< Acts 8 >

1 Saul was in agreement with his death. So there began on that day a great persecution against the church that was in Jerusalem; and the believers were all scattered throughout the regions of Judea and Samaria, except the apostles.
Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀. Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli.
2 Devout men buried Stephen and made great lamentation over him.
Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀.
3 But Saul greatly harmed the church; he went into house after house and dragged out men and women, and put them into prison.
Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
4 Yet the believers who had been scattered went about proclaiming the word.
Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà.
5 Philip went down to the city of Samaria and proclaimed to them the Christ.
Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn.
6 When multitudes of people heard and saw the signs that Philip did, they paid attention together to what he said.
Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ.
7 Unclean spirits came out of many who were possessed, crying out with a loud voice, and many who were paralyzed and lame were healed.
Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá.
8 So there was much joy in that city.
Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.
9 But there was a certain man in the city named Simon, who had earlier been practicing sorcery; he used to astonish the people of Samaria, while claiming that he was an important person.
Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Simoni, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaria. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun.
10 All the Samaritans, from the least to the greatest, paid attention to him; they said, “This man is that power of God which is called Great.”
Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bu ọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ ńlá.”
11 They listened to him, because he had astonished them for a long time with his sorceries.
Wọ́n bu ọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn.
12 But when they believed Philip as he proclaimed the good news about the kingdom of God and the name of Jesus Christ, they were baptized, both men and women.
Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Filipi gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jesu Kristi, a bamitiisi wọn.
13 Even Simon himself believed, and after he was baptized he stayed with Philip constantly. When he saw signs and mighty deeds taking place, he was amazed.
Simoni tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bamitiisi rẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú Filipi, ó wo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Filipi ṣe, ẹnu sì yà á.
14 Now when the apostles in Jerusalem heard that Samaria had received the word of God, they sent to them Peter and John.
Nígbà tí àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu sí gbọ́ pé àwọn ara Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Peteru àti Johanu sí wọn.
15 When they had come down, they prayed for them, that they might receive the Holy Spirit.
Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́,
16 For until that time, the Holy Spirit had not come upon any of them; they had only been baptized into the name of the Lord Jesus.
nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni.
17 Then Peter and John placed their hands on them, and they received the Holy Spirit.
Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.
18 Now when Simon saw that the Holy Spirit was given through the laying on of the apostles' hands, he offered them money.
Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n,
19 He said, “Give me this power, too, that whoever I place my hands on might receive the Holy Spirit.”
ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”
20 But Peter said to him, “May your silver perish along with you, because you thought to obtain the gift of God with money.
Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!
21 You have no part or share in this matter, because your heart is not right with God.
Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run.
22 Therefore repent of this wickedness of yours, and pray to the Lord, so that he might perhaps forgive you for the intention of your heart.
Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́.
23 For I see that you are in the poison of bitterness and in the bonds of sin.”
Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”
24 Simon answered and said, “Pray to the Lord for me, so that nothing you have said may happen to me.”
Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”
25 When they had testified and spoken the word of the Lord, Peter and John returned to Jerusalem, proclaiming the gospel to many villages of the Samaritans.
Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìyìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria.
26 Now an angel of the Lord spoke to Philip and said, “Arise and go toward the south to the road that goes down from Jerusalem to Gaza.” (This road is in a desert.)
Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.”
27 He arose and went. Behold, there was a man from Cush, a eunuch of great authority under Candace, queen of the Cushites. He was in charge of all her treasure. He had come to Jerusalem to worship.
Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsi, ọkùnrin kan ará Etiopia, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọ́dọ̀ Kandake ọbabìnrin àwọn ara Etiopia, ẹni tí í ṣe olórí ìṣúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn,
28 He was returning and sitting in his chariot, and was reading the prophet Isaiah.
Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah.
29 The Spirit said to Philip, “Go over and stay close to this chariot.”
Ẹ̀mí sì wí fún Filipi pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”
30 So Philip ran to him, and heard him reading Isaiah the prophet, and said, “Do you understand what you are reading?”
Filipi si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah, Filipi sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”
31 The Cushite said, “How can I, unless someone guides me?” He begged Philip to come up into the chariot and sit with him.
Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Filipi kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.
32 Now the passage of the scripture which the Ethiopian was reading was this, “He was led like a sheep to the slaughter, and like a lamb before his shearer is silent, so he did not open his mouth.
Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí: “A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa; àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.
33 In his humiliation justice was taken away from him. Who can fully describe his descendants? For his life was taken from the earth.”
Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún. Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀? Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”
34 So the eunuch asked Philip, and said, “I beg you, who is the prophet speaking about, himself, or someone else?”
Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?”
35 Philip began to speak, and beginning with this scripture he proclaimed the good news about Jesus to him.
Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìyìnrere ti Jesu fún un.
36 As they went on the road, they came to some water and the eunuch said, “Look, there is water here. What prevents me from being baptized?”
Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti se ìrìbọmi?”
38 So the Ethiopian commanded the chariot to stop. They went down into the water, both Philip and the eunuch, and Philip baptized him.
Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀.
39 When they came up out of the water, the Spirit of the Lord took Philip away, and the eunuch saw him no more, but went on his way rejoicing.
Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú, omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.
40 But Philip appeared at Azotus and he went through that region, proclaiming the gospel to all the cities until he came to Caesarea.
Filipi sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Asotu, bí ó ti ń kọjá lọ, o wàásù ìyìnrere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesarea.

< Acts 8 >