< 2 Samuel 1 >

1 Après la mort de Saül, David, qui venait de battre les Amalécites, resta deux jours à Ciklag.
Lẹ́yìn ikú Saulu, Dafidi ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki bọ̀, ó sì dúró ní Siklagi ní ọjọ́ méjì.
2 Le troisième jour, on vit un homme venir du camp de Saül, les vêtements déchirés, la tête couverte de poussière. En arrivant auprès de David, il se jeta à terre et se prosterna.
Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Saulu, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un.
3 "D’Où viens-tu?" lui demanda David. Il lui répondit: "Du camp d’Israël, d’où je me suis échappé.
Dafidi sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?” “Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.”
4 Que s’est-il passé? dit David, raconte-le moi." Il raconta que le peuple avait fui du champ de bataille, qu’il en était mort un grand nombre, que Saül et son fils Jonathan avaient également péri.
Dafidi béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.” Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Saulu àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jonatani sì kú pẹ̀lú.”
5 David dit au jeune homme qui l’avait renseigné: "Comment sais-tu que Saül et son fils Jonathan sont morts?"
Nígbà náà, ní Dafidi sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jonatani ti kú.”
6 Le jeune homme qui apportait les nouvelles lui répondit: "Me trouvant par hasard sur le mont Ghelboé, j’ai vu Saül appuyé sur sa lance; déjà les chars et les cavaliers l’avaient atteint.
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, “Mo wà ní orí òkè Gilboa níbẹ̀ ni Saulu fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.
7 En se retournant, il m’aperçut et m’appela. Je répondis: Me voici.
Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, ‘Kí ni mo lè ṣe?’
8 Il me dit: "Qui es-tu? Un Amalécite, répondis-je.
“Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’ “Mo dáhùn pé, ‘Ará a Amaleki.’
9 Eh bien, dit-il, place-toi auprès de moi et donne-moi la mort, car les affres m’ont saisi, bien que ma vie soit encore intacte."
“Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láààyè.’
10 Je m’approchai de lui et le tuai, car je savais qu’il ne survivrait pas à sa chute. Puis je pris le diadème qui ceignait sa tête et le bracelet qui ornait son bras, et je les apporte ici à mon seigneur."
“Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún olúwa mi.”
11 Alors David saisit ses vêtements et les déchira, et ainsi firent tous ceux qui étaient avec lui.
Nígbà náà ni, Dafidi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya.
12 Ils manifestèrent leur deuil, pleurèrent et jeûnèrent jusqu’au soir à cause de Saül et de Jonathan, son fils, du peuple de Dieu et de la maison d’Israël, qui avaient succombé sous le glaive.
Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti fún àwọn ọmọ-ogun Olúwa, àti fún àwọn ilé Israẹli, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà.
13 David dit encore au jeune homme qui lui avait fait le récit: "D’Où es-tu?" Il répondit: "Je suis fils d’un étranger, d’un Amalécite.
Dafidi sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?” O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Amaleki.”
14 Comment, lui dit David, n’as-tu pas craint de lever la main pour faire périr l’oint du Seigneur?"
Dafidi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni àmì òróró Olúwa?”
15 Puis David appela un des serviteurs et lui dit: "Approche, jette-toi sur lui!" Le serviteur le frappa à mort.
Nígbà náà Dafidi pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú.
16 Et David lui dit: "Ton sang retombe sur ta tête! Car ta propre bouche a déposé contre toi lorsque tu as dit: C’Est moi qui ai fait mourir l’oint du Seigneur."
Nítorí Dafidi wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé, ‘Mo pa ẹni àmì òróró Olúwa.’”
17 David composa cette élégie sur Saül et son fils Jonathan,
Dafidi sì fi orin ọ̀fọ̀ yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Saulu àti lórí Jonatani ọmọ rẹ̀,
18 et décida qu’on enseignerait aux fils de Juda le chant de l’Arc, qui est consigné dans le livre de Yachar:
Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Juda ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jaṣari):
19 "Oh! L’Orgueil d’Israël! Le voilà gisant sur les hauteurs! Comme ils sont tombés, les vaillants!
“Ògo rẹ, Israẹli ni a pa ní òkè gíga rẹ. Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!
20 Ne l’allez pas dire à Gath, ne le publiez pas dans les rues d’Ascalon; elles pourraient s’en réjouir, les filles des Philistins, elles en triompheraient, les filles des impurs!
“Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gati, ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Aṣkeloni, kí àwọn ọmọbìnrin Filistini má bá à yọ̀, kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má ba à dunnú.
21 Montagnes de Ghelboé, plus de rosée, plus de pluie sur vous, plus de campagnes riches en offrande! Car là fut déshonoré le bouclier des forts, le bouclier de Saül, qui plus jamais ne sera oint d’huile!
“Ẹ̀yin òkè Gilboa, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé, asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.
22 Devant le sang des blessés, devant la graisse des guerriers, l’arc de Jonathan ne reculait point, ni l’épée de Saül ne revenait à vide.
“Ọrun Jonatani kì í padà bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í padà lásán, láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa, àti ẹran àwọn alágbára.
23 Saül et Jonathan, chéris et aimables durant leur vie, n’ont pas été séparés par la mort; plus prompts que les aigles, plus courageux que les lions!
Saulu àti Jonatani— ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn, ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n. Wọ́n yára ju idì lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.
24 Filles d’Israël, pleurez Saül, qui vous habillait richement de pourpre, qui ajoutait des joyaux d’or à votre parure!
“Ẹ̀yin ọmọbìnrin Israẹli, ẹ sọkún lórí Saulu, ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín, ẹni tí ó fi wúrà sí ara aṣọ yín.
25 Comme ils sont tombés, les vaillants, en plein combat; tombé mort, Jonathan, sur tes hauteurs!
“Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun! Jonatani, ìwọ tí a pa ní òkè gíga.
26 Jonathan, mon frère, ta perte m’accable, tu m’étais si cher! Ton affection m’était précieuse plus que l’amour des femmes…
Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jonatani arákùnrin mi; ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi. Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu, ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ.
27 Comme ils sont tombés, ces vaillants, et perdues, ces armes de guerre!"
“Wò ó bí alágbára ti ṣubú! Ohun ìjà sì ti ṣègbé!”

< 2 Samuel 1 >