< Mark 15 >

1 Early in the morning, the chief priests met together with the elders and scribes and the entire Jewish council. Then they bound Jesus and led him away. They handed him over to Pilate.
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbàgbà, àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àjọ ìgbìmọ̀ fi ẹnu kò lórí ohun tí wọn yóò ṣe. Wọ́n sì de Jesu, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fi lé Pilatu lọ́wọ́.
2 Pilate asked him, “Are you the King of the Jews?” He answered him, “You say so.”
Pilatu sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu sì dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti wí náà ni.”
3 The chief priests were presenting many charges against Jesus.
Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án.
4 Pilate again asked him, “Do you give no answer? See how many charges they are bringing against you!”
Pilatu sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.”
5 But Jesus no longer answered Pilate, and that amazed him.
Ṣùgbọ́n Jesu kò dalóhùn síbẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pilatu.
6 Now at the time of the feast, Pilate usually released to them one prisoner, a prisoner they requested.
Ní báyìí, nígbà àjọ, gẹ́gẹ́ bí àṣà, òun a máa dá òǹdè kan sílẹ̀ fún wọn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá béèrè fún.
7 There with the rebels in prison, among the murderers held for their part in the rebellion, was a man named Barabbas.
Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Baraba. Wọ́n ti ju òun àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nítorí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì pa ènìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn.
8 The crowd came to Pilate and began to ask him to do for them as he had done in the past.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pilatu, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún.
9 Pilate answered them and said, “Do you want me to release to you the King of the Jews?”
Pilatu béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Ṣe ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yin?”
10 For he knew that it was because of envy that the chief priests had handed Jesus over to him.
Òun mọ̀ pé nítorí ìlara ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fà Jesu lé òun lọ́wọ́.
11 But the chief priests stirred up the crowd to cry out that Barabbas should be released instead.
Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà ru ọ̀pọ̀ ènìyàn sókè pé, kí ó kúkú dá Baraba sílẹ̀ fún wọn.
12 Pilate answered them again and said, “What then should I do with the King of the Jews?”
Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù?”
13 They shouted again, “Crucify him!”
Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, “Kàn án mọ àgbélébùú!”
14 Pilate said to them, “What wrong has he done?” But they shouted more and more, “Crucify him.”
Nígbà náà ni Pilatu bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?” Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
15 Pilate wanted to satisfy the crowd, so he released Barabbas to them. He scourged Jesus and then handed him over to be crucified.
Pilatu sì ń fẹ́ ṣe èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jesu tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú.
16 The soldiers led him inside the courtyard (which is the government headquarters), and they called together the whole cohort of soldiers.
Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú ààfin (tí a ń pè ní Pretoriomu), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ogun jọ.
17 They put a purple robe on Jesus, and they twisted together a crown of thorns and put it on him.
Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí.
18 They began to salute him and say, “Hail, King of the Jews!”
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì wí pé, Kábíyèsí, ọba àwọn Júù.
19 They struck his head with a reed staff and they spat on him. They bent their knees before him to pretend to worship him.
Wọ́n sì fi ọ̀pá lù ú lórí, wọ́n sì tutọ́ sí i lára, wọ́n sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.
20 When they had mocked him, they took off of him the purple robe and put his own garments on him, and then led him out to crucify him.
Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elése àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
21 A certain man, Simon of Cyrene, was coming in from the country (he was the father of Alexander and Rufus), and they forced him to carry his cross.
Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Simoni ará Kirene. Òun ni baba Aleksanderu àti Rufusi. Wọ́n sì mú un ní tipátipá pé, kí ó rú àgbélébùú Jesu.
22 The soldiers brought Jesus to the place called Golgotha (which interpreted means, “Place of a Skull”).
Wọ́n sì mú Jesu wá sí Gọlgọta (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí)
23 They offered him wine mixed with myrrh, but he did not drink it.
Wọ́n sì fi myrri wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á.
24 They crucified him and divided up his garments by casting lots to determine what piece each soldier would take.
Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn bá à lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù.
25 It was the third hour when they crucified him.
Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú.
26 On a sign they wrote the charge against him, “The king of the Jews.”
Àkọlé ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni: Ọba àwọn Júù.
27 With him they crucified two robbers, one on the right of him and one on his left.
Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀.
29 Those who passed by insulted him, shaking their heads and saying, “Aha! You who would destroy the temple and rebuild it in three days,
Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta,
30 save yourself and come down from the cross!”
sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!”
31 In the same way the chief priests were mocking him with each other, along with the scribes, and said, “He saved others, but he cannot save himself.
Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà.
32 Let the Christ, the King of Israel, come down now from the cross, that we may see and believe,” and those who were crucified with him also taunted him.
Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.
33 At the sixth hour, darkness came over the whole land until the ninth hour.
Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán.
34 At the ninth hour Jesus cried out with a loud voice, “Eloi, Eloi, lama sabachthani?” which is interpreted, “My God, my God, why have you forsaken me?”
Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, lama sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).
35 Some of those standing by heard his words and said, “Look, he is calling for Elijah.”
Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Elijah.”
36 Someone ran, put sour wine on a sponge, put it on a reed staff, and gave it to him to drink. The man said, “Let us see if Elijah comes to take him down.”
Nígbà náà ni ẹnìkan sáré lọ ki kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jesu kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Elijah yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ wa.”
37 Then Jesus cried out with a loud voice and died.
Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.
38 The curtain of the temple was split in two from the top to the bottom.
Aṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀.
39 When the centurion who stood and faced Jesus saw that he had died in this way, he said, “Truly this man was the Son of God.”
Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe.”
40 There were also women who looked on from a distance. Among them were Mary Magdalene, Mary (the mother of James the younger and of Joses), and Salome.
Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń wò ó láti òkèèrè. Maria Magdalene wà lára àwọn obìnrin náà, àti Maria ìyá Jakọbu kékeré àti ti Jose, àti Salome.
41 When he was in Galilee they followed him and served him. Many other women also came up with him to Jerusalem.
Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.
42 When evening had come, because it was the Day of Preparation, that is, the day before the Sabbath,
Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí i ṣe, ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú,
43 Joseph of Arimathea came there. He was a respected member of the council, who was waiting for the kingdom of God. He boldly went in to Pilate and asked for the body of Jesus.
Josẹfu ará Arimatea wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pilatu láti tọrọ òkú Jesu.
44 Pilate was amazed that Jesus was already dead; he called the centurion and asked him if Jesus was dead.
Ẹnu ya Pilatu láti gbọ́ pé Jesu ti kú. Nítorí náà ó pe balógun ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jesu ti kú nítòótọ́.
45 When Pilate learned from the centurion that Jesus was dead, he gave the body to Joseph.
Nígbà tí balógun ọ̀rún náà sì fún Pilatu ni ìdánilójú pé Jesu ti kú, Pilatu jọ̀wọ́ òkú rẹ̀ fún Josẹfu.
46 Joseph had bought a linen cloth. He took him down from the cross, wrapped him in the linen cloth, and laid him in a tomb that had been cut out of a rock. Then he rolled a stone against the entrance of the tomb.
Josẹfu sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jesu kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.
47 Mary Magdalene and Mary the mother of Joses saw the place where Jesus was buried.
Maria Magdalene àti Maria ìyá Jose ń wò ó bi Josẹfu ti n tẹ́ Jesu sí ibojì.

< Mark 15 >