< דברי הימים א 8 >

ובנימן--הוליד את בלע בכרו אשבל השני ואחרח השלישי 1
Benjamini jẹ́ baba: Bela àkọ́bí rẹ̀, Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,
נוחה הרביעי ורפא החמישי 2
Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀karùnún.
ויהיו בנים לבלע--אדר וגרא ואביהוד 3
Àwọn ọmọ Bela ni, Adari, Gera, Abihudi,
ואבישוע ונעמן ואחוח 4
Abiṣua, Naamani, Ahoa,
וגרא ושפופן וחורם 5
Gera, Ṣefufani àti Huramu.
ואלה בני אחוד אלה הם ראשי אבות ליושבי גבע ויגלום אל מנחת 6
Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:
ונעמן ואחיה וגרא הוא הגלם והוליד את עזא ואת אחיחד 7
Naamani Ahijah àti Gera, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Ussa àti Ahihudu.
ושחרים הוליד בשדה מואב מן שלחו אתם--חושים ואת בערא נשיו 8
A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣaharaimu ní Moabu lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, Huṣimu àti Baara.
ויולד מן חדש אשתו--את יובב ואת צביא ואת מישא ואת מלכם 9
Nípasẹ̀ ìyàwó rẹ̀ Hodeṣi ó ní Jobabu Sibia, Meṣa, Malkamu,
ואת יעוץ ואת שכיה ואת מרמה אלה בניו ראשי אבות 10
Jeusi, Sakia àti Mirma. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.
ומחשים הוליד את אביטוב ואת אלפעל 11
Nípasẹ̀ Huṣimu ó ní Abitubu àti Elipali.
ובני אלפעל עבר ומשעם ושמד הוא בנה את אונו ואת לד ובנתיה 12
Àwọn ọmọ Elipali: Eberi, Miṣamu, Ṣemedu (ẹni tí ó kọ́ Ono àti Lodi pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká rẹ̀.)
וברעה ושמע--המה ראשי האבות ליושבי אילון המה הבריחו את יושבי גת 13
Pẹ̀lú Beriah àti Ṣema, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Aijaloni àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gati kúrò.
ואחיו ששק וירמות 14
Ahio, Ṣasaki, Jeremoti,
וזבדיה וערד ועדר 15
Sebadiah, Aradi, Ederi
ומיכאל וישפה ויוחא בני בריעה 16
Mikaeli, Iṣifa àti Joha jẹ́ àwọn ọmọ Beriah.
וזבדיה ומשלם וחזקי וחבר 17
Sebadiah, Meṣullamu, Hiski, Heberi
וישמרי ויזליאה ויובב בני אלפעל 18
Iṣimerai, Isiliahi àti Jobabu jẹ́ àwọn ọmọ Elipali.
ויקים וזכרי וזבדי 19
Jakimu, Sikri, Sabdi,
ואליעיני וצלתי ואליאל 20
Elienai, Siletai, Elieli,
ועדיה ובראיה ושמרת בני שמעי 21
Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei.
וישפן ועבר ואליאל 22
Iṣipani Eberi, Elieli,
ועבדון וזכרי וחנן 23
Abdoni, Sikri, Hanani,
וחנניה ועילם וענתתיה 24
Hananiah, Elamu, Anitotijah,
ויפדיה ופניאל (ופנואל) בני ששק 25
Ifediah àti Penueli jẹ́ àwọn ọmọ Ṣasaki.
ושמשרי ושחריה ועתליה 26
Ṣamṣerai, Ṣeharaiah, Ataliah
ויערשיה ואליה וזכרי בני ירחם 27
Jareṣiah, Elijah àti Sikri jẹ́ àwọn ọmọ Jerohamu.
אלה ראשי אבות לתלדותם ראשים אלה ישבו בירושלם 28
Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.
ובגבעון ישבו אבי גבעון ושם אשתו מעכה 29
Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka,
ובנו הבכור עבדון וצור וקיש ובעל ונדב 30
àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu,
וגדור ואחיו וזכר 31
Gedori Ahio, Sekeri
ומקלות הוליד את שמאה ואף המה נגד אחיהם ישבו בירושלם--עם אחיהם 32
pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.
ונר הוליד את קיש וקיש הוליד את שאול ושאול הוליד את יהונתן ואת מלכישוע ואת אבינדב ואת אשבעל 33
Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.
ובן יהונתן מריב בעל ומריב בעל הוליד את מיכה 34
Ọmọ Jonatani: Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika.
ובני מיכה--פיתון ומלך ותארע ואחז 35
Àwọn ọmọ Mika: Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi.
ואחז הוליד את יהועדה ויהועדה הוליד את עלמת ואת עזמות ואת זמרי וזמרי הוליד את מוצא 36
Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa.
ומוצא הוליד את בנעא רפה בנו אלעשה בנו אצל בנו 37
Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.
ולאצל ששה בנים--ואלה שמותם עזריקם בכרו וישמעאל ושעריה ועבדיה וחנן כל אלה בני אצל 38
Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn: Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Obadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.
ובני עשק אחיו אולם בכרו--יעוש השני ואליפלט השלשי 39
Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Eseki: Ulamu àkọ́bí rẹ̀, Jeuṣi ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Elifeleti ẹ̀ẹ̀kẹ́ta.
ויהיו בני אולם אנשים גבורי חיל דרכי קשת ומרבים בנים ובני בנים--מאה וחמשים כל אלה מבני בנימן 40
Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin áàdọ́jọ ní gbogbo rẹ̀. Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Benjamini.

< דברי הימים א 8 >