< Osée 1 >
1 Parole de Yahweh qui fut adressée à Osée, fils de Béeri, dans les jours d’Ozias, de Joatham, d’Achaz, d’Ezéchias, rois de Juda, et dans les jours de Jéroboam, fils de Joas, roi d’Israël.
Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli.
2 Lorsque Yahweh commença à parler à Osée, Yahweh dit à Osée: « Va, prends une femme de prostitution et des enfants de prostitution, car le pays ne fait que se prostituer en abandonnant Yahweh. »
Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.”
3 Il alla et prit Gomer, fille de Débelaïm; elle conçut et lui enfanta un fils.
Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gomeri ọmọbìnrin Diblaimu, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.
4 Et Yahweh lui dit: « Nomme-le Jezrahel, car encore un peu de temps et je punirai le sang de Jezrahel sur la maison de Jéhu, et je mettrai fin à la royauté de la maison d’Israël.
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hosea pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jesreeli, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jehu ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jesreeli, Èmi yóò sì mú ìjọba Israẹli wá sí òpin.
5 En ce jour-là je briserai l’arc d’Israël dans la plaine de Jezrahel. »
Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò ṣẹ́ ọrun Israẹli ní àfonífojì Jesreeli.”
6 Elle conçut encore et enfanta une fille; et Yahweh dit à Osée: « Nomme-la Lô-Ruchama, car je n’aurai plus compassion de la maison d’Israël pour lui pardonner ses péchés.
Gomeri sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Olúwa sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ruhama, nítorí pé, Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Israẹli mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n.
7 Mais j’aurai compassion de la maison de Juda, et je les sauverai par Yahweh, leur Dieu; je ne les sauverai ni par l’arc et l’épée, ni par le combat, ni par les chevaux et les cavaliers. »
Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.”
8 Elle sevra Lô-Ruchama; puis elle conçut et enfanta un fils.
Lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ọmú lẹ́nu Lo-ruhama, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni
9 Et Yahweh dit à Osée: « Nomme-le Lô-Ammi, car vous n’êtes pas mon peuple, et moi je ne serai pas votre Dieu. »
Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.
10 Le nombre des enfants d’Israël sera comme le sable de la mer, qui ne se mesure, ni ne se compte; et au lieu où on leur disait: « Vous n’êtes pas mon peuple, » on leur dira: « Fils du Dieu vivant!
“Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘Ọmọ Ọlọ́run alààyè.’
11 Et les enfants de Juda et les enfants d’Israël se réuniront, ils se donneront un même chef et monteront hors du pays, car grande sera la journée de Jezrahel.
Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.