< Exode 38 >
1 Il fit l'autel des holocaustes en bois d'acacia. Il était carré. Sa longueur était de cinq coudées, sa largeur de cinq coudées, et sa hauteur de trois coudées.
Ó sì fi igi kasia kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, igun rẹ̀ ṣe déédé.
2 Il fit ses cornes aux quatre coins. Ses cornes étaient d'un seul tenant avec lui, et il le couvrit d'airain.
Ó ṣe ìwo sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, nítorí kí ìwo àti pẹpẹ náà lè jẹ́ ọ̀kan, ó sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ.
3 Il fit tous les ustensiles de l'autel: les marmites, les pelles, les bassins, les fourchettes et les brasiers. Il fit tous ses ustensiles en bronze.
Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi n mú ẹran àti àwo iná rẹ̀.
4 Il fit pour l'autel une grille d'un réseau de bronze, sous le rebord qui l'entoure en bas, et qui atteint la moitié de sa hauteur.
Ó ṣe ààrò fún pẹpẹ náà, àwọ̀n onídẹ, kí ó wà níṣàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, dé ìdajì òkè pẹpẹ náà.
5 Il fondit quatre anneaux aux quatre coins de la grille d'airain, pour servir de support aux poteaux.
Ó dá òrùka idẹ láti mú kí ó di òpó igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin idẹ ààrò náà mú.
6 Il fit les poteaux de bois d'acacia, et les recouvrit de bronze.
Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn òpó náà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú idẹ.
7 Il plaça les perches dans les anneaux situés sur les côtés de l'autel, pour le porter. Il le rendit creux avec des planches.
Ó sì fi òpó náà bọ inú òrùka, nítorí kí ó lè wà ní ìhà pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó sì fi pákó ṣé pẹpẹ náà ní oníhò nínú.
8 Il fit le bassin d'airain et sa base d'airain, avec les miroirs des servantes qui faisaient le service à l'entrée de la tente de la Rencontre.
Ó ṣe agbada idẹ, o sì fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀ ti àwòjìji àwọn obìnrin tí ó ń sìn ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ.
9 Il fit le parvis. Du côté du midi, les toiles du parvis étaient de fin lin retors, de cent coudées.
Ó sì ṣe àgbàlá inú náà. Ní ìhà gúúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn,
10 Les colonnes étaient au nombre de vingt, et les bases au nombre de vingt, en bronze; les crochets des colonnes et leurs tringles étaient en argent.
pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.
11 Pour le côté septentrional, il y avait cent coudées; leurs vingt colonnes et leurs vingt bases étaient en bronze; les crochets des colonnes et leurs tringles étaient en argent.
Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.
12 Pour le côté occidental, il y avait des tentures de cinquante coudées, avec dix colonnes et dix bases, les crochets des colonnes et leurs tringles étant en argent.
Ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀.
13 Pour le côté oriental, vers l'est, il y avait cinquante coudées;
Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀.
14 pour un côté, les tentures avaient quinze coudées, leurs colonnes trois, et leurs bases trois;
Aṣọ títa ìhà ẹnu-ọ̀nà kan jẹ́ mita mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,
15 et de même pour l'autre côté: d'un côté et de l'autre, à la porte du parvis, il y avait des tentures de quinze coudées, leurs colonnes trois, et leurs bases trois.
àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mita mẹ́fà ààbọ̀ pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà.
16 Toutes les tentures qui entouraient le parvis étaient de fin lin retors.
Gbogbo aṣọ tí ó yí àgbàlá náà jẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.
17 Les bases des colonnes étaient en bronze. Les crochets des colonnes et leurs filets étaient d'argent. Leurs chapiteaux étaient recouverts d'argent. Tous les piliers du parvis avaient des bandes d'argent.
Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni. Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà; gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà.
18 Le rideau de la porte du parvis était un ouvrage de broderie, en bleu, pourpre et cramoisi, et en fin lin retors. Sa longueur était de vingt coudées, et sa hauteur dans le sens de la largeur était de cinq coudées, comme les toiles du parvis.
Aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe; ogún ìgbọ̀nwọ́ sì ni gígùn rẹ̀, àti gíga rẹ̀ ní ìbò rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó bá aṣọ títa àgbàlá wọ̀n-ọn-nì ṣe déédé,
19 Les colonnes étaient au nombre de quatre, et les socles au nombre de quatre, en bronze; les crochets étaient en argent, et les garnitures des chapiteaux et les filets étaient en argent.
pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà.
20 Tous les pieux du tabernacle et du parvis étaient d'airain.
Gbogbo èèkàn àgọ́ tabanaku náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ.
21 Voici les quantités de matériaux utilisés pour le tabernacle, le tabernacle du témoignage, telles qu'elles ont été comptées, selon l'ordre de Moïse, pour le service des Lévites, par Ithamar, fils du prêtre Aaron.
Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabanaku náà, tabanaku ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mose nípa àwọn ọmọ Lefi ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni àlùfáà.
22 Betsaleel, fils d'Uri, fils de Hur, de la tribu de Juda, fit tout ce que Yahvé avait ordonné à Moïse.
(Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, ṣe ohun gbogbo ti Olúwa pàṣẹ fún Mose.
23 Il avait avec lui Oholiab, fils d'Ahisamach, de la tribu de Dan, graveur, habile ouvrier, et brodeur en bleu, en pourpre, en cramoisi et en fin lin.
Pẹ̀lú rẹ̀ ni Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani: alágbẹ̀dẹ, àti oníṣẹ́-ọnà àti oníṣọ̀nà tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ní aṣọ aláró àti elése àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.)
24 Tout l'or qui servit à l'exécution de tous les travaux du sanctuaire, l'or des offrandes, fut de vingt-neuf talents et sept cent trente sicles, selon le sicle du sanctuaire.
Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ǹtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti òjìlélẹ́ẹ̀gbẹ́rín ó dín mẹ́wàá ṣékélì gẹ́gẹ́ bí i ṣékélì ibi mímọ́.
25 L'argent de ceux qui étaient comptés dans l'assemblée était de cent talents et de mille sept cent soixante-quinze sicles, selon le sicle du sanctuaire:
Fàdákà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì àti òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,
26 un beka par tête, c'est-à-dire un demi-sicle, selon le sicle du sanctuaire, pour tous ceux qui passaient à l'appel de l'assemblée, depuis l'âge de vingt ans et au-dessus, soit six cent trois mille cinq cent cinquante hommes.
ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ lé ẹgbẹ̀tadínlógún ó lé àádọ́jọ ọkùnrin.
27 Les cent talents d'argent étaient destinés à couler les socles du sanctuaire et les socles du voile: cent socles pour les cent talents, un talent par socle.
Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùn-ún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì náà tálẹ́ǹtì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.
28 Avec les mille sept cent soixante-quinze sicles, il fit des crochets pour les piliers, recouvrit leurs chapiteaux et leur fit des filets.
Ó lo òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣékélì ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ọ̀já wọn.
29 Le bronze de l'offrande était de soixante-dix talents et de deux mille quatre cents sicles.
Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ǹtì àti egbèjìlá ṣékélì.
30 Il fit avec cela les socles de l'entrée de la tente d'assignation, l'autel d'airain, sa grille d'airain, tous les ustensiles de l'autel,
Ó lò ó láti fi ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, pẹpẹ idẹ náà pẹ̀lú ààrò idẹ rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,
31 les socles du parvis, les socles de la porte du parvis, toutes les broches du tabernacle et toutes les broches du parvis.
ihò ìtẹ̀bọ̀ àgbàlá náà àyíká àti ihò ìtẹ̀bọ̀ ẹnu-ọ̀nà àgbàlá àti gbogbo èèkàn àgọ́ náà, àti gbogbo èèkàn àgbàlá náà yíká.