< Psalms 44 >
1 To the Overseer. — By sons of Korah. An Instruction. O God, with our ears we have heard, Our fathers have recounted to us, The work Thou didst work in their days, In the days of old.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili. À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run; àwọn baba wa tí sọ fún wa ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn, ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
2 Thou, [with] Thy hand, nations hast dispossessed. And Thou dost plant them. Thou afflictest peoples, and sendest them away.
Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde, Ìwọ sì gbin àwọn baba wa; ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
3 For, not by their sword Possessed they the land, And their arm gave not salvation to them, But Thy right hand, and Thine arm, And the light of Thy countenance, Because Thou hadst accepted them.
Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ; àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.
4 Thou [art] He, my king, O God, Command the deliverances of Jacob.
Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
5 By Thee our adversaries we do push, By Thy name tread down our withstanders,
Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú; nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,
6 For, not in my bow do I trust, And my sword doth not save me.
èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi, idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
7 For Thou hast saved us from our adversaries, And those hating us Thou hast put to shame.
ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa, ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
8 In God we have boasted all the day, And Thy name to the age we thank. (Selah)
Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́, àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. (Sela)
9 In anger Thou hast cast off and causest us to blush, And goest not forth with our hosts.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá, Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
10 Thou causest us to turn backward from an adversary, And those hating us, Have spoiled for themselves.
Ìwọ ti bá wa jà, ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa, àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa, wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
11 Thou makest us food like sheep, And among nations Thou hast scattered us.
Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn, Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
12 Thou sellest Thy people — without wealth, And hast not become great by their price.
Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré, Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.
13 Thou makest us a reproach to our neighbours, A scorn and a reproach to our surrounders.
Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14 Thou makest us a simile among nations, A shaking of the head among peoples.
Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15 All the day my confusion [is] before me, And the shame of my face hath covered me.
Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́, ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16 Because of the voice of a reproacher and reviler, Because of an enemy and a self-avenger.
nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.
17 All this met us, and we did not forget Thee, Nor have we dealt falsely in Thy covenant.
Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
18 We turn not backward our heart, Nor turn aside doth our step from Thy path.
Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
19 But Thou hast smitten us in a place of dragons, And dost cover us over with death-shade.
Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá, ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú, tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.
20 If we have forgotten the name of our God, And spread our hands to a strange God,
Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21 Doth not God search out this? For He knoweth the secrets of the heart.
Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
22 Surely, for Thy sake we have been slain all the day, Reckoned as sheep of the slaughter.
Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́ a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.
23 Stir up — why dost Thou sleep, O Lord? Awake, cast us not off for ever.
Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn? Dìde fúnra rẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24 Why Thy face hidest Thou? Thou forgettest our afflictions and our oppression,
Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́ tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?
25 For bowed to the dust hath our soul, Cleaved to the earth hath our belly.
Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku; ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26 Arise, a help to us, And ransom us for thy kindness' sake.
Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́; rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.