוה | 6 |
Àwọn olórí Israẹli àti ọba rẹ̀ ará wọn sílẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Olódodo ni Olúwa.”
ובראות יהוה כי נכנעו היה דבר יהוה אל שמעיה לאמר נכנעו לא אשחיתם ונתתי להם כמעט לפליטה ולא תתך חמתי בירושלם ביד שישק | 7 |
Nígbà tí Olúwa rí i pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa yí tọ Ṣemaiah lọ pé, “Níwọ́n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jerusalẹmu ní ipasẹ̀ Ṣiṣaki.
כי יהיו לו לעבדים וידעו עבודתי ועבודת ממלכות הארצות | 8 |
Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàrín sí sìn mí àti sí sin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn.”
ויעל שישק מלך מצרים על ירושלם ויקח את אצרות בית יהוה ואת אצרות בית המלך את הכל לקח ויקח את מגני הזהב אשר עשה שלמה | 9 |
Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá.
ויעש המלך רחבעם תחתיהם מגני נחשת והפקיד על יד שרי הרצים השמרים פתח בית המלך | 10 |
Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Rehoboamu dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùṣọ́ tí ó wà ní ẹnu iṣẹ́ ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́.
ויהי מדי בוא המלך בית יהוה באו הרצים ונשאום והשבום אל תא הרצים | 11 |
Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé Olúwa, àwọn olùṣọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn àpáta náà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́.
ובהכנעו שב ממנו אף יהוה ולא להשחית לכלה וגם ביהודה היה דברים טובים | 12 |
Nítorí ti Rehoboamu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú Olúwa yí padà kúrò lórí rẹ̀, a kò sì pa á run pátápátá. Nítòótọ́, ìre díẹ̀ wà ní Juda.
ויתחזק המלך רחבעם בירושלם--וימלך כי בן ארבעים ואחת שנה רחבעם במלכו ושבע עשרה שנה מלך בירושלם העיר אשר בחר יהוה לשום את שמו שם מכל שבטי ישראל ושם אמו נעמה העמנית | 13 |
Ọba Rehoboamu fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi ní Jerusalẹmu, ó sì tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí Olúwa ti yàn jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli ní èyí tí ó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Ammoni.
ויעש הרע כי לא הכין לבו לדרוש את יהוה | 14 |
O sì ṣe búburú, nítorí tí kò múra nínú ọkàn rẹ̀ láti wá Olúwa.
ודברי רחבעם הראשנים והאחרונים--הלא הם כתובים בדברי שמעיה הנביא ועדו החזה להתיחש ומלחמות רחבעם וירבעם כל הימים | 15 |
Fún tí iṣẹ́ ìjọba Rehoboamu láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Ṣemaiah wòlíì àti ti Iddo, aríran tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá? Ìtẹ̀síwájú ogun jíjà sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu.
וישכב רחבעם עם אבתיו ויקבר בעיר דויד וימלך אביה בנו תחתיו | 16 |
Rehoboamu sun pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sin ín sínú ìlú ńlá ti Dafidi. Abijah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.