< Lévitique 21 >

1 Le Seigneur dit aussi à Moïse: Parle aux prêtres, fils d’Aaron, et tu leur diras: Qu’un prêtre ne se souille point à la mort de ses concitoyens;
Olúwa sọ fún Mose wí pe, “Bá àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí àwọn ènìyàn wọn tí ó kù.
2 Or, il s’y souillera, à moins qu’il ne s’agisse seulement de ses consanguins et de ses proches, c’est-à-dire, de son père et de sa mère, de son fils et de sa fille, de son frère,
Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe àwọn tí ó súnmọ́ ọn bí ìyá rẹ̀, baba rẹ̀, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin, àti arákùnrin rẹ̀.
3 Et de sa sœur vierge, qui n’a pas été mariée à un homme;
Tàbí fún arábìnrin rẹ̀ tí kò ì tí ì wọ ilé ọkọ tí ó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí tí arábìnrin bẹ́ẹ̀, ó lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.
4 Mais il ne se souillera pas non plus pour le prince de son peuple.
Nítorí tí ó jẹ́ olórí, òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
5 Ils ne raseront point leur tête, ni leur barbe, et dans leur chair ils ne feront point d’incisions.
“‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irùngbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.
6 Ils seront saints pour leur Dieu et ils ne souilleront point son nom; car ils offrent l’holocauste du Seigneur, et les pains de leur Dieu, et c’est pour cela qu’ils seront saints.
Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.
7 Ils n’épouseront point une femme déshonorée et une fille prostituée, ni celle qui a été répudiée par son mari; parce qu’ils sont consacrés à leur Dieu,
“‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn.
8 Et qu’ils offrent les pains de proposition. Qu’ils soient donc saints, parce que je suis saint, moi aussi, le Seigneur qui les sanctifie.
Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.
9 Si la fille d’un prêtre est surprise en fornication et qu’elle ait déshonoré le nom de son père, elle sera complètement brûlée par les flammes.
“‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà kan bá fi iṣẹ́ àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ó dójútì baba rẹ̀, iná ni a ó dá sun ún.
10 Le pontife, c’est-à-dire, le grand-prêtre parmi ses frères, sur la tête duquel l’huile de l’onction a été répandue, dont les mains ont été consacrées à son sacerdoce et qui est revêtu des saints vêtements, ne découvrira point sa tête et ne déchirera point ses vêtements:
“‘Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, tí a sì ti fi àmì òróró yàn án láti máa wọ aṣọ àlùfáà, ó gbọdọ̀ tọ́jú irun orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.
11 Et il n’entrera absolument auprès d’aucun mort: pour son père même et pour sa mère il ne se souillera point.
Kí ó ma ṣe wọlé tọ òkú lọ, kí ó má ṣe sọ ará rẹ di àìmọ́ nítorí baba tàbí nítorí ìyá rẹ̀.
12 Une sortira point des lieux saints, afin qu’il ne souille pas le sanctuaire du Seigneur, parce que l’huile de la sainte onction de son Dieu est sur lui. Je suis le Seigneur.
Kò gbọdọ̀ kúrò ní ibi mímọ́ Ọlọ́run tàbí kí ó sọ ọ́ di aláìmọ́ torí pé a ti fi ìfòróróyàn Ọlọ́run yà á sí mímọ́. Èmi ni Olúwa.
13 C’est une vierge qu’il prendra pour femme;
“‘Ọmọbìnrin tí yóò fẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí kò mọ ọkùnrin rí.
14 Mais il ne prendra point une veuve, et une femme répudiée, ou déshonorée, ni une prostituée, mais une jeune fille de son peuple.
Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
15 Qu’il ne mêle point le sang de sa race avec le vulgaire de sa nation, parce que je suis le Seigneur qui le sanctifie.
Kí ó má ba à sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́.’”
16 Le Seigneur parla encore à Moïse, disant:
Olúwa sì bá Mose sọ̀rọ̀ pé,
17 Dis à Aaron: Un homme de ta lignée dans tes familles, qui aura une tache, n’offrira point des pains à son Dieu;
“Sọ fún Aaroni pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú irú-ọmọ rẹ̀ ní ìran-ìran wọn, tí ó bá ní ààrùn kan, kí ó má ṣe súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọ́run rẹ̀.
18 Et il ne s’approchera point de son ministère, s’il est aveugle, s’il est boiteux, s’il a le nez petit, ou grand, ou tordu,
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi ẹbọ náà. Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé.
19 S’il a le pied rompu ou la main,
Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀,
20 S’il est bossu, s’il est chassieux, s’il a une taie sur l’œil, s’il a une gale continue, ou une dartre vive sur le corps, ou une hernie.
tàbí tí ó jẹ́ abuké, tàbí tí ó ya aràrá tàbí tí ó ní àìsàn ojú tàbí tí ó ní egbò tàbí tí a ti yọ nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀.
21 Quiconque de la race d’Aaron, le prêtre, aura une tache, ne s’approchera point pour offrir des hosties au Seigneur, ni des pains à son Dieu:
Ẹnikẹ́ni tí ó ní àbùkù nínú irú-ọmọ Aaroni àlùfáà kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ tí fi iná sun sí Olúwa. Nítorí pé ó jẹ́ alábùkù, kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ àkàrà sí Ọlọ́run rẹ̀.
22 Il mangera néanmoins des pains qui sont offerts dans le sanctuaire,
Ó lè jẹ́ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ tàbí èyí tí ó mọ́ jùlọ, ṣùgbọ́n torí pé ó ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi aṣọ títa tàbí pẹpẹ.
23 De telle sorte seulement, qu’il n’entre pas au dedans du voile, et qu’il ne s’approche pas de l’autel, parce qu’il a une tache et qu’il ne doit point souiller mon sanctuaire. Je suis le Seigneur qui vous sanctifie.
Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ba ibi mímọ́ mi jẹ́ torí pé, Èmi Olúwa ló ti sọ wọ́n di mímọ́.’”
24 Moïse dit donc à Aaron, à ses fils et à tout Israël tout ce qui lui avait été commandé.
Wọ̀nyí ni àwọn ohun tí Mose sọ fún Aaroni, àwọn ọmọ Aaroni àti gbogbo ọmọ Israẹli.

< Lévitique 21 >