< 1 Chroniques 3 >

1 Voici les fils de David qui lui naquirent à Hébron; le premier-né fut: Amnon, fils de la Jezraélite Achinaam; le second, Damniel (Daluia), fils d'Abigaïl du Carmel;
Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni. Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli; èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;
2 Le troisième, Absalon, fils de Moha (Maacha), fille de Tholmé, roi de Gedsur; le quatrième, Adonias (Ornia), fils d'Aggith;
ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un; ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;
3 Le cinquième, Saphatia, fils d'Abital; le sixième, Jethram, fils de sa femme Agla.
ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali; àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.
4 Il en eut six à Hébron, et il y régna sept ans et demi; après quoi, il régna trente-trois ans à Jérusalem.
Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.
5 Voici ceux qui lui naquirent en Jérusalem: Samaa, Sobab, Nathan et Salomon. Quatre fils de Bethsabée, fille d'Amiel.
Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu: Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.
6 Puis, Ebaar, Elisa, Eliphaleth,
Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti,
7 Nagé, Naphec, Japhie,
Noga, Nefegi, Jafia,
8 Elisama, Eliada et Eliphala; en tout: neuf.
Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n.
9 Tous fils de David, outre les fils de ses concubines, et Thamar, leur sœur.
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.
10 Fils de Salomon: Roboam, Abias son fils, Asa son fils, Josaphat son fils,
Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu, Abijah ọmọ rẹ̀, Asa ọmọ rẹ̀, Jehoṣafati ọmọ rẹ̀,
11 Joram son fils, Ochozias son fils, Joas son. fils,
Jehoramu ọmọ rẹ̀, Ahasiah ọmọ rẹ̀, Joaṣi ọmọ rẹ̀,
12 Amasias son fils, Azarias son fils, Joathan son fils,
Amasiah ọmọ rẹ̀, Asariah ọmọ rẹ̀, Jotamu ọmọ rẹ̀,
13 Achaz son fils, Ezéchias son fils, Manassé son fils,
Ahasi ọmọ rẹ̀, Hesekiah ọmọ rẹ̀, Manase ọmọ rẹ̀,
14 Amon son fils, Josias son fils.
Amoni ọmọ rẹ̀, Josiah ọmọ rẹ̀.
15 Fils de Josias: Joanan le premier-né, Joacin le second, Sédécias le troisième, et Salum le quatrième.
Àwọn ọmọ Josiah: àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani, èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu, ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah, ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.
16 Fils de Joacin: Jéchonias son fils, Sédécias son fils.
Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu: Jekoniah ọmọ rẹ̀, àti Sedekiah.
17 Fils de Jéchonias: Asir, Salathiel son fils,
Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn: Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin,
18 Melchiram, Phadaïas, Fanesar, Jécimie, Hosamath et Nabadias.
Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah.
19 Fils de Phadaïas: Zorobabel et Sémeï. Fils de Zorobabel: Mosollam et Ananias; Salometh fut leur sœur.
Àwọn ọmọ Pedaiah: Serubbabeli àti Ṣimei. Àwọn ọmọ Serubbabeli: Meṣullamu àti Hananiah. Ṣelomiti ni arábìnrin wọn.
20 Il eut encore: Asubé, Ool, Barachie, Asadie et Asobed; cinq fils.
Àwọn márùn-ún mìíràn sì tún wà: Haṣuba, Oheli, Berekiah, Hasadiah àti Jusabhesedi.
21 Fils d'Ananias: Phalettie, Jésias son fils, Raphal son fils, Orna son fils, Abdias son fils, et Séchénias son fils.
Àwọn ọmọ Hananiah: Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Obadiah àti ti Ṣekaniah.
22 Fils de Sechénias: Samaïe. Fils de Samaie: Battus, Johel, Berri, Noadie et Saphat; six issus de Sechénias.
Àwọn ọmọ Ṣekaniah: Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn.
23 Fils de Noadie: Elithenan, Ezécie, Ezricam; trois.
Àwọn ọmọ Neariah: Elioenai; Hesekiah, àti Asrikamu, mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Fils d'Elithenan: Odolie, Eliasebon, Phadaïe, Acub, Joanan, Dalaaïe et Anan; sept.
Àwọn ọmọ Elioenai: Hodafiah, Eliaṣibu, Pelaiah, Akkubu, Johanani, Delaiah àti Anani, méje sì ni gbogbo wọn.

< 1 Chroniques 3 >