< 1 Chroniques 12 >

1 Et voici ceux qui accompagnaient David à Sicelag, quand il était contraint de se cacher de Saül, fils de Cis; et ils comptaient parmi les vaillants, hommes de secours dans les batailles.
Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Siklagi, nígbà tí ó sá kúrò níwájú Saulu ọmọ Kiṣi (wọ́n wà lára àwọn jagunjagun ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti ibi ìjà.
2 Ils tiraient leur arc de la main droite et de la main gauche; ils étaient frondeurs et archers. Des frères de Saül, de la tribu de Benjamin,
Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Saulu láti ẹ̀yà Benjamini):
3 Le chef était Achiézer; puis, venaient Joas, fils d'Asma le Gabathéen; Johel, Jophalet, fils d'Asmoth; Berchia, Jehul d'Anathoth,
Ahieseri olórí wọn àti Joaṣi àwọn ọmọ Ṣemaah ará Gibeah: Jeṣieli àti Peleti ọmọ Asmafeti, Beraka, Jehu ará Anatoti.
4 Samaïas de Gabaon, vaillant parmi les trente, et leur chef, puis, Jérémie, Jézéel, Joanan, Joazobath de Garathiim,
Àti Iṣmaiah ará Gibeoni, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n; Jeremiah, Jahasieli, Johanani, Josabadi ará Gedera,
5 Azaï, Arimuth, Baalie, Samaraie et Saphatias d'Haréphiel,
Elusai, Jerimoti, Bealiah, Ṣemariah àti Ṣefatia ará Harufiti;
6 Elcana, Jesuni, Ozriel, Jozara, Sobocam et les Coréens,
Elkana, Iṣiah, Asareeli, Joeseri àti Jaṣobeamu ará Kora;
7 Et Jelia, Zabadie, fils de Joram, et ceux de Gédor.
àti Joẹla, àti Sebadiah àwọn ọmọ Jerohamu láti Gedori.
8 Et, de la tribu de Gad, des hommes vaillants et forts, quittant le désert, rejoignirent David; tous exercés aux combats, portant bouclier et javelines, hommes à face de lion, et légers à la course dans les montagnes, comme des chevreuils.
Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.
9 Aza était le chef, Abdias le second, Eliab le troisième,
Eseri sì jẹ́ ìjòyè, Obadiah sì jẹ́ igbákejì akọgun, Eliabu ẹlẹ́ẹ̀kẹta,
10 Masmana le quatrième, Jérémie le cinquième,
Miṣimana ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, Jeremiah ẹlẹ́ẹ̀karùnún
11 Jéthi le sixième, Eliab le septième,
Attai ẹlẹ́ẹ̀kẹfà, Elieli èkeje,
12 Joanan le huitième, Eléazer le neuvième,
Johanani ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ Elsabadi ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn-án
13 Jérémia le dixième, Melcbanaï le onzième.
Jeremiah ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá àti Makbannai ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá.
14 Ils étaient les chefs de l'armée des fils de Gad; celui du moindre rang commandait cent hommes; celui du rang le plus élevé en commandait mille.
Àwọn ará Gadi wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún.
15 Ce furent ceux-là qui passèrent le Jourdain pendant le premier mois, lorsqu'il coulait à pleins bords, et ils mirent en fuite tous ceux qui habitaient ses deux rives.
Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jordani ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà-oòrùn àti níhà ìwọ̀-oòrùn.
16 Il vint aussi à David des auxiliaires des fils de Benjamin et de Juda.
Ìyókù ará Benjamini àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Juda lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní ibi gíga.
17 Et David se porta au-devant d'eux, et il leur dit: Si vous êtes venus en paix, mon cœur sera bienveillant pour vous; mais si vous n'êtes point sincères, si vous avez dessein de me livrer à mes ennemis, que le Dieu de vos pères vous voie, et qu'il vous punisse.
Dafidi sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo ṣetán láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀tá mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.”
18 Et l'esprit entra en Amasaï, un chef des trente, et il dit: David, fils de Jessé, marche avec ton peuple, la paix, la paix avec toi, la paix avec tes auxiliaires; car c'est ton Dieu qui t'a secondé. Et David les accueillit, et il leur donna des commandements dans l'armée.
Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Amasai ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé, “Tìrẹ ni àwa ń ṣe, ìwọ Dafidi! Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jese! Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ, àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.
19 Et des fils de Manassé vinrent à David, dans le même temps que les Philistins étaient en guerre avec Saül, et qu'ils avaient répudié le secours de David, parce que, dans leur conseil, les chefs des Philistins avaient dit: Il se réconciliera avec son maître Saül, en lui portant les têtes de nos hommes.
Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Manase sì yà sí ọ̀dọ̀ Dafidi nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Filistini láti bá Saulu jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wọn kò sì ran ará Filistini lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn tiwọn sọ̀rọ̀ papọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé, “Yóò jẹ́ ìparun fún wa tí ó bá padà tọ ọ̀gá rẹ̀ Saulu lọ.”)
20 Et comme il retournait à Sicelag, Edna, Josabeth, Rodiel, Michel, Josabeth, Elimuth et Semathi, vinrent auprès de lui, de Manassé; c'étaient des chefs de mille hommes de Manassé.
Nígbà tí Dafidi lọ sí Siklagi, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Manase ẹni tí ó sì yà sọ́dọ̀ rẹ̀. Adina, Josabadi, Jediaeli, Mikaeli, Josabadi, Elihu àti Siletai, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Manase.
21 Et ils furent les auxiliaires de David contre ses ennemis; tous vaillants, comme ils l'étaient, prirent rang parmi les chefs de l'armée.
Wọ́n sì ran Dafidi lọ́wọ́ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
22 Car cette armée s'augmentait de jour en jour, et elle devenait forte comme l'armée de Dieu.
Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run.
23 Et voici le dénombrement des chefs de l'armée qui entrèrent avec David à Hébron, pour lui transmettre la royauté de Saül, selon la parole du Seigneur.
Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni láti yí ìjọba Dafidi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.
24 Fils de Juda, portant lance et bouclier: six mille huit cents, prêts à combattre.
Ọkùnrin Juda, tí o ń gbé asà àti ọ̀kọ̀, ẹgbàáta lé lẹ́gbẹ̀rin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun.
25 Fils de Siméon, vaillants prêts à combattre: sept mille cent.
Àwọn ọkùnrin Simeoni, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó lé ọgọ́rùn-ún;
26 Fils de Lévi: quatre mille six cents.
àwọn ọkùnrin Lefi ẹgbàajì ó le ẹgbẹ̀ta,
27 Joad conduisait les fils d'Aaron; il avait avec lui trois mille sept cents hommes.
pẹ̀lú Jehoiada, olórí ìdílé Aaroni pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn,
28 Sadoc, jeune homme fort et vaillant, avait amené, de sa famille paternelle, vingt-deux chefs.
àti Sadoku akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀;
29 Fils de Benjamin, frères de Saül: trois mille; mais le plus grand nombre de cette tribu formait encore la garde du palais de Saül.
àwọn arákùnrin Benjamini ìbátan ọkùnrin Saulu ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtítọ́ sí ilé Saulu títí di ìgbà náà;
30 Fils d'Ephraïm: vingt mille, vaillants et forts, hommes illustres dans leurs familles paternelles.
àwọn arákùnrin Efraimu, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ogún ẹgbẹ̀rún ó le ẹgbẹ̀rin;
31 Fils de la demi-tribu de Manassé: dix-huit mille, qui furent recensés nominativement, pour établir roi David.
àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba, ẹgbàá mẹ́sàn.
32 Fils d'Issachar, connaissant ce qu'exigeaient les circonstances, sachant ce qu'il y avait à faire pour Israël: deux cents, et avec eux tous leurs frères.
Àti ní ti àwọn ọmọ Isakari, àwọn ẹni tí ó ní òye àkókò, láti mọ ohun tí Israẹli ìbá máa ṣe; olórí wọn jẹ́ ìgbà; àti gbogbo àwọn ìbátan wọn ń bẹ ní ìkáwọ́ wọn.
33 Fils de Zabulon, allant au combat avec toutes les armes de guerre: cinquante mille, auxiliaires de David, n'ayant pas les mains vides.
Àwọn ọkùnrin Sebuluni, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ohun èlò ìjà, láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóòótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.
34 Fils de Nephthali: mille chefs, et avec eux trente-sept mille hommes, portant lance et bouclier.
Àwọn ọkùnrin Naftali, ẹgbẹ̀rún ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún. Ọkùnrin tí wọ́n gbé asà àti ọ̀kọ̀ wọn.
35 Fils de Dan, prêts à combattre: vingt-huit mille huit cents.
Àwọn ọkùnrin Dani, tí wọ́n ṣetán fún ogun ẹgbàá mẹ́tàlá.
36 Fils d'Aser: quarante mille auxiliaires.
Àwọn ọkùnrin Aṣeri, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ ogun múra fún ogun ọ̀kẹ́ méjì.
37 Fils de Ruben, de Gad, et de la demi-tribu de Manassé, au delà du Jourdain, portant toutes les armes de guerre: cent vingt mille.
Láti ìlà-oòrùn Jordani, ọkùnrin Reubeni, Gadi, àti ìdajì ẹ̀yà Manase, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà.
38 Tous ces hommes, qui étaient aguerris et prêts à combattre, vinrent à Hébron, pleins d'un esprit pacifique, afin de proclamer David roi de tout Israël, et tout le reste du peuple n'avait qu'une âme pour couronner David.
Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ́ fún nínú ẹgbẹ́. Wọ́n wá sí Hebroni tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dafidi jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Israẹli sì jẹ́ onínú kan láti fi Dafidi jẹ ọba.
39 Et ils demeurèrent trois jours, mangeant et buvant ce que leurs frères avaient préparé pour eux,
Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dafidi, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèsè oúnjẹ fún wọn.
40 Et ce qu'on leur apportait de tout le territoire depuis Issachar jusqu'à Zabulon et Nephthali, sur des chameaux, des ânes, des mulets et des bœufs, savoir: des viandes cuites, de la farine, des figues, des raisins secs, du vin et de l'huile, outre une multitude de bœufs et de moutons; car tout Israël était en joie.
Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli.

< 1 Chroniques 12 >