< Job 34 >

1 Moreover Elihu answered,
Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé,
2 “Hear my words, you wise men. Give ear to me, you who have knowledge.
“Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye.
3 For the ear tries words, as the palate tastes food.
Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò.
4 Let us choose for us that which is right. Let us know among ourselves what is good.
Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa; ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa.
5 For Job has said, ‘I am righteous, God has taken away my right.
“Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi; Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.
6 Notwithstanding my right I am considered a liar. My wound is incurable, though I am without disobedience.’
Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí, bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’
7 What man is like Job, who drinks scorn like water,
Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?
8 who goes in company with the workers of iniquity, and walks with wicked men?
Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.
9 For he has said, ‘It profits a man nothing that he should delight himself with God.’
Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn, tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’
10 “Therefore listen to me, you men of understanding: far be it from God, that he should do wickedness, from the Almighty, that he should commit iniquity.
“Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi, ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye: Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú, àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!
11 For the work of a man he will render to him, and cause every man to find according to his ways.
Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe, yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.
12 Yes surely, God will not do wickedly, neither will the Almighty pervert justice.
Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà; bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.
13 Who put him in charge of the earth? Or who has appointed him over the whole world?
Ta ni ó fi ìtọ́jú ayé lé e lọ́wọ́, tàbí ta ni ó fi gbogbo ayé lé e lọ́wọ́?
14 If he set his heart on himself, if he gathered to himself his spirit and his breath,
Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀ tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
15 all flesh would perish together, and man would turn again to dust.
gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀, ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.
16 “If now you have understanding, hear this. Listen to the voice of my words.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí; fetísí ohùn ẹnu mi.
17 Should even one who hates justice govern? Will you condemn him who is righteous and mighty,
Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí? Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?
18 who says to a king, ‘Vile!’ or to nobles, ‘Wicked!’?
O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’ tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘Ìkà ni ẹ̀yin,’
19 He doesn’t respect the persons of princes, nor respect the rich more than the poor, for they all are the work of his hands.
mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ, nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?
20 In a moment they die, even at midnight. The people are shaken and pass away. The mighty are taken away without a hand.
Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú, àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ; a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.
21 “For his eyes are on the ways of a man. He sees all his goings.
“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.
22 There is no darkness, nor thick gloom, where the workers of iniquity may hide themselves.
Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.
23 For he doesn’t need to consider a man further, that he should go before God in judgment.
Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.
24 He breaks mighty men in pieces in ways past finding out, and sets others in their place.
Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí, a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn,
25 Therefore he takes knowledge of their works. He overturns them in the night, so that they are destroyed.
nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn, ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
26 He strikes them as wicked men in the open sight of others;
Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i,
27 because they turned away from following him, and wouldn’t pay attention to any of his ways,
nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i, wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,
28 so that they caused the cry of the poor to come to him. He heard the cry of the afflicted.
kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní.
29 When he gives quietness, who then can condemn? When he hides his face, who then can see him? He is over a nation or a man alike,
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi? Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i? Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;
30 that the godless man may not reign, that there be no one to ensnare the people.
kí aláìwà bi Ọlọ́run kí ó má bá à jẹ ọba kí wọn kí ó má di ìdẹwò fún ènìyàn.
31 “For has any said to God, ‘I am guilty, but I will not offend any more.
“Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé, èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́?
32 Teach me that which I don’t see. If I have done iniquity, I will do it no more’?
Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi bi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
33 Shall his recompense be as you desire, that you refuse it? For you must choose, and not I. Therefore speak what you know.
Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà? Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́, ìwọ gbọdọ̀ yan, kì í ṣe èmi. Nítorí náà sọ ohun tí o mọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ́!
34 Men of understanding will tell me, yes, every wise man who hears me:
“Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi, àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,
35 ‘Job speaks without knowledge. His words are without wisdom.’
‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’
36 I wish that Job were tried to the end, because of his answering like wicked men.
Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin, nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú.
37 For he adds rebellion to his sin. He claps his hands among us, and multiplies his words against God.”
Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa, ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”

< Job 34 >