< Jérémie 24 >
1 Yahweh me fit voir, et voici deux paniers de figues posés devant le temple de Yahweh; — c’était après que Nabuchodonosor, roi de Babylone, eut emmené captif de Jérusalem à Babylone Jéchonias, fils de Joakim, roi de Juda, les chefs de Juda, les charpentiers et les serruriers; —
Lẹ́yìn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli tán. Olúwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa.
2 l’un des paniers contenait de très bonnes figues comme le sont les figues de la première récolte; l’autre panier, des figues très mauvaises, qu’on ne pouvait manger, tant elles étaient mauvaises.
Agbọ̀n kan ni èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára bí èyí tí ó tètè pọ́n; èkejì sì ní èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú rékọjá tí kò sì le è ṣe é jẹ.
3 Et Yahweh me dit: « Que vois-tu Jérémie? » Et je répondis: « Des figues; les bonnes figues sont très bonnes, les mauvaises sont très mauvaises et ne peuvent être mangées, tant elles sont mauvaises. »
Nígbà náà ni Olúwa bi mí pé, “Kí ni ìwọ rí Jeremiah?” Mo dáhùn pe, “Èso ọ̀pọ̀tọ́.” Mo dáhùn. “Èyí tí ó dáradára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ.”
4 Et la parole de Yahweh me fut adressée en ces termes:
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
5 Ainsi parle Yahweh, Dieu d’Israël: Comme on regarde ces bonnes figues, ainsi je regarderai avec faveur les captifs de Juda, que j’ai envoyés de ce lieu au pays des Chaldéens.
“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjèjì láti Juda sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kaldea.
6 Je dirigerai sur eux mes regards pour leur bien, et je les ramènerai dans ce pays; je les établirai pour ne plus les détruire; je les planterai pour ne plus les arracher.
Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere, Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu.
7 Je leur donnerai un cœur pour me connaître et savoir que je suis Yahweh; ils seront mon peuple et je serai leur Dieu, car ils reviendront à moi de tout leur cœur.
Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, “Èmi ni Olúwa.” Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
8 Et comme on traite les mauvaises figues, qu’on ne mange pas, tant elles sont mauvaises — ainsi parle Yahweh, — ainsi je traiterai Sédécias, roi de Juda, ses princes et le reste de Jérusalem, ceux qui sont demeurés dans ce pays, et ceux qui habitent au pays d’Égypte.
“‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Sedekiah ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jerusalẹmu, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Ejibiti.
9 J’en ferai un objet d’horreur, un malheur, dans tous les royaumes de la terre, un opprobre, une fable, une risée, une malédiction, dans tous les lieux où je les chasserai.
Èmi yóò sọ wọ́n di ìwọ̀sí àti ẹni ibi nínú gbogbo ìjọba ayé, láti di ẹni ìfibú àti ẹni òwe, ẹni ẹ̀sín, àti ẹni ẹ̀gàn ní ibi gbogbo tí Èmi ó lé wọn sí.
10 Et j’enverrai sur eux l’épée, la famine et la peste jusqu’à ce qu’ils aient disparu du sol que j’avais donné à eux et à leurs pères.
Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí wọn, títí tí gbogbo wọn yóò parun lórí ilẹ̀ tí a fún wọn àti fún àwọn baba wọn.’”