< Job 7 >

1 Is there not a warfare to man on earth? And as the days of an hireling his days?
“Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀? Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe?
2 As a servant desireth the shadow, And as a hireling expecteth his wage,
Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji, àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀.
3 So I have been caused to inherit months of vanity, And nights of misery they numbered to me.
Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.
4 If I lay down then I said, 'When do I rise!' And evening hath been measured, And I have been full of tossings till dawn.
Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’ Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síyìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.
5 Clothed hath been my flesh [with] worms, And a clod of dust, My skin hath been shrivelled and is loathsome,
Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ, awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.
6 My days swifter than a weaving machine, And they are consumed without hope.
“Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ, o sì di lílò ní àìní ìrètí.
7 Remember Thou that my life [is] a breath, Mine eye turneth not back to see good.
Háà! Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi; ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.
8 The eye of my beholder beholdeth me not. Thine eyes [are] upon me — and I am not.
Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́; ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.
9 Consumed hath been a cloud, and it goeth, So he who is going down to Sheol cometh not up. (Sheol h7585)
Bí ìkùùkuu tí i túká, tí í sì fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́. (Sheol h7585)
10 He turneth not again to his house, Nor doth his place discern him again.
Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.
11 Also I — I withhold not my mouth — I speak in the distress of my spirit, I talk in the bitterness of my soul.
“Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́, èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi, èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.
12 A sea -[monster] am I, or a dragon, That thou settest over me a guard?
Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú, tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?
13 When I said, 'My bed doth comfort me,' He taketh away in my talking my couch.
Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára, ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú.
14 And thou hast affrighted me with dreams, And from visions thou terrifiest me,
Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi, ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí.
15 And my soul chooseth strangling, Death rather than my bones.
Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.
16 I have wasted away — not to the age do I live. Cease from me, for my days [are] vanity.
O sú mi, èmi kò le wà títí: jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.
17 What [is] man that Thou dost magnify him? And that Thou settest unto him Thy heart?
“Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀? Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e?
18 And inspectest him in the mornings, In the evenings dost try him?
Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀, ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkígbà!
19 How long dost Thou not look from me? Thou dost not desist till I swallow my spittle.
Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ, tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì.
20 I have sinned, what do I to Thee, O watcher of man? Why hast Thou set me for a mark to Thee, And I am for a burden to myself — and what?
Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó ṣe sí ọ. Ìwọ Olùsójú ènìyàn? Èéṣe tí ìwọ fi fi mí ṣe àmì itasi níwájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì di ẹrẹ̀ wíwo fún ọ?
21 Thou dost not take away my transgression, And cause to pass away mine iniquity, Because now, for dust I lie down: And Thou hast sought me — and I am not!
Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn, kí ìwọ kí ó sì mú àìṣedéédéé mi kúrò? Ǹjẹ́ nísinsin yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀, ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní òwúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”

< Job 7 >