< Psalms 45 >
1 To the Overseer. — 'On the Lilies.' — By sons of Korah. — An Instruction. — A song of loves. My heart hath indited a good thing, I am telling my works to a king, My tongue [is] the pen of a speedy writer.
Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó. Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
2 Thou hast been beautified above the sons of men, Grace hath been poured into thy lips, Therefore hath God blessed thee to the age.
Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ: a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè: nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
3 Gird Thy sword upon the thigh, O mighty, Thy glory and Thy majesty!
Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
4 As to Thy majesty — prosper! — ride! Because of truth, and meekness — righteousness, And Thy right hand showeth Thee fearful things.
Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́; jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
5 Thine arrows [are] sharp, — Peoples fall under Thee — In the heart of the enemies of the king.
Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
6 Thy throne, O God, [is] age-during, and for ever, A sceptre of uprightness [Is] the sceptre of Thy kingdom.
Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
7 Thou hast loved righteousness and hatest wickedness, Therefore God, thy God, hath anointed thee, Oil of joy above thy companions.
Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ, nípa fífi àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
8 Myrrh and aloes, cassia! all thy garments, Out of palaces of ivory Stringed instruments have made thee glad.
Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia; láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
9 Daughters of kings [are] among thy precious ones, A queen hath stood at thy right hand, In pure gold of Ophir.
Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró nínú wúrà Ofiri.
10 Hearken, O daughter, and see, incline thine ear, And forget thy people, and thy father's house,
Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.
11 And the king doth desire thy beauty, Because he [is] thy lord — bow thyself to him,
Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi nítorí òun ni olúwa rẹ kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12 And the daughter of Tyre with a present, The rich of the people do appease thy face.
Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
13 All glory [is] the daughter of the king within, Of gold-embroidered work [is] her clothing.
Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀, iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
14 In divers colours she is brought to the king, Virgins — after her — her companions, Are brought to thee.
Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá, àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
15 They are brought with joy and gladness, They come into the palace of the king.
Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn wọ́n sì wọ ààfin ọba.
16 Instead of thy fathers are thy sons, Thou dost appoint them for princes in all the earth.
Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀ ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
17 I make mention of Thy name in all generations, Therefore do peoples praise Thee, To the age, and for ever!
Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.