< 1 Timothy 6 >

1 What euere seruauntis ben vndur yok, deme thei her lordis worthi al onour, lest the name of the Lord and the doctryn be blasfemyd.
Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.
2 And thei that han feithful lordis, dispise hem not, for thei ben britheren; but more serue thei, for thei ben feithful and louyd, whiche ben parceneris of benefice. Teche thou these thingis, and moneste thou these thingis.
Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú.
3 If ony man techith othere wise, and acordith not to the hoolsum wordis of oure Lord Jhesu Crist, and to that teching that is bi pitee,
Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jesu Kristi Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu,
4 he is proud, and kan no thing, but langwischith aboute questiouns and stryuyng of wordis, of the whiche ben brouyt forth enuyes, stryues, blasfemyes, yuele suspiciouns, fiytingis of men,
Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkan kan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀ búburú wá,
5 that ben corrupt in soule, and that ben pryued fro treuthe, that demen wynnyng to be pitee.
àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí.
6 But a greet wynnyng is pitee, with sufficience.
Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni.
7 For we brouyten in no thing in to this world, and no doute, that we moun not bere `awey ony thing.
Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ.
8 But we hauynge foodis, and with what thingus we schulen be hilid, be we paied with these thingis.
Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn.
9 For thei that wolen be maad riche, fallen in to temptacioun, and `in to snare of the deuel, and in to many vnprofitable desiris and noyous, whiche drenchen men in to deth and perdicioun.
Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.
10 For the rote of alle yuelis is coueytise, which summen coueitinge erriden fro the feith, and bisettiden hem with many sorewis.
Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.
11 But, thou, man of God, fle these thingis; but sue thou riytwisnesse, pite, feith, charite, pacience, myldenesse.
Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù.
12 Stryue thou a good strijf of feith, catche euerlastinge lijf, in to which thou art clepid, and hast knoulechid a good knouleching bifor many witnessis. (aiōnios g166)
Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀. (aiōnios g166)
13 I comaunde to thee bifor God, that quikeneth alle thingis, and bifor Crist Jhesu, that yeldide a witnessing vnder Pilat of Pounce, a good confessioun,
Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu,
14 that thou kepe the comaundement with out wem, with out repreef, in to the comyng of oure Lord Jhesu Crist;
kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.
15 whom the blessid and aloone miyti king of kyngis and Lord of lordis schal schewe in his tymes.
Èyí ti yóò fihàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa.
16 Which aloone hath vndeedlynesse, and dwellith in liyt, to which no man may come; whom no man say, nether may se; to whom glorie, and honour, and empire be with out ende. Amen. (aiōnios g166)
Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín. (aiōnios g166)
17 Comaunde thou to the riche men of this world, that thei vndurstonde not hiyli, nether that thei hope in vncerteynte of richessis, but in the lyuynge God, that yyueth to vs alle thingis plenteuously to vse; (aiōn g165)
Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; (aiōn g165)
18 to do wel, to be maad riche in good werkis, liytli to yyue, to comyne,
kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn;
19 to tresoure to hem silf a good foundement in to tyme to comynge, that thei catche euerlastinge lijf.
kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.
20 Thou Tymothe, kepe the thing bitakun to thee, eschewynge cursid noueltees of voicis, and opynyouns of fals name of kunnyng;
Timotiu, máa ṣọ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀;
21 which summen bihetinge, aboute the feith fellen doun. The grace of God be with thee. Amen.
èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ṣìnà ìgbàgbọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ.

< 1 Timothy 6 >