< Proverbs 29 >
1 He who is often rebuked and stiffens his neck will be destroyed suddenly, with no remedy.
Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
2 When the righteous thrive, the people rejoice; but when the wicked rule, the people groan.
Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.
3 Whoever loves wisdom brings joy to his father; but a companion of prostitutes squanders his wealth.
Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.
4 The king by justice makes the land stable, but he who takes bribes tears it down.
Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini, ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.
5 A man who flatters his neighbour spreads a net for his feet.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀ ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.
6 An evil man is snared by his sin, but the righteous can sing and be glad.
Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.
7 The righteous care about justice for the poor. The wicked aren’t concerned about knowledge.
Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.
8 Mockers stir up a city, but wise men turn away anger.
Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.
9 If a wise man goes to court with a foolish man, the fool rages or scoffs, and there is no peace.
Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.
10 The bloodthirsty hate a man of integrity; and they seek the life of the upright.
Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.
11 A fool vents all of his anger, but a wise man brings himself under control.
Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.
12 If a ruler listens to lies, all of his officials are wicked.
Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.
13 The poor man and the oppressor have this in common: The LORD gives sight to the eyes of both.
Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.
14 The king who fairly judges the poor, his throne shall be established forever.
Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́ ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo.
15 The rod of correction gives wisdom, but a child left to himself causes shame to his mother.
Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.
16 When the wicked increase, sin increases; but the righteous will see their downfall.
Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn.
17 Correct your son, and he will give you peace; yes, he will bring delight to your soul.
Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.
18 Where there is no revelation, the people cast off restraint; but one who keeps the law is blessed.
Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà, ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́.
19 A servant can’t be corrected by words. Though he understands, yet he will not respond.
A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i.
20 Do you see a man who is hasty in his words? There is more hope for a fool than for him.
Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀? Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.
21 He who pampers his servant from youth will have him become a son in the end.
Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.
22 An angry man stirs up strife, and a wrathful man abounds in sin.
Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè, onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.
23 A man’s pride brings him low, but one of lowly spirit gains honour.
Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.
24 Whoever is an accomplice of a thief is an enemy of his own soul. He takes an oath, but dares not testify.
Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀, ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn.
25 The fear of man proves to be a snare, but whoever puts his trust in the LORD is kept safe.
Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.
26 Many seek the ruler’s favour, but a man’s justice comes from the LORD.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso, ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.
27 A dishonest man detests the righteous, and the upright in their ways detest the wicked.
Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́: ènìyàn búburú kórìíra olódodo.