< Isaiah 35 >
1 The wilderness and the Arabah will be glad; and the desert will rejoice and blossom. Like the rose,
Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn; aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná. Gẹ́gẹ́ bí ewéko,
2 it will blossom abundantly and rejoice with joy and singing; the glory of Lebanon will be given to it, the splendor of Carmel and Sharon; they will see the glory of Yahweh, the splendor of our God.
ní títanná yóò tanná; yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kọrin. Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un, ẹwà Karmeli àti Ṣaroni; wọn yóò rí ògo Olúwa, àti ẹwà Ọlọ́run wa.
3 Strengthen the weak hands, and steady the knees that shake.
Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun.
4 Say to those with a fearful heart, “Be strong, do not fear! Look, your God will come with vengeance, with the recompense of God. He will come and save you.”
Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé, “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san; pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.”
5 Then the eyes of the blind will see, and the ears of the deaf will hear.
Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.
6 Then the lame man will leap like a deer, and the mute tongue will sing, for water breaks out in the Arabah, and streams in the wilderness.
Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú aginjù àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
7 The burning sand will become a pool, and the thirsty ground springs of water; in the habitation of jackals, where they once lay, will be grass with reeds and rushes.
Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà, ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi. Ní ibùgbé àwọn dragoni, níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀, ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.
8 A highway will be there called The Holy Way. The unclean will not travel it. But it will be for him who walks in it. No fool will go on it.
Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀: a ó sì máa pè é ní ọ̀nà ìwà mímọ́. Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà; yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà, àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.
9 No lion will be there, no ferocious beast will be on it; they will not be found there, but the redeemed will walk there.
Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀; a kì yóò rí wọn níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,
10 The ransomed of Yahweh will return and come with singing to Zion, and everlasting joy will be on their heads; gladness and joy will overtake them; sorrow and sighing will flee away.
àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin; ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí. Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.