< Malachie 4 >

1 « Car voici, le jour vient, brûlant comme une fournaise, où tous les orgueilleux et tous les méchants seront du chaume. Le jour qui vient les consumera, dit Yahvé des Armées, et il ne leur laissera ni racine ni rameau.
“Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀; tí yóò máa jó bi iná ìléru. Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn.
2 Mais pour vous qui craignez mon nom, le soleil de la justice se lèvera, la guérison dans ses ailes. Vous sortirez et vous sauterez comme des veaux de l'étable.
Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.
3 Vous foulerez les méchants, car ils seront comme de la cendre sous la plante de vos pieds, au jour que je ferai, dit Yahvé des armées.
Ẹ̀yin yóò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀: nítorí wọn yóò di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
4 « Souviens-toi de la loi de Moïse, mon serviteur, que je lui ai prescrite en Horeb pour tout Israël, lois et ordonnances.
“Ẹ rántí òfin Mose ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Horebu fún gbogbo Israẹli.”
5 Voici, je vais vous envoyer Élie le prophète avant que ne vienne le jour grand et terrible de Yahvé.
“Wò ó, èmi yóò rán wòlíì Elijah sí i yín, ki ọjọ́ ńlá, ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa to dé.
6 Il tournera le cœur des pères vers les enfants et le cœur des enfants vers leurs pères, de peur que je ne vienne frapper la terre de malédiction. »
Òun yóò sì pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sì ti àwọn baba wọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò wá, èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà gégùn.”

< Malachie 4 >