< Osée 12 >
1 Ephraïm se repaît de vent, et il court après le vent d'orient. Tout le jour il accumule le mensonge et la violence; ils concluent alliance avec Assur, et l'huile est transportée en Egypte.
Efraimu ń jẹ afẹ́fẹ́; o ń lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀-oòrùn ní gbogbo ọjọ́. O sì ń gbèrú nínú irọ́ o dá májẹ̀mú pẹ̀lú Asiria o sì fi òróró olifi ránṣẹ́ sí Ejibiti.
2 Yahweh a aussi procès avec Juda; il va châtier Jacob selon ses voies, il lui rendra selon ses œuvres.
Olúwa ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò, yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.
3 Dans le sein de sa mère, Jacob supplanta son frère, et dans sa vigueur il lutta avec Dieu.
Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run
4 Il lutta avec l'ange et il eut le dessus; il pleura et lui demanda grâce; il le trouva ensuite à Béthel, et là Dieu a parlé avec nous.
Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀, o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀. Ó bá Olúwa ní Beteli, Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,
5 Or Yahweh est le Dieu des armées, son nom est Yahweh.
àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀.
6 Et toi, tu reviendras à ton Dieu; garde la bonté et la justice, et espère en ton Dieu toujours.
Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀; di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
7 Chanaan tient dans sa main une balance fausse, il aime à extorquer.
Oníṣòwò ń lo òsùwọ̀n èké o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ.
8 Ephraïm dit: " Pourtant je me suis enrichi, je me suis fait une fortune; dans tous mes gains, on ne trouvera pas pour moi un tort qui soit un péché. "
Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”
9 Et moi je suis Yahweh, ton Dieu, depuis le pays d'Egypte; je te ferai encore habiter dans les tentes, comme aux jours de fête.
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ; ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti; èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́ bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì.
10 Et j'ai parlé aux prophètes, et moi, j'ai multiplié la vision; et, par l'intermédiaire des prophètes, j'ai parlé en paraboles.
Mo sọ fún àwọn wòlíì, mo fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran hàn wọ́n mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”
11 Si Galaad est vanité, ils ne seront que néant; à Galgal, ils ont sacrifié des taureaux; aussi leurs autels seront comme des monceaux de pierres, sur les sillons des champs.
Gileadi ha burú bí? Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán. Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rú ẹbọ ní Gilgali? Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko.
12 Jacob s'enfuit dans la plaine d'Aram; Israël servit pour une femme, et pour une femme il garda les troupeaux.
Jakọbu sálọ si orílẹ̀-èdè Aramu; Israẹli sìn kí o tó fẹ́ ìyàwó ó ṣe ìtọ́jú ẹran láti fi san owó ìyàwó.
13 Et par un prophète, Yahweh fit monter Israël hors d'Egypte, et par un prophète il fut gardé.
Olúwa lo wòlíì kan láti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, nípasẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
14 Ephraïm a provoqué amèrement la colère divine; Il laissera tomber son sang sur lui, et son Seigneur lui rendra son outrage.
Ṣùgbọ́n Efraimu ti mú un bínú gidigidi; Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sí orí rẹ̀ òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.