< Juges 13 >
1 Les enfants d’Israël recommencèrent à déplaire au Seigneur, et celui-ci les soumit aux Philistins durant quarante années.
Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Olúwa sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistini lọ́wọ́ fún ogójì ọdún.
2 Il y avait alors à Çorea un homme d’une famille de Danites, appelé Manoah. Sa femme était stérile, elle n’avait jamais enfanté.
Ọkùnrin ará Sora kan wà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Manoa láti ẹ̀yà Dani. Aya rẹ̀ yàgàn kò sì bímọ.
3 Or, un ange du Seigneur apparut à cette femme et lui dit: "Vois, tu es stérile, tu n’as jamais eu d’enfant: eh bien! tu concevras, et tu auras un fils.
Angẹli Olúwa fi ara han obìnrin náà, ó sì wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yàgàn, ìwọ kò sì tí ì bímọ, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.
4 Et maintenant observe-toi bien, ne bois ni vin ni autre liqueur enivrante, et ne mange rien d’impur.
Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan,
5 Car tu vas concevoir et enfanter un fils; le rasoir ne doit pas toucher sa tête, car cet enfant doit être un Naziréen consacré à Dieu dès le sein maternel, et c’est lui qui entreprendra de sauver Israël de la main des Philistins."
nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.”
6 La femme alla trouver son mari et lui dit: "Un homme de Dieu est venu à moi, et son aspect était comme celui d’un ange, fort imposant; je ne lui ai pas demandé d’où il venait, et il ne m’a point appris son nom.
Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ angẹli Ọlọ́run, ó ba ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.
7 Il m’a dit: "Tu vas concevoir et enfanter un fils; et maintenant ne bois ni vin ni liqueur forte, ne mange rien d’impur, car cet enfant sera un Naziréen consacré à Dieu depuis le sein de sa mère jusqu’au jour de sa mort."
Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Nasiri Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’”
8 Alors Manoah implora l’Eternel en disant: "De grâce, Seigneur! que l’homme divin que tu as envoyé revienne nous visiter, pour nous enseigner nos devoirs à l’égard de l’enfant qui doit naître."
Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”
9 Dieu exauça la prière de Manoah; l’ange du Seigneur vint de nouveau trouver la femme tandis qu’elle se tenait aux champs, Manoah son époux n’étant pas avec elle.
Ọlọ́run fetí sí ohùn Manoa, angẹli Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Manoa kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.
10 Elle courut en toute hâte l’annoncer à son époux, lui disant: "Voici que j’ai revu l’homme qui était venu à moi l’autre jour."
Nítorí náà ni obìnrin náà ṣe yára lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó fi ara hàn mí ní ọjọ́sí ti tún padà wá.”
11 Manoah se leva et suivit sa femme, et, arrivé près du personnage, lui dit: "Es-tu celui qui a parlé à cette femme?" Il répondit: "Je le suis."
Manoa yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, “Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀?” Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Èmi ni.”
12 Manoah reprit: "Vienne maintenant ce que tu as prédit, quelle règle, quelle conduite est recommandée pour cet enfant?"
Manoa bi ọkùnrin náà pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ kí ni yóò jẹ́ ìlànà fún ìgbé ayé àti iṣẹ́ ọmọ náà?”
13 L’Ange de l’Eternel répondit à Manoah: "Tout ce que j’ai désigné à ta femme, elle doit se l’interdire:
Angẹli Olúwa náà dáhùn wí pé, “Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un
14 elle ne mangera rien de ce que produit la vigne, ne boira ni vin, ni liqueur enivrante, s’abstiendra de tout mets impur; bref, tout ce que je lui ai prescrit, elle l’observera."
kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èso àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pàṣẹ fún un.”
15 Manoah dit à l’ange de l’Eternel: "Oh! permets que nous te retenions encore et que nous te servions un jeune chevreau."
Manoa sọ fún angẹli Olúwa náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèsè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.”
16 L’Ange de l’Eternel répondit à Manoah: "Tu aurais beau me retenir, je ne mangerais point de ton pain; et si c’est un holocauste que tu veux faire, offre-le à l’Eternel!" Or, Manoah ignorait que c’était un ange de Dieu.
Angẹli Olúwa náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí Olúwa.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli Olúwa ní i ṣe.)
17 Et il dit à l’ange: "Quel est ton nom? Dis-le, pour que, ta prédiction accomplie, nous puissions t’honorer."
Manoa sì béèrè lọ́wọ́ angẹli Olúwa náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?”
18 L’Ange répondit: "A quoi bon t’enquérir de mon nom? c’est un mystère."
Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè orúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.”
19 Et Manoah prit le jeune chevreau ainsi que l’oblation, et les offrit, sur le rocher, à l’Eternel. Alors un miracle s’accomplit, dont Manoah et sa femme furent témoins:
Lẹ́yìn náà ni Manoa mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rú ẹbọ lórí àpáta kan sí Olúwa. Nígbà tí Manoa àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò Olúwa ṣe ohun ìyanu kan.
20 au moment où la flamme s’élevait de l’autel vers le ciel, l’ange du Seigneur disparut au milieu de cette flamme. Manoah et sa femme, à cette vue, se jetèrent la face contre terre.
Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, angẹli Olúwa gòkè re ọ̀run láàrín ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Manoa àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojúbolẹ̀.
21 L’Ange cessa ainsi d’être visible pour Manoah et pour sa femme; alors Manoah reconnut que c’était un ange de l’Eternel,
Nígbà tí angẹli Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Manoa àti aya rẹ̀ mọ́, Manoa wá mọ̀ pé angẹli Olúwa ni.
22 et il dit à sa femme: "Nous sommes morts, car c’est un être divin que nous avons vu!"
Manoa sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.”
23 Sa femme lui répartit: "Si l’Eternel avait voulu nous faire mourir, il n’aurait pas accepté de notre part holocauste et oblation; il ne nous aurait pas montré tous ces prodiges, ni fait à cette heure une telle prédiction."
Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.”
24 Cette femme donna le jour à un fils, qu’elle nomma Samson. L’Enfant grandit et fut béni du Seigneur.
Obìnrin náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Samsoni. Ọmọ náà dàgbà Olúwa sì bùkún un.
25 L’Esprit divin le saisit pour la première fois à Mahané-Dan, entre Çorea et Echtaol.
Ẹ̀mí Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Mahane-Dani ní agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli.