< Amos 2 >
1 This is what Yahweh says: “For three sins of Moab, even for four, I will not turn away punishment, because he burned the bones of the king of Edom to lime.
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, nítorí ó ti sun ún, di eérú, egungun ọba Edomu,
2 I will send fire on Moab, and it will devour the fortresses of Kerioth. Moab will die in an uproar, with shouting and the sound of the trumpet.
Èmi yóò rán iná sí orí Moabu èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run. Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè.
3 I will destroy the judge in her, and I will kill all the princes with him,” says Yahweh.
Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,” ni Olúwa wí.
4 This is what Yahweh says: “For three sins of Judah, even for four, I will not turn away punishment, because they rejected the law of Yahweh and did not keep his statutes. Their lies caused them to go astray, after which their fathers had also walked.
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́. Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà, òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé,
5 I will send fire on Judah, and it will devour the fortresses of Jerusalem.”
Èmi yóò rán iná sí orí Juda èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”
6 This is what Yahweh says: “For three sins of Israel, even for four, I will not turn away punishment, because they sold the innocent for silver and the needy for a pair of sandals.
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.
7 They trample on the heads of the poor as people trample on dust on the ground; they push the oppressed away. A man and his father sleep with the same girl and so profane my holy name.
Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀, bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára. Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà, láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.
8 They lie down beside every altar on clothes taken as pledges, and in the house of their God they drink the wine of those who were fined.
Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ, lórí aṣọ tí wọ́n fi jẹ́ ẹ̀jẹ́ ní ilé òrìṣà wọn wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn.
9 Yet I destroyed the Amorite before them, whose height was like the height of cedars; he was strong as the oaks. Yet I destroyed his fruit above and his roots below.
“Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari. Òun sì le koko bí igi óákù mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá.
10 Also, I brought you up out of the land of Egypt and led you forty years in the wilderness to possess the land of the Amorites.
Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.
11 I raised up prophets from among your sons and Nazirites from your young men. Is it not so, people of Israel? —this is Yahweh's declaration.
“Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?” ni Olúwa wí.
12 But you persuaded the Nazirites to drink wine and commanded the prophets not to prophesy.
“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.
13 Look, I will crush you as a cart that is full of grain can crush someone.
“Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.
14 The swift will find no escape; the strong will not add to his own strength; neither will the mighty save himself.
Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀ jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.
15 The archer will not stand; the fast runner will not escape; the horseman will not save himself.
Tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.
16 Even the bravest warriors will flee naked in that day —this is Yahweh's declaration.”
Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ yóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí.