< Sprueche 26 >

1 Wie der Schnee zum Sommer und der Regen zur Ernte, so wenig paßt Ehre für den Narren.
Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.
2 Wie ein Sperling davonflattert und eine Schwalbe wegfliegt, so ein unverdienter Fluch: er trifft nicht ein.
Bí ológoṣẹ́ tí ń ṣí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rábàbà èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.
3 Dem Pferd eine Geißel, dem Esel ein Zaum und dem Narren eine Rute auf den Rücken!
Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.
4 Antworte dem Narren nicht nach seiner Narrheit, damit du ihm nicht gleichest;
Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.
5 antworte aber dem Narren nach seiner Narrheit, damit er sich nicht weise dünke.
Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.
6 Es haut sich die Füße ab und muß Ärger schlucken, wer seine Sachen durch einen Narren besorgen läßt.
Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè.
7 Schwach wie die Beine des Lahmen, so ist ein [weiser] Spruch im Munde des Toren.
Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè.
8 Wie wenn man einen Stein in der Schleuder festbindet, so ist's, wenn man einem Toren Ehre erweist.
Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá.
9 Ein Dorn geriet in die Hand eines Trunkenen und ein Spruch in den Mund der Toren!
Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.
10 Ein Händelsüchtiger verletzt alle und nimmt Toren und Landstreicher in seinen Sold.
Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.
11 Wie ein Hund, der zu seinem Gespei zurückkehrt, so ist ein Narr, der seine Dummheit wiederholt.
Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
12 Siehst du einen Mann, der sich selbst weise dünkt, so kannst du für einen Toren mehr Hoffnung haben als für ihn!
Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀? Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.
13 Der Faule spricht: «Es ist ein Löwe draußen, ein Leu ist mitten auf der Straße!»
Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”
14 Die Tür dreht sich in der Angel und der Faule in seinem Bett.
Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.
15 Der Faule steckt seine Hand in die Schüssel; er bringt sie kaum mehr zum Mund zurück!
Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ, ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
16 Ein Fauler dünkt sich weiser als sieben, die verständige Antworten geben.
Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀, ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.
17 Es packt einen vorüberlaufenden Hund bei den Ohren, wer sich in einen Streit mischt, der ihn nichts angeht.
Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.
18 Wie ein Wahnsinniger, der feurige und todbringende Pfeile abschießt,
Bí i asínwín ti ń ju ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni
19 so ist ein Mensch, der seinen Nächsten betrügt und dann spricht: «Ich habe nur gescherzt!»
ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”
20 Wo kein Holz mehr ist, erlischt das Feuer; und wenn der Verleumder fort ist, so hört der Hader auf.
Láìsí igi, iná yóò kú láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.
21 Zur Glut braucht es Kohlen und zum Feuer Holz, und um Streit anzufangen, einen zänkischen Mann.
Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.
22 Die Worte des Verleumders sind wie Leckerbissen; sie dringen ins Innerste des Leibes.
Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
23 Silberschaum über Scherben gezogen, also sind feurige Lippen und ein böses Herz.
Ètè jíjóni, àti àyà búburú, dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò.
24 Mit seinen Lippen verstellt sich der Hasser, und in seinem Herzen nimmt er sich Betrügereien vor.
Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.
25 Wenn er schöne Worte macht, so traue ihm nicht; denn es sind sieben Greuel in seinem Herzen.
Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́ nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.
26 Hüllt sich der Haß in Täuschung, so wird seine Bosheit doch offenbar in der Gemeinde.
Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.
27 Wer [andern] eine Grube gräbt, fällt selbst hinein; und wer einen Stein wälzt, zu dem kehrt er zurück.
Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀. Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.
28 Eine Lügenzunge haßt die von ihr Zermalmten, und ein glattes Maul richtet Verderben an.
Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà, ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.

< Sprueche 26 >