< Psaumes 20 >
1 Au chef des chantres. Psaume de David. Que l’Eternel t’exauce au jour de détresse, que le nom du Dieu de Jacob te protège!
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
2 Qu’il t’envoie son secours du Sanctuaire, que de Sion il soit ton appui!
Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
3 Qu’il se souvienne de toutes tes offrandes, et fasse bon accueil à tes holocaustes!
Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. (Sela)
4 Puisse-t-il t’accorder ce que ton cœur désire et accomplir tous tes desseins!
Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
5 Nous allons célébrer ta victoire, arborer comme un drapeau le nom de notre Dieu. Que l’Eternel comble tous tes vœux!
Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.
6 A cette heure je sais que l’Eternel soutient son oint, qu’il lui répond des cieux, siège de sa sainteté, par l’aide puissante de sa droite.
Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé, Olúwa pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́. Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
7 Que les uns se fient aux chars, les autres aux chevaux, nous nous réclamons, nous, du nom de l’Eternel, notre Dieu.
Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin, ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.
8 Ceux-là plient et tombent, et nous demeurons debout, pleins de force.
Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú, ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
9 Eternel, viens à notre secours! Que le Roi nous exauce le jour où nous l’invoquons!
Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba! Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!