< Hesekielin 5 >
1 Ja sinä, ihmisen lapsi, ota sinulles niin terävä miekka kuin partaveitsi, ja keritse sillä pääs ja partas; ja ota vaaka ja jaa ne sillä.
“Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi ṣe abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in.
2 Kolmannen osan pitää sinun tulella polttaman keskellä kaupunkia, kuin piirittämisen päivät ovat täytetyt; toinen kolmas osa ota ja hakkaa miekalla kaupungin ympärillä; viimeinen kolmas osa heitä tuleen, että minä vetäisin miekan ulos heidän jälkeensä.
Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdákan nínú ìdámẹ́ta irun yìí níná láàrín ìlú. Mú ìdákan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdákan yòókù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká.
3 Mutta ota vähä niistä luvalla ja sido hamees kulmaan.
Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.
4 Ja ota taas vähä niistä, ja heitä se tuleen, ja polta se tulessa; siitä pitää tulen tuleman koko Israelin huoneesen.
Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Israẹli.
5 Näin sanoo Herra, Herra: tämä on Jerusalem, jonka minä pakanain keskelle asettanut olen, ja maakunnat hänen ympärillensä.
“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èyí ní Jerusalẹmu, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárín àwọn Orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.
6 Mutta hän on kääntänyt minun oikeuteni jumalattomuudeksi, enemmin kuin pakanat, ja minun säätyni enemmin kuin ne maakunnat, jotka hänen ympäristöllänsä ovat; sillä he heittävät minun oikeuteni pois, ja ei tahdo elää minun säätyini jälkeen.
Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, o kò sì pa ìlànà mi mọ́.
7 Sentähden sanoo Herra, Herra näin: että te enemmän pahuutta teette kuin pakanat, jotka ovat teidän ympärillänne, ja ette vaella minun säädyissäni, ettekä tee minun oikeuteni jälkeen, ette myös tee pakanainkaan oikeuden jälkeen, jotka ovat teidän ympärillänne:
“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká lọ, tí ẹ kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ túnṣe dáradára tó àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká.
8 Sentähden sanoo Herra, Herra näin: katso, minä tulen sinun tykös, minä myös tulen, ja tahdon tuomita sinun pakanain silmäin edessä.
“Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jerusalẹmu, èmi yóò sì jẹ ọ́ ní yà lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká.
9 Ja tahdon niin tehdä sinun kanssas, kuin en minä ikänä ennen tehnyt ole, enkä myös tästedes tehdä tahdo, kaikkein sinun kauhistustes tähden.
Nítorí gbogbo ohun ìríra rẹ, èmi yóò ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrín rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́.
10 Sentähden pitää isäin syömän lapsensa sinun keskelläs, ja lasten syömän isänsä. Ja tahdon sinun niin tuomita, että kaikki sinun jäänees pitää kaikkiin tuuliin hajoitetuksi tuleman.
Nítorí náà láàrín rẹ àwọn baba yóò máa jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. Èmi yóò jẹ ọ́ ní yà, èmi yóò sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú ẹ̀fúùfù.
11 Sentähden niin totta kuin minä elän, sanoo Herra, Herra: ettäs olet saastuttanut minun Pyhäni kaikilla sinun turmeluksillas ja kaikilla sinun kauhistuksillas, niin tahdon minä myös hukuttaa sinun pois, ja minun silmäni ei pidä sinua säästämän, ei myös armahtaman.
Nítorí náà, Olúwa Olódùmarè wí pé, bí mo ṣe wà láààyè, nítorí pé ìwọ ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, èmi yóò mú ojúrere mi kúrò lára rẹ, èmi kò ní í da ọ sí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́.
12 Kolmas osa sinusta pitää rutolla kuoleman ja nälkään nääntymän sinun keskelläs; ja toinen kolmas osa pitää lankeeman miekalla sinun ympäristölläs; ja sen viimeisen kolmannen osan tahdon minä hajoittaa kaikkiin tuuliin, ja vetää ulos miekan heidän jälkeensä.
Ìdámẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdámẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ, èmi yóò sì tú ìdámẹ́ta yòókù ká sínú ẹ̀fúùfù, èmi yóò sì máa fi idà lé wọn.
13 Näin pitää minun vihani täytetyksi tuleman, ja minun hirmuisuuteni saatan minä heidän päällensä, että minä saisin lohdutuksen; ja heidän pitää ymmärtämän, että minä Herra minun kiivaudessani puhunut olen, kuin minä hirmuisuuteni heissä täyttänyt olen.
“Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbóná mi yóò sì rọlẹ̀, èmi yóò sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi.
14 Minä tahdon saattaa sinun autioksi ja pilkaksi pakanoille, jotka sinun ympärilläs ovat, kaikkein niiden silmäin eteen, jotka käyvät sieltä ohitse.
“Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá.
15 Ja se häväistys ja pilkka pitää oleman opiksi ja ihmeeksi pakanoille, jotka ovat sinun ympärilläs, kuin minä annan oikeuteni käydä sinun päälles vihan, julmuuden ja rangaistusten kanssa. Minä Herra olen sen sanonut.
O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ẹ̀kọ̀ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
16 Ja kuin minä ne pahat nälän nuolet heidän sekaansa lähettävä olen, jotka vahingolliset oleman pitää, jotka minä lähetän hukkaamaan teitä; ja annan teille nälän enemmäksi ja enemmäksi tulla, ja ottaman pois leivän aineen.
Nígbà tí èmi ó rán ọfà búburú ìyàn sí wọn, èyí tí yóò jẹ́ fún ìparun wọn. Èmí tí èmi yóò rán run yín. Èmí yóò sì sọ ìyàn di púpọ̀ fún yín. Èmí yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ yín.
17 Ja nälän ja pahat pedot tahdon minä antaa tulla teidän sekaanne, ne pitää teitä tekemän lapsettomaksi. Ja siellä pitää ruton ja veren liikkuman sinun seassas ja miekan tahdon minä antaa tulla sinun päälles. Minä Herra olen sen sanonut.
Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ̀ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò kọjá láàrín yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi Olúwa ló sọ bẹ́ẹ̀.”