< Hosea 3 >
1 Yahweh said to me, “Go again, love a woman, loved by her husband, but who is an adulteress. Love her just as I, Yahweh, love the people of Israel, although they turn to other gods and love raisin cakes.”
Olúwa sì wí fún mi pé, “Tun lọ fẹ́ obìnrin kan tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, àti panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Olúwa sì àwọn ọmọ Israẹli tí ń wo àwọn ọlọ́run mìíràn, tí wọ́n sì ń fẹ́ àkàrà èso àjàrà.”
2 So I bought her for myself for fifteen pieces of silver and a homer and a lethek of barley.
Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti homeri kan àti lẹ́tékì barle kan.
3 I said to her, “You must live with me many days. You will not be a prostitute or belong to any other man. In the same way, I will be with you.”
Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú rẹ.”
4 For the people of Israel will live for many days without a king, prince, sacrifice, stone pillar, ephod or household idols.
Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan.
5 Afterward the people of Israel will return and seek Yahweh their God and David their king, and in the last days, they will come trembling before Yahweh and his goodness.
Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò padà láti wá Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún Olúwa àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.