< Zephaniah 2 >

1 Gather yourselves together, yes, gather together, you nation that has no shame,
Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọ pọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú,
2 before the appointed time when the day passes as the chaff, before the fierce anger of the LORD comes on you, before the day of the LORD’s anger comes on you.
kí a tó pa àṣẹ náà, kí ọjọ́ náà tó kọjá bí ìyàngbò ọkà, kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín, kí ọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín.
3 Seek the LORD, all you humble of the land, who have kept his ordinances. Seek righteousness. Seek humility. It may be that you will be hidden in the day of the LORD’s anger.
Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pàṣẹ. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú, bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.
4 For Gaza will be forsaken, and Ashkelon a desolation. They will drive out Ashdod at noonday, and Ekron will be rooted up.
Nítorí pé, a ó kọ Gasa sílẹ̀, Aṣkeloni yóò sì dahoro. Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Aṣdodu jáde, a ó sì fa Ekroni tu kúrò.
5 Woe to the inhabitants of the sea coast, the nation of the Cherethites! The LORD’s word is against you, Canaan, the land of the Philistines. I will destroy you until there is no inhabitant.
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí Òkun, ẹ̀yin ènìyàn ara Kereti; ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kenaani, ilẹ̀ àwọn ara Filistini. “Èmi yóò pa yín run, ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín.”
6 The sea coast will be pastures, with cottages for shepherds and folds for flocks.
Ilẹ̀ náà ní etí Òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kereti, ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn.
7 The coast will be for the remnant of the house of Judah. They will find pasture. In the houses of Ashkelon, they will lie down in the evening, for the LORD, their God, will visit them and restore them.
Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Juda, níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí koríko fún ẹran. Ní ilé Aṣkeloni ni wọn yóò dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bẹ̀ wọn wò, yóò sì yí ìgbèkùn wọn padà.
8 I have heard the reproach of Moab and the insults of the children of Ammon, with which they have reproached my people and magnified themselves against their border.
“Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu, àti ẹlẹ́yà àwọn Ammoni, àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn.
9 Therefore, as I live, says the LORD of Hosts, the God of Israel, surely Moab will be as Sodom, and the children of Ammon as Gomorrah, a possession of nettles and salt pits, and a perpetual desolation. The remnant of my people will plunder them, and the survivors of my nation will inherit them.
Nítorí náà, bí Èmi tí wà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí, “nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu, àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra, ibi tí ó kún fún yèrèpè, àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé. Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn; àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn.”
10 This they will have for their pride, because they have reproached and magnified themselves against the people of the LORD of Hosts.
Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn, nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa àwọn ọmọ-ogun ṣe ẹlẹ́yà.
11 The LORD will be awesome to them, for he will famish all the gods of the land. Men will worship him, everyone from his place, even all the shores of the nations.
Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn; nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà run. Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn, olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá.
12 You Cushites also, you will be killed by my sword.
“Ẹ̀yin Etiopia pẹ̀lú, a ó fi idà mi pa yín.”
13 He will stretch out his hand against the north, destroy Assyria, and will make Nineveh a desolation, as dry as the wilderness.
Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí apá àríwá, yóò sì pa Asiria run, yóò sì sọ Ninefe di ahoro, àti di gbígbẹ bí aginjù.
14 Herds will lie down in the middle of her, all kinds of animals. Both the pelican and the porcupine will lodge in its capitals. Their calls will echo through the windows. Desolation will be in the thresholds, for he has laid bare the cedar beams.
Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ni àárín rẹ̀, àti gbogbo ẹranko àwọn orílẹ̀-èdè. Òwìwí aginjù àti ti n kígbe ẹyẹ òwìwí yóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ̀n rẹ̀. Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé, ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu-ọ̀nà, òun yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá kedari sílẹ̀.
15 This is the joyous city that lived carelessly, that said in her heart, “I am, and there is no one besides me.” How she has become a desolation, a place for animals to lie down in! Everyone who passes by her will hiss and shake their fists.
Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu. Ó sì sọ fun ara rẹ̀ pé, “Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi.” Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́, ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó! Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn.

< Zephaniah 2 >