< Psalms 138 >
1 By David. I will give you thanks with my whole heart. Before the gods, I will sing praises to you.
Ti Dafidi. Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo; níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2 I will bow down towards your holy temple, and give thanks to your Name for your loving kindness and for your truth; for you have exalted your Name and your Word above all.
Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ; nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
3 In the day that I called, you answered me. You encouraged me with strength in my soul.
Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn, ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
4 All the kings of the earth will give you thanks, LORD, for they have heard the words of your mouth.
Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́, Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.
5 Yes, they will sing of the ways of the LORD, for the LORD’s glory is great!
Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa; nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.
6 For though the LORD is high, yet he looks after the lowly; but he knows the proud from afar.
Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7 Though I walk in the middle of trouble, you will revive me. You will stretch out your hand against the wrath of my enemies. Your right hand will save me.
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè; ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
8 The LORD will fulfil that which concerns me. Your loving kindness, LORD, endures forever. Don’t forsake the works of your own hands.
Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé; Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé; má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.