< Amos 1 >
1 Paroles d'Amos, qui fut parmi les bergers de Thécué. Ce qu'il a vu au sujet d'Israël, dans les jours d'Ozias, roi de Juda, et dans les jours de Jéroboam, fils de Joas, roi d'Israël, deux ans avant le tremblement de terre.
Àwọn ọ̀rọ̀ Amosi, ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn Tekoa; ohun tí o rí nípa Israẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí Ussiah ọba Juda àti Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli.
2 Il dit: Yahweh rugira de Sion; de Jérusalem il fera entendre sa voix; les pâturages des bergers seront en deuil, et le sommet du Carmel sera desséché.
Ó wí pé, “Olúwa yóò bú jáde láti Sioni, ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá; ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, orí òkè Karmeli yóò sì rọ.”
3 Ainsi parle Yahweh: A cause de trois crimes de Damas, et à cause de quatre, — je ne le révoquerai point. Parce qu'ils ont broyé Galaad avec des traîneaux de fer,
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú,
4 j'enverrai le feu dans la maison d'Hazaël, et il dévorera les palais de Ben-Hadad;
Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli, èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run.
5 je briserai le verrou de Damas, j'exterminerai de Biqath-Aven l'habitant, et de Beth-Eden, celui qui tient le sceptre; et le peuple de Syrie ira captif à Qir, dit Yahweh.
Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní àfonífojì Afeni run àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni. Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,” ni Olúwa wí.
6 Ainsi parle Yahweh: A cause de trois crimes de Gaza, et à cause de quatre, — je ne le révoquerai point. Parce qu'ils ont déporté des convois entiers de captifs, pour les livrer à Edom,
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú, ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn. Ó sì tà wọ́n fún Edomu,
7 j'enverrai le feu dans les murs de Gaza, et il dévorera ses palais;
Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run.
8 j'exterminerai d'Azot l'habitant, et d'Ascalon celui qui tient le sceptre, et je tournerai ma main sur Accaron; et le reste des Philistins périra, dit le Seigneur Yahweh.
Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò, ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú. Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
9 Ainsi parle Yahweh: A cause de trois crimes de Tyr, et à cause de quatre, — je ne le révoquerai point. Parce qu'ils ont livré des convois entiers de captifs à Edom, et ne se sont pas souvenus de l'alliance fraternelle,
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu. Wọn kò sì náání májẹ̀mú ọbàkan,
10 j'enverrai le feu sur le mur de Tyr, et il dévorera ses palais.
Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire, tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”
11 Ainsi parle Yahweh: A cause de trois crimes d'Edom, et à cause de quatre, — je ne le révoquerai point. Parce qu'il a poursuivi son frère avec le glaive, et qu'il a étouffé sa compassion, et parce que sa colère déchire à jamais, et qu'il garde jusqu'à la fin sa rancune,
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀, Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù, ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí, ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́,
12 j'enverrai le feu dans Théman, et il dévorera les palais de Bosra.
Èmi yóò rán iná sí orí Temani, tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”
13 Ainsi parle Yahweh: A cause de trois crimes des enfants d'Ammon, et à cause de quatre, — je ne le révoquerai point. Parce qu'ils ont fendu le ventre des femmes enceintes de Galaad, afin d'élargir leur frontière,
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni, àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.
14 j'allumerai un feu sur le mur de Rabbah, et il dévorera ses palais, au milieu des cris de guerre d'un jour de bataille, au milieu du tourbillon d'un jour de tempête.
Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun, pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà.
15 Et leur roi s'en ira en captivité, lui et ses princes avec lui, dit Yahweh.
Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn, òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,” ni Olúwa wí.