< Néhémie 7 >

1 Lorsque la muraille fut rebâtie et que j’eus posé les battants des portes, on établit dans leurs fonctions les portiers, les chantres et les Lévites.
Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì ri àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Lefi.
2 Je donnai mes ordres à Hanani, mon frère, et à Hanania, chef de la citadelle de Jérusalem, homme supérieur au grand nombre par sa fidélité et par sa crainte de Dieu.
Mo fún Hanani arákùnrin mi pẹ̀lú Hananiah olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jerusalẹmu, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòtítọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ.
3 Je leur dis: Les portes de Jérusalem ne s’ouvriront pas avant que la chaleur du soleil soit venue, et l’on fermera les battants aux verrous en votre présence; les habitants de Jérusalem feront la garde, chacun à son poste devant sa maison.
Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn Jerusalẹmu títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”
4 La ville était spacieuse et grande, mais peu peuplée, et les maisons n’étaient pas bâties.
Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́.
5 Mon Dieu me mit au cœur d’assembler les grands, les magistrats et le peuple, pour en faire le dénombrement. Je trouvai un registre généalogique de ceux qui étaient montés les premiers, et j’y vis écrit ce qui suit.
Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà.
6 Voici ceux de la province qui revinrent de l’exil, ceux que Nebucadnetsar, roi de Babylone, avait emmenés captifs, et qui retournèrent à Jérusalem et en Juda, chacun dans sa ville.
Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó ní ìgbèkùn (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú u rẹ̀.
7 Ils partirent avec Zorobabel, Josué, Néhémie, Azaria, Raamia, Nachamani, Mardochée, Bilschan, Mispéreth, Bigvaï, Nehum, Baana. Nombre des hommes du peuple d’Israël:
Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordekai, Bilṣani, Misperi, Bigfai, Nehumu, àti Baanah). Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọkùnrin Israẹli,
8 les fils de Pareosch, deux mille cent soixante-douze;
àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án
9 les fils de Schephathia, trois cent soixante-douze;
Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá
10 les fils d’Arach, six cent cinquante-deux;
Arah jẹ́ ẹgbẹ̀tàléláàádọ́ta ó lé méjì
11 les fils de Pachath-Moab, des fils de Josué et de Joab, deux mille huit cent dix-huit;
Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún
12 les fils d’Élam, mille deux cent cinquante-quatre;
Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin
13 les fils de Zatthu, huit cent quarante-cinq;
Sattu jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún
14 les fils de Zaccaï, sept cent soixante;
Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin
15 les fils de Binnuï, six cent quarante-huit;
Binnui jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ
16 les fils de Bébaï, six cent vingt-huit;
Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n
17 les fils d’Azgad, deux mille trois cent vingt-deux;
Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin
18 les fils d’Adonikam, six cent soixante-sept;
Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje
19 les fils de Bigvaï, deux mille soixante-sept;
Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin
20 les fils d’Adin, six cent cinquante-cinq;
Adini jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún
21 les fils d’Ather, de la famille d’Ézéchias, quatre-vingt-dix-huit;
Ateri (láti ipasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún
22 les fils de Haschum, trois cent vingt-huit;
Haṣumu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ
23 les fils de Betsaï, trois cent vingt-quatre;
Besai jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́rin
24 les fils de Hariph, cent douze;
Harifu jẹ́ méjìléláàádọ́fà
25 les fils de Gabaon, quatre-vingt-quinze;
Gibeoni jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn.
26 les gens de Bethléhem et de Netopha, cent quatre-vingt-huit;
Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu àti Netofa jẹ́ igba ó dín méjìlélógún
27 les gens d’Anathoth, cent vingt-huit;
Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje
28 les gens de Beth-Azmaveth, quarante-deux;
Beti-Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì
29 les gens de Kirjath-Jearim, de Kephira et de Beéroth, sept cent quarante-trois;
Kiriati-Jearimu, Kefira, àti Beeroti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta
30 les gens de Rama et de Guéba, six cent vingt et un;
Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún
31 les gens de Micmas, cent vingt-deux;
Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà
32 les gens de Béthel et d’Aï, cent vingt-trois;
Beteli àti Ai jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà
33 les gens de l’autre Nebo, cinquante-deux;
Nebo mìíràn jẹ́ méjìléláàádọ́ta
34 les fils de l’autre Élam, mille deux cent cinquante-quatre;
Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta
35 les fils de Harim, trois cent vingt;
Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó
36 les fils de Jéricho, trois cent quarante-cinq;
Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún.
37 les fils de Lod, de Hadid et d’Ono, sept cent vingt et un;
Lodi, Hadidi, àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kan
38 les fils de Senaa, trois mille neuf cent trente.
Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó dín àádọ́rin.
39 Sacrificateurs: les fils de Jedaeja, de la maison de Josué, neuf cent soixante-treize;
Àwọn àlùfáà: àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje
40 les fils d’Immer, mille cinquante-deux;
Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì
41 les fils de Paschhur, mille deux cent quarante-sept;
Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta
42 les fils de Harim, mille dix-sept.
Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún.
43 Lévites: les fils de Josué et de Kadmiel, des fils d’Hodva, soixante-quatorze.
Àwọn ọmọ Lefi: àwọn ọmọ Jeṣua (láti ipasẹ̀ Kadmieli, láti ipasẹ̀ Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin.
44 Chantres: les fils d’Asaph, cent quarante-huit.
Àwọn akọrin: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ méjìdínláàádọ́jọ.
45 Portiers: les fils de Schallum, les fils d’Ather, les fils de Thalmon, les fils d’Akkub, les fils de Hathitha, les fils de Schobaï, cent trente-huit.
Àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjìdínlógóje.
46 Néthiniens: les fils de Tsicha, les fils de Hasupha, les fils de Thabbaoth,
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ Siha, Hasufa, Tabboati,
47 les fils de Kéros, les fils de Sia, les fils de Padon,
Kerosi, Sia, Padoni,
48 les fils de Lebana, les fils de Hagaba, les fils de Salmaï,
Lebana, Hagaba, Ṣalmai,
49 les fils de Hanan, les fils de Guiddel, les fils de Gachar,
Hanani, Giddeli, Gahari,
50 les fils de Reaja, les fils de Retsin, les fils de Nekoda,
Reaiah, Resini, Nekoda,
51 les fils de Gazzam, les fils d’Uzza, les fils de Paséach,
Gassamu, Ussa, Pasea,
52 les fils de Bésaï, les fils de Mehunim, les fils de Nephischsim,
Besai, Mehuni, Nefisimu,
53 les fils de Bakbuk, les fils de Hakupha, les fils de Harhur,
Bakbu, Hakufa, Harhuri,
54 les fils de Batslith, les fils de Mehida, les fils de Harscha,
Basluti, Mehida, Harṣa,
55 les fils de Barkos, les fils de Sisera, les fils de Thamach,
Barkosi, Sisera, Tema,
56 les fils de Netsiach, les fils de Hathipha.
Nesia, àti Hatifa.
57 Fils des serviteurs de Salomon: les fils de Sothaï, les fils de Sophéreth, les fils de Perida,
Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni: àwọn ọmọ Sotai, Sofereti; Perida,
58 les fils de Jaala, les fils de Darkon, les fils de Guiddel,
Jaala, Darkoni, Giddeli,
59 les fils de Schephathia, les fils de Hatthil, les fils de Pokéreth-Hatsebaïm, les fils d’Amon.
Ṣefatia, Hattili, Pokereti-Haṣṣebaimu, àti Amoni.
60 Total des Néthiniens et des fils des serviteurs de Salomon: trois cent quatre-vingt-douze.
Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ.
61 Voici ceux qui partirent de Thel-Mélach, de Thel-Harscha, de Kerub-Addon, et d’Immer, et qui ne purent pas faire connaître leur maison paternelle et leur race, pour prouver qu’ils étaient d’Israël.
Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli.
62 Les fils de Delaja, les fils de Tobija, les fils de Nekoda, six cent quarante-deux.
Àwọn ọmọ Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì.
63 Et parmi les sacrificateurs: les fils de Hobaja, les fils d’Hakkots, les fils de Barzillaï, qui avait pris pour femme une des filles de Barzillaï, le Galaadite, et fut appelé de leur nom.
Lára àwọn àlùfáà ni: àwọn ọmọ Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).
64 Ils cherchèrent leurs titres généalogiques, mais ils ne les trouvèrent point. On les exclut du sacerdoce,
Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́.
65 et le gouverneur leur dit de ne pas manger des choses très saintes jusqu’à ce qu’un sacrificateur eût consulté l’urim et le thummim.
Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé.
66 L’assemblée tout entière était de quarante-deux mille trois cent soixante personnes,
Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó,
67 sans compter leurs serviteurs et leurs servantes, au nombre de sept mille trois cent trente-sept. Parmi eux se trouvaient deux cent quarante-cinq chantres et chanteuses.
yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta; wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún.
68 Ils avaient sept cent trente-six chevaux, deux cent quarante-cinq mulets,
Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin, ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún;
69 quatre cent trente-cinq chameaux, et six mille sept cent vingt ânes.
ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún; kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin.
70 Plusieurs des chefs de famille firent des dons pour l’œuvre. Le gouverneur donna au trésor mille dariques d’or, cinquante coupes, cinq cent trente tuniques sacerdotales.
Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.
71 Les chefs de familles donnèrent au trésor de l’œuvre vingt mille dariques d’or et deux mille deux cents mines d’argent.
Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ogún ẹgbẹ̀rún dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá mina fàdákà.
72 Le reste du peuple donna vingt mille dariques d’or, deux mille mines d’argent, et soixante-sept tuniques sacerdotales.
Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ogún ẹgbẹ̀rún dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì mina fàdákà àti ẹẹ́tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.
73 Les sacrificateurs et les Lévites, les portiers, les chantres, les gens du peuple, les Néthiniens et tout Israël s’établirent dans leurs villes. Le septième mois arriva, et les enfants d’Israël étaient dans leurs villes.
Àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Israẹli wà ní ìlú wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje, tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú ìlú u wọn,

< Néhémie 7 >