< Marc 16 >
1 Lorsque le sabbat fut passé, Marie de Magdala, Marie, mère de Jacques, et Salomé, achetèrent des aromates, afin d’aller embaumer Jésus.
Nígbà tí ọjọ́ ìsinmi sì kọjá, Maria Magdalene, Maria ìyá Jakọbu, àti Salome mú òróró olóòórùn dídùn wá kí wọn bá à le fi kun Jesu lára.
2 Le premier jour de la semaine, elles se rendirent au sépulcre, de grand matin, comme le soleil venait de se lever.
Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, wọ́n wá sí ibi ibojì nígbà tí oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ,
3 Elles disaient entre elles: Qui nous roulera la pierre loin de l’entrée du sépulcre?
wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò ní ẹnu ibojì fún wa?”
4 Et, levant les yeux, elles aperçurent que la pierre, qui était très grande, avait été roulée.
Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn sì wò ó, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta tí ó tóbi gidigidi náà kúrò.
5 Elles entrèrent dans le sépulcre, virent un jeune homme assis à droite vêtu d’une robe blanche, et elles furent épouvantées.
Nígbà tí wọ́n sì wo inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnu sì yà wọn.
6 Il leur dit: Ne vous épouvantez pas; vous cherchez Jésus de Nazareth, qui a été crucifié; il est ressuscité, il n’est point ici; voici le lieu où on l’avait mis.
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ̀yin ń wá Jesu tí Nasareti, tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ó jíǹde! Kò sí níhìn-ín yìí mọ́, ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.
7 Mais allez dire à ses disciples et à Pierre qu’il vous précède en Galilée: c’est là que vous le verrez, comme il vous l’a dit.
Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Peteru wí pé, ‘Òun ti ń lọ síwájú yín sí Galili. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’”
8 Elles sortirent du sépulcre et s’enfuirent. La peur et le trouble les avaient saisies; et elles ne dirent rien à personne, à cause de leur effroi.
Wọ́n sáré jáde lọ kánkán, kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì; ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi; wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n.
9 (note: The most reliable and earliest manuscripts do not include Mark 16:9-20.) Jésus, étant ressuscité le matin du premier jour de la semaine, apparut d’abord à Marie de Magdala, de laquelle il avait chassé sept démons.
(note: The most reliable and earliest manuscripts do not include Mark 16:9-20.) Nígbà tí Jesu jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mí Èṣù méje jáde.
10 Elle alla en porter la nouvelle à ceux qui avaient été avec lui, et qui s’affligeaient et pleuraient.
Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún.
11 Quand ils entendirent qu’il vivait, et qu’elle l’avait vu, ils ne le crurent point.
Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé Jesu wa láààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.
12 Après cela, il apparut, sous une autre forme, à deux d’entre eux qui étaient en chemin pour aller à la campagne.
Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbèríko.
13 Ils revinrent l’annoncer aux autres, qui ne les crurent pas non plus.
Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, síbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́.
14 Enfin, il apparut aux onze, pendant qu’ils étaient à table; et il leur reprocha leur incrédulité et la dureté de leur cœur, parce qu’ils n’avaient pas cru ceux qui l’avaient vu ressuscité.
Lẹ́yìn náà, Jesu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn mọ́kànlá níbi tí wọ́n ti ń jẹun papọ̀; Ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba ẹ̀rí àwọn tí ó ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ gbọ́.
15 Puis il leur dit: Allez par tout le monde, et prêchez la bonne nouvelle à toute la création.
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì máa wàásù ìyìnrere mi fún gbogbo ẹ̀dá.
16 Celui qui croira et qui sera baptisé sera sauvé, mais celui qui ne croira pas sera condamné.
Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí a sì tẹ̀bọmi yóò là. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò gbàgbọ́ yóò jẹ̀bi.
17 Voici les miracles qui accompagneront ceux qui auront cru: en mon nom, ils chasseront les démons; ils parleront de nouvelles langues;
Àmì wọ̀nyí yóò sì máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ. Ní orúkọ mi ni wọ́n yóò máa lé ẹ̀mí èṣù jáde. Wọn yóò máa fi èdè tuntun sọ̀rọ̀.
18 ils saisiront des serpents; s’ils boivent quelque breuvage mortel, il ne leur fera point de mal; ils imposeront les mains aux malades, et les malades, seront guéris.
Wọn yóò sì gbé ejò lọ́wọ́, bí wọ́n bá sì jẹ májèlé kò nípa wọ́n lára rárá. Wọ́n yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá.”
19 Le Seigneur, après leur avoir parlé, fut enlevé au ciel, et il s’assit à la droite de Dieu.
Nígbà tí Jesu Olúwa sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ báyìí tan, á gbé e lọ sí ọ̀run, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.
20 Et ils s’en allèrent prêcher partout. Le Seigneur travaillait avec eux, et confirmait la parole par les miracles qui l’accompagnaient.
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ. Wọ́n ń wàásù káàkiri. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa àwọn àmì tí ó tẹ̀lé e.