< 2 Chroniques 4 >

1 Salomon fit un autel d’airain; sa longueur était de vingt coudées, sa largeur de vingt coudées, et sa hauteur de dix coudées.
Ó ṣe pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga.
2 Il fit la mer d’ airain fondu. Elle avait dix coudées d’un bord à l’autre, elle était entièrement ronde; sa hauteur était de cinq coudées, et un cordon de trente coudées mesurait sa circonférence.
Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni gíga rẹ̀.
3 Des figures de bœufs l’entouraient au-dessous du bord, dix par coudée, faisant tout le tour de la mer, sur deux rangs; les bœufs étaient fondus avec elle en une seule pièce.
Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn.
4 Elle était posée sur douze bœufs, dont trois regardaient le nord, trois regardaient l’occident, trois regardaient le midi et trois regardaient l’orient; la mer était sur eux, et toute la partie postérieure de leur corps était cachée en dedans.
Okùn náà dúró lórí akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà-oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárín.
5 Son épaisseur était d’un palme, et son bord était semblable au bord d’une coupe, à une fleur de lis. Elle pouvait contenir trois mille baths.
Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta bati dúró.
6 Il fit dix bassins, et en plaça cinq à droite et cinq à gauche pour qu’on s’y lave; on y nettoyait ce qui devait être offert en holocauste. La mer était destinée aux purifications des prêtres.
Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan.
7 Il fit les dix chandeliers d’or, selon les prescriptions faites à leur égard, et il les plaça dans le Temple, cinq à droite et cinq à gauche.
Ó ṣe ìgbé fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá.
8 Il fit dix tables, et il les mit dans le Temple, cinq à droite et cinq à gauche. Il fit cent coupes d’or.
Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rùn-ún ọpọ́n ìbùwọ́n wúrà.
9 Il fit le parvis des prêtres et la grande cour, avec les portes pour la cour; il couvrit leurs battants d’airain.
Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ.
10 Il plaça la mer du côté droit, à l’est, vers le sud.
Ó gbé Òkun náà ka orí ìhà gúúsù ní ẹ̀bá igun gúúsù àríwá.
11 Hiram fit les pots, les pelles et les coupes. C’est ainsi qu’ Hiram acheva l’ouvrage qu’il fit pour le roi Salomon dans la maison de Dieu:
Huramu ṣe àwọn ìkòkò pẹ̀lú, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni Huramu parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Solomoni ní ilé Ọlọ́run.
12 les deux colonnes, les bourrelets et les chapiteaux qui sont sur le sommet des colonnes; les deux treillis pour couvrir les deux bourrelets des chapiteaux qui sont sur le sommet des colonnes;
Àwọn ọ̀wọ́n méjì; ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ́n iṣẹ́; àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n;
13 les quatre cents grenades pour les deux treillis, deux rangées de grenades par treillis, pour couvrir les deux bourrelets des chapiteaux qui sont sur les colonnes.
irinwó pomegiranate fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì náà, ẹsẹ̀ méjì pomegiranate ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lórí àwọn òpó náà;
14 Il fit les bases; il fit les bassins sur les bases;
ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn;
15 la mer et les douze bœufs au-dessous;
agbada ńlá kan àti màlúù méjìlá lábẹ́ rẹ̀;
16 les pots, les pelles et les fourchettes. Maître Hiram fit tous ces ustensiles pour le roi Salomon, pour la maison de Yahweh; ils étaient d’airain poli.
àwọn ìkòkò àti ọ̀kọ̀ àti àmúga ẹran àti gbogbo ohun èlò tí ó fi ara pẹ́ ẹ. Gbogbo ohun èlò ti Huramu-Abi fi idẹ dídán ṣe fún Solomoni ọba, fún ilé Olúwa jẹ́ idẹ dídán.
17 Le roi les fit fondre dans la plaine du Jourdain, dans un sol argileux, entre Sochot et Saréda.
Ọba dà wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ní àárín méjì Sukkoti àti Sereda.
18 Salomon fit tous ces ustensiles en très grande quantité, car le poids de l’airain ne fut pas vérifié.
Gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Solomoni ṣe ní iye lórí púpọ̀ tí a kò le mọ ìwọ̀n iye idẹ tí ó wọ́n.
19 Salomon fit encore tous les autres ustensiles pour la maison de Dieu: l’autel d’or; les tables sur lesquelles on mettait les pains de proposition;
Solomoni pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run: pẹpẹ wúrà tábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀;
20 les chandeliers avec leurs lampes d’or pur, pour que, selon la loi, on les allume devant le sanctuaire;
àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀;
21 les fleurs, les lampes et les mouchettes d’or, d’un or très pur;
pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú ni ó jẹ́ kìkìdá wúrà tí ó gbópọn;
22 les couteaux, les coupes, les tasses et les encensoirs d’or pur, ainsi que les battants d’or pour la porte intérieure de la maison à l’entrée du Saint des saints, et pour la porte de la maison à l’entrée du temple.
pẹ̀lú ọ̀pá fìtílà, àti àwokòtò àti ṣíbí àti àwokòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹmpili, àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí Ibi Mímọ́ Jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn à bá wọ inú gbọ̀ngàn ńlá.

< 2 Chroniques 4 >