< Ἰώβ 29 >
1 ἔτι δὲ προσθεὶς Ιωβ εἶπεν τῷ προοιμίῳ
Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé,
2 τίς ἄν με θείη κατὰ μῆνα ἔμπροσθεν ἡμερῶν ὧν με ὁ θεὸς ἐφύλαξεν
“Háà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pa mí mọ́,
3 ὡς ὅτε ηὔγει ὁ λύχνος αὐτοῦ ὑπὲρ κεφαλῆς μου ὅτε τῷ φωτὶ αὐτοῦ ἐπορευόμην ἐν σκότει
nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí, àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já.
4 ὅτε ἤμην ἐπιβρίθων ὁδοῖς ὅτε ὁ θεὸς ἐπισκοπὴν ἐποιεῖτο τοῦ οἴκου μου
Bí mo ti rí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi,
5 ὅτε ἤμην ὑλώδης λίαν κύκλῳ δέ μου οἱ παῖδες
nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi, nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;
6 ὅτε ἐχέοντό μου αἱ ὁδοὶ βουτύρῳ τὰ δὲ ὄρη μου ἐχέοντο γάλακτι
nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi, àti tí àpáta ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá.
7 ὅτε ἐξεπορευόμην ὄρθριος ἐν πόλει ἐν δὲ πλατείαις ἐτίθετό μου ὁ δίφρος
“Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,
8 ἰδόντες με νεανίσκοι ἐκρύβησαν πρεσβῦται δὲ πάντες ἔστησαν
nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi, wọ́n sì sá pamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹsẹ̀ wọn,
9 ἁδροὶ δὲ ἐπαύσαντο λαλοῦντες δάκτυλον ἐπιθέντες ἐπὶ στόματι
àwọn ọmọ-aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, wọn a sì fi ọwọ́ wọn lé ẹnu.
10 οἱ δὲ ἀκούσαντες ἐμακάρισάν με καὶ γλῶσσα αὐτῶν τῷ λάρυγγι αὐτῶν ἐκολλήθη
Àwọn ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọn sì lẹ̀ mọ́ èrìgì ẹnu wọn.
11 ὅτι οὖς ἤκουσεν καὶ ἐμακάρισέν με ὀφθαλμὸς δὲ ἰδών με ἐξέκλινεν
Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi, àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi,
12 διέσωσα γὰρ πτωχὸν ἐκ χειρὸς δυνάστου καὶ ὀρφανῷ ᾧ οὐκ ἦν βοηθός ἐβοήθησα
nítorí mo gbà tálákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́, àti aláìní baba tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un.
13 εὐλογία ἀπολλυμένου ἐπ’ ἐμὲ ἔλθοι στόμα δὲ χήρας με εὐλόγησεν
Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.
14 δικαιοσύνην δὲ ἐνεδεδύκειν ἠμφιασάμην δὲ κρίμα ἴσα διπλοΐδι
Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́ mi dàbí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.
15 ὀφθαλμὸς ἤμην τυφλῶν ποὺς δὲ χωλῶν
Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹsẹ̀ fún amúnkùn ún.
16 ἐγὼ ἤμην πατὴρ ἀδυνάτων δίκην δέ ἣν οὐκ ᾔδειν ἐξιχνίασα
Mo ṣe baba fún tálákà; mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí.
17 συνέτριψα δὲ μύλας ἀδίκων ἐκ δὲ μέσου τῶν ὀδόντων αὐτῶν ἅρπαγμα ἐξέσπασα
Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ènìyàn búburú, mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.
18 εἶπα δέ ἡ ἡλικία μου γηράσει ὥσπερ στέλεχος φοίνικος πολὺν χρόνον βιώσω
“Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóò kú nínú ilé mi, èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí iyanrìn.
19 ἡ ῥίζα μου διήνοικται ἐπὶ ὕδατος καὶ δρόσος αὐλισθήσεται ἐν τῷ θερισμῷ μου
Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi, ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.
20 ἡ δόξα μου καινὴ μετ’ ἐμοῦ καὶ τὸ τόξον μου ἐν χειρὶ αὐτοῦ πορεύσεται
Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀ mi, ọrun mi sì padà di tuntun ní ọwọ́ mi.’
21 ἐμοῦ ἀκούσαντες προσέσχον ἐσιώπησαν δὲ ἐπὶ τῇ ἐμῇ βουλῇ
“Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí, wọn a sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.
22 ἐπὶ δὲ τῷ ἐμῷ ῥήματι οὐ προσέθεντο περιχαρεῖς δὲ ἐγίνοντο ὁπόταν αὐτοῖς ἐλάλουν
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀ mọ́; ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.
23 ὥσπερ γῆ διψῶσα προσδεχομένη τὸν ὑετόν οὕτως οὗτοι τὴν ἐμὴν λαλιάν
Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò; wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀kúrò.
24 ἐὰν γελάσω πρὸς αὐτούς οὐ μὴ πιστεύσωσιν καὶ φῶς τοῦ προσώπου μου οὐκ ἀπέπιπτεν
Èmi sì rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn kò bá gbà á gbọ́; ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye sí wọn.
25 ἐξελεξάμην ὁδὸν αὐτῶν καὶ ἐκάθισα ἄρχων καὶ κατεσκήνουν ὡσεὶ βασιλεὺς ἐν μονοζώνοις ὃν τρόπον παθεινοὺς παρακαλῶν
Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sì jókòó bí olóyè wọn. Mo jókòó bí ọba ní àárín ológun rẹ, mo sì rí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.