< Philippians 1 >

1 Paul and Timothy, servants of Christ Jesus, to all those set apart in Christ Jesus who are at Philippi, with the overseers and deacons.
Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi, Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì:
2 May grace be to you and peace from God our Father and the Lord Jesus Christ.
Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jesu Kristi.
3 I thank my God every time I remember you;
Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín.
4 and always in every prayer for all of you, I pray with joy.
Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà,
5 I give thanks for your fellowship in the gospel from the first day until now.
nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí.
6 I am confident of this very thing, that he who began a good work in you will continue to complete it until the day of Jesus Christ.
Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé.
7 It is right for me to feel this way about all of you because I have you in my heart. You all have been my partners in grace both in my imprisonment and in my defense and confirmation of the gospel.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìyìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi.
8 For God is my witness, how I long for all of you with the compassion of Christ Jesus.
Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.
9 I am praying this: That your love may abound more and more in knowledge and all understanding.
Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀,
10 I pray for this so that you may approve what is excellent, and so you may be sincere and without offense on the day of Christ.
kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi,
11 I pray that you also will be filled with the fruit of righteousness that comes through Jesus Christ, to the glory and praise of God.
lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.
12 Now I want you to know, brothers, that what has happened to me has really served to advance the gospel.
Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi jásí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìyìnrere.
13 As a result, my chains in Christ came to light throughout the whole palace guard and to everyone else.
Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi.
14 Most of the brothers have far more confidence in the Lord because of my chains, and they have courage to fearlessly speak the word.
Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.
15 Some indeed even proclaim Christ out of envy and strife, and also others out of good will.
Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é.
16 The latter do it out of love, knowing that I am put here for the defense of the gospel.
Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi.
17 But the former proclaim Christ out of selfish ambition, not sincerely. They think they will afflict me while I am in chains.
Àwọn kan ẹ̀wẹ̀ si ń fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a gbé mi dìde láti dá ààbò bo iṣẹ́ ìyìnrere.
18 What then? Only that in every way—whether from false motives or from true—Christ is proclaimed, and in this I rejoice. Yes, and I will rejoice,
Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí. Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀,
19 for I know that this will result in my deliverance through your prayers and the help of the Spirit of Jesus Christ.
nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi.
20 It is my eager expectation and certain hope that I will in no way be ashamed, but that I will have complete boldness, so that now as always, Christ will be exalted in my body, whether by life or by death.
Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú.
21 For to me to live is Christ and to die is gain.
Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi.
22 But if I am to live in the flesh, that means fruitful labor for me. Yet which to choose? I do not know.
Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀.
23 For I am hard pressed between the two. My desire is to depart and be with Christ, which is far better,
Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù:
24 yet to remain in the flesh is more necessary for your sake.
síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín.
25 Being convinced of this, I know that I will remain and continue with you all, for your progress and joy in the faith,
Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́,
26 so that in me you may have increasing reasons to boast in Christ Jesus when I come to you again.
kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.
27 Only conduct yourselves in a manner worthy of the gospel of Christ, so that whether I come to see you or am absent, I may hear about you, that you are standing firm in one spirit, with one mind striving together for the faith of the gospel.
Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìyìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan.
28 Do not be frightened in any respect by those who are your opponents. This is a sign to them of their destruction, but of your salvation—and this from God.
Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe àmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là.
29 For it has been granted to you, for the sake of Christ, not only to believe in him, but also to suffer for his sake,
Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.
30 having the same conflict which you saw in me, and now you hear in me.
Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.

< Philippians 1 >