< Ézéchiel 46 >
1 Voici ce que dit le Seigneur Dieu: La porte du parvis intérieur qui regarde vers l’orient sera fermée les six jours dans lesquels on travaille; mais le jour du sabbat elle sera ouverte; et aussi le jour des calendes elle sera ouverte.
“‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmi àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a ṣí i.
2 Et le prince entrera par la voie du vestibule de la porte de dehors; et il s’arrêtera sur le seuil de la porte; et les prêtres offriront son holocauste, et ses oblations pacifiques; il adorera sur le seuil de la porte, et il sortira; mais la porte ne sera pas fermée jusqu’au soir.
Ọmọ-aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kángun sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu-ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ìlẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́.
3 Et le peuple du pays adorera aussi devant le Seigneur à l’entrée de cette porte aux sabbats et aux calendes.
Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà.
4 Or le prince offrira au Seigneur cet holocauste: le jour du sabbat six agneaux sans tache, et un bélier sans tache;
Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù.
5 Et le sacrifice d’un éphi de farine par bélier; mais pour les agneaux le sacrifice sera ce que donnera sa main; et un hin d’huile par chaque éphi.
Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan.
6 Mais au premier jour des calendes, un veau sans tache, pris d’un troupeau; et six agneaux et six béliers sans tache seront ajoutés.
Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n.
7 Et il offrira en sacrifice un éphi de farine par veau, un éphi aussi par bélier; mais quant aux agneaux, le sacrifice sera selon que sa main aura trouvé, et un hin d’huile par chaque éphi.
Yóò si pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ efa fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti efa kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún efa kan.
8 Et lorsque le prince doit entrer dans le temple, qu’il entre par la voie du vestibule de la porte orientale; et qu’il sorte par la même voie.
Nígbà tí ọmọ-aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.
9 Mais lorsque le peuple du pays entrera en la présence du Seigneur dans les solennités, que celui qui entre par la porte de l’aquilon, pour adorer, sorte par la voie de la porte du midi; et que celui qui entre par la porte du midi, sorte par la voie de la porte de l’aquilon; nul ne retournera par la voie de la porte par laquelle il sera entré; mais il sortira par celle d’en face.
“‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.
10 Mais le prince au milieu d’eux, entrera avec ceux qui entrent, et sortira avec ceux qui sortent.
Ọmọ-aládé gbọdọ̀ wà ní àárín wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.
11 Et aux jours de foire et dans les solennités, le sacrifice sera un éphi de farine par veau et un éphi par bélier; mais pour les agneaux, le sacrifice sera selon que la main de chacun aura trouvé, et un hin d’huile par chaque éphi.
“‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan.
12 Or lorsque le prince offrira au Seigneur un holocauste volontaire, ou des victimes pacifiques volontaires, on lui ouvrira la porte qui regarde vers l’orient; et il offrira son holocauste et ses victimes pacifiques, comme cela a coutume de se faire au jour du sabbat; et il sortira, et la porte sera fermée après qu’il sera sorti.
Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un. Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà.
13 Et il offrira chaque jour en holocauste au Seigneur un agneau de la même année, sans tache; et il l’offrira toujours le matin.
“‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀.
14 Et il offrira tous les matins en sacrifice pour cet agneau la, sixième partie d’un éphi, et la troisième partie d’un hin d’huile, afin qu’elle soit mêlée avec la farine; c’est là le sacrifice qu’il est obligé, selon la loi, d’offrir au Seigneur, sacrifice continuel et perpétuel.
Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí.
15 Il immolera l’agneau, et offrira le sacrifice et l’huile, tous les matins; holocauste éternel.
Nítorí náà ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.
16 Voici ce que dit le Seigneur Dieu: Si le prince fait un don à l’un de ses fils, ce sera son héritage à lui et à ses fils; ils le posséderont héréditairement.
“‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ, tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ.
17 Mais s’il fait un legs de son héritage à l’un de ses serviteurs, il ne lui appartiendra que jusqu’à l’année de rémission; et alors il retournera au prince, mais son héritage appartiendra à ses fils.
Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pamọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀, lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ-aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; ó jẹ́ tiwọn.
18 Et le prince ne prendra rien par violence de l’héritage du peuple, ni de ses biens; mais de son bien propre il donnera un héritage à ses fils, afin que parmi mon peuple, personne ne soit écarté de ce qu’il possède.
Ọmọ-aládé kò gbọdọ̀ mú nǹkan kan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma ba à ya nǹkan kan kúrò lára ìní rẹ̀.’”
19 Et il m’introduisit par l’entrée qui était à côté de la porte, dans les chambres du sanctuaire, près des prêtres, chambres qui regardaient vers l’aquilon; et là était un lieu tourné vers l’occident.
Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bàá ẹnu-ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀-oòrùn.
20 Et il me dit: C’est le lieu où les prêtres cuiront les viandes des victimes immolées pour le péché et pour le délit; où ils cuiront ce qui sert au sacrifice; afin qu’ils ne les portent point dans le parvis extérieur, et que le peuple ne soit pas sanctifié.
O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má ṣe jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá, kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”
21 Et il me fit sortir dans le parvis extérieur, et me mena aux quatre coins du parvis; et voici qu’il y avait une petite cour au coin du parvis; à chaque coin du parvis il y avait une petite cour.
Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan.
22 Ces petites cours ainsi disposées aux quatre coins du parvis, avaient quarante coudées de long, et trente de large; les quatre étaient d’une même mesure.
Ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnu pọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú; àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà.
23 Et une muraille enfermait tout autour les quatre petites cours; et des cuisines avaient été construites sous les portiques tout autour.
Ní agbègbè inú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo.
24 Et il me dit: Voici la maison des cuisines, dans laquelle les ministres de la maison du Seigneur cuiront les victimes du peuple.
Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn.”