< 1 Chronik 23 >

1 Als David alt und lebenssatt geworden war, bestellte er seinen Sohn Salomo zum König über Israel.
Nígbà tí Dafidi sì dàgbà, tí ó sì di arúgbó, ó sì fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lórí Israẹli.
2 Er versammelte alle Fürsten Israels, ebenso die Priester und die Leviten.
Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi.
3 Und die Leviten wurden von dreißig Jahren an und darüber gezählt. Ihre Kopfzahl war 38.000 Mann.
Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún.
4 "Von diesen sollen 24.000 der Arbeit am Hause des Herrn vorstehen und 6.000 Amtleute und Richter sein!
Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá méjìlá ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́.
5 4.000 seien Torhüter, und 4.000 sollen den Herrn mit den Spielgeräten preisen, die ich zum Lobpreis mache!"
Ẹgbàajì ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí.
6 David teilte sie in Abteilungen nach den Levisöhnen Gerson, Kehat und Merari.
Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
7 Zu den Gersoniten gehörten Ladan und Simei.
Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni: Laadani àti Ṣimei.
8 Ladans Söhne sind das Oberhaupt Jechiel, Zetam und Joel, drei.
Àwọn ọmọ Laadani Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joẹli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.
9 Simeis Söhne sind Selomit, Chaziel und Haran, drei. Diese sind die Familienhäupter Ladans.
Àwọn ọmọ Ṣimei: Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn. Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.
10 Simeis Söhne waren auch Jachat, Zina, Jëus und Beria. Dies sind die Söhne Simeis, vier.
Àti ọmọ Ṣimei: Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.
11 Jachat war das Oberhaupt und Zina der zweite. Jëus aber und Beria hatten nur wenig Kinder, so daß sie bloß eine Familie, eine Amtsklasse bildeten.
Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.
12 Kehats Söhne sind Amram, Ishar, Chebron und Uzziel, vier.
Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn.
13 Amrams Söhne sind Aaron und Moses. Aaron aber wurde ausgesondert, um für immer hochheilig geweiht zu sein, er und seine Söhne, damit sie beständig vor dem Herrn räucherten, ihm dienten und mit seinem Namen segneten.
Àwọn ọmọ Amramu. Aaroni àti Mose. A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé.
14 Moses aber war der Mann Gottes. Seine Söhne wurden zum Levitenstamm gerechnet.
Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi.
15 Mosis Söhne sind Gersom und Eliezer.
Àwọn ọmọ Mose: Gerṣomu àti Elieseri.
16 Gersoms Söhne sind: das Oberhaupt Sebuel.
Àwọn ọmọ Gerṣomu: Ṣubaeli sì ni alákọ́kọ́.
17 Eliezers Söhne sind: das Oberhaupt Rechabja; andere Söhne hatte Eliezer nicht. Dagegen waren Rechabjas Söhne überaus zahlreich.
Àwọn ọmọ Elieseri: Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́. Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.
18 Ishars Söhne sind: das Oberhaupt Selomit.
Àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.
19 Chebrons Söhne sind: das Oberhaupt Jeriahu, Amarja, der zweite, Jachaziel, der dritte, und Jekamam, der vierte.
Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.
20 Uzziels Söhne sind das Oberhaupt Mika und Isia, der zweite,
Àwọn ọmọ Usieli: Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.
21 Meraris Söhne sind Machli und Musi. Machlis Söhne sind Eleazar und Kis.
Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Mahili: Eleasari àti Kiṣi.
22 Eleazar starb, ohne Söhne zu hinterlassen. Er hatte nur Töchter. Diese heirateten die Söhne des Kis.
Eleasari sì kú pẹ̀lú àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.
23 Musis Söhne sind Machli, Eder und Jeremot, drei.
Àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Dies sind Levis Söhne nach ihren Familien, die Familienhäupter nach ihrer Musterung, nach der Zahl der Namen, Kopf für Kopf, die beim Dienste am Hause des Herrn beschäftigt waren, von zwanzig Jahren und darüber.
Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.
25 Denn David sprach: "Der Herr, Israels Gott, hat seinem Volke Ruhe verliehen und wohnt in Jerusalem für alle Zeiten."
Nítorí pé Dafidi ti sọ pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé,
26 So brauchten auch die Leviten die Wohnung nicht mehr zu tragen und keines der zu ihrem Dienst erforderlichen Geräte.
àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀.”
27 Denn nach Davids letzten Befehlen wurde die Zahl der Levisöhne von den Zwanzigjährigen an berechnet.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
28 Ihre Amtspflicht bestand in der Unterstützung der Aaronssöhne beim Dienst im Hause des Herrn, als Aufseher über die Vorhöfe und Zellen und über die Reinigung alles Heiligen sowie in den Dienstverrichtungen am Gotteshause,
Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.
29 ferner in der Besorgung der reihenweise aufgelegten Brote, des Feinmehls zum Speiseopfer und der ungesäuerten Fladen, der Pfanne und des Eingerührten, eines jeden Hohl- und Längenmaßes,
Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òsùwọ̀n.
30 ferner darin, daß sie jeden Morgen hintraten, dem Herrn zu danken und ihn zu preisen, ebenso am Abend,
Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́.
31 und bei jeder Darbringung von Brandopfern für den Herrn an den Sabbaten, Neumonden und Festen, soviel ihrer nach Vorschrift beständig vor dem Herrn darzubringen waren.
Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.
32 So sollten sie die Geschäfte am Bundeszelt tun und die Geschäfte am Heiligtum, ferner die Geschäfte bei ihren Brüdern, den Aaronssöhnen, während des Dienstes am Hause des Herrn.
Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún Ibi Mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.

< 1 Chronik 23 >