< Acts 15 >
1 Some men came down from Judea to Antioch and taught the brothers, saying, “Unless you are circumcised according to the custom of Moses, you cannot be saved.”
Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.”
2 This brought Paul and Barnabas into a sharp dispute and debate with them. So Paul and Barnabas along with some others from among them were appointed to go up to Jerusalem to meet with the apostles and elders about this question.
Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí.
3 They therefore, being sent by the church, passed through both Phoenicia and Samaria and announced the conversion of the Gentiles. They brought great joy to all the brothers.
Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà, wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin.
4 When they came to Jerusalem, they were welcomed by the church and the apostles and the elders, and they reported all the things that God had done with them.
Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.
5 But certain men who believed, who belonged to the group of Pharisees, stood up and said, “It is necessary to circumcise them and to command them to keep the law of Moses.”
Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ẹ̀yà àwọn Farisi tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mose mọ́.”
6 So the apostles and the elders gathered together to consider this matter.
Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí.
7 After much debate, Peter stood up and said to them, “Brothers, you know that a good while ago God made a choice among you, that by my mouth the Gentiles should hear the word of the gospel, and believe.
Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Peteru dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìnrere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́.
8 God, who knows the heart, witnesses to them, giving them the Holy Spirit, just as he did to us;
Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olùmọ̀-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa.
9 and he made no distinction between us and them, making their hearts clean by faith.
Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárín àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́.
10 Now therefore why do you test God, that you should put a yoke upon the neck of the disciples which neither our fathers nor we were able to bear?
Ǹjẹ́ nítorí náà èéṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù?
11 But we believe that we shall be saved through the grace of the Lord Jesus, just as they were.”
Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jesu àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”
12 All the multitude kept silent while they listened to Barnabas and Paul report the signs and wonders God had worked among the Gentiles through them.
Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi etí sí Barnaba àti Paulu, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrín àwọn aláìkọlà.
13 After they stopped speaking, James answered, saying, “Brothers, listen to me.
Lẹ́yìn tí wọn sì dákẹ́, Jakọbu dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi,
14 Simon has told how God first graciously helped the Gentiles in order to take from them a people for his name.
Simeoni ti ròyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojú wo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀.
15 The words of the prophets agree with this, as it is written,
Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe déédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
16 'After these things I will return, and I will build again the tent of David, which has fallen down; I will set up and restore its ruins again,
“‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà, èmi ó sì tún àgọ́ Dafidi pa tí ó ti wó lulẹ̀: èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́, èmi ó sì gbé e ró.
17 so that the remnant of men may seek the Lord, including all the Gentiles called by my name.'
Kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa, àti gbogbo àwọn kèfèrí, lára ẹni tí a ń pe orúkọ mi,’ ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí,
18 This is what the Lord says, who has done these things that have been known from ancient times. (aiōn )
ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá. (aiōn )
19 Therefore, my opinion is, that we should not trouble those of the Gentiles who turn to God.
“Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu.
20 But we will write to them that they must keep away from the pollution of idols, from sexual immorality, and from the meat of strangled animals, and from blood.
Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fàsẹ́yìn kúrò nínú oúnjẹ tí a ṣe fún òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀.
21 For Moses has been proclaimed in every city from the ancient times and he is read in the synagogues every Sabbath.”
Nítorí òfin Mose nígbà àtijọ́ ṣá ní a ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú Sinagọgu ni ọjọọjọ́ ìsinmi.”
22 Then it seemed good to the apostles and the elders, with the whole church, to choose Judas called Barsabbas, and Silas, who were leaders of the church, and send them to Antioch with Paul and Barnabas.
Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.
23 They wrote this: “From the apostles and elders, your brothers, to the Gentile brothers in Antioch, Syria, and Cilicia: Greetings!
Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé, Àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà, tí ó jẹ́ ti aláìkọlà tí ó wà ní Antioku, àti ní Siria, àti ní Kilikia.
24 We have heard that certain men have gone out from us, with no orders from us, and have disturbed you with teachings that upset your souls.
Níwọ́n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín ní ọkàn padà (wí pé, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣàìmá pa òfin Mose mọ́), ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ.
25 This being so, all of us have agreed to choose men and to send them to you along with our beloved Barnabas and Paul,
Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa.
26 men who have risked their lives for the name of our Lord Jesus Christ.
Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi.
27 Therefore we are sending Judas and Silas, who will tell you the same thing themselves in their own words.
Nítorí náà àwa rán Judasi àti Sila àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín.
28 For it seemed good to the Holy Spirit and to us, to lay upon you no greater burden than these necessary things:
Nítorí ó dára lójú Ẹ̀mí Mímọ́, àti lójú wa, kí a má ṣe di ẹrù le é yin lórí, bí kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì;
29 that you abstain from things sacrificed to idols, blood, things strangled, and from sexual immorality. If you keep yourselves from these, it shall be well with you. Farewell.”
í ẹ̀yin fàsẹ́yìn kúrò nínú ẹran ti à pa bọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti nínú àgbèrè. Bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere. Àlàáfíà.
30 So they, when they were dismissed, came down to Antioch; after they gathered the multitude together, they delivered the letter.
Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá si Antioku. Nígbà tí wọn sì pé àwọn ìjọ papọ̀, wọn fi ìwé náà fún wọn.
31 When they had read it, they rejoiced because of the encouragement.
Nígbà tí wọn sì kà á, wọ́n yọ̀ fún ìtùnú náà.
32 Judas and Silas, also prophets, encouraged the brothers with many words and strengthened them.
Bí Judasi àti Sila tìkára wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le.
33 After they had spent some time there, they were sent away in peace from the brothers to those who had sent them.
Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá.
35 But Paul and Barnabas stayed in Antioch along with many others, where they taught and proclaimed the word of the Lord.
Paulu àti Barnaba sì dúró díẹ̀ ni Antioku, wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.
36 After some days Paul said to Barnabas, “Let us return now and visit the brothers in every city where we proclaimed the word of the Lord, and see how they are.”
Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.”
37 Barnabas wanted to also take with them John who was called Mark.
Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku.
38 But Paul thought it was not good to take Mark, who had left them in Pamphylia and did not go further with them in the work.
Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.
39 Then there arose a sharp disagreement, so that they separated from each other, and Barnabas took Mark with him and sailed away to Cyprus.
Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì, Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi.
40 But Paul chose Silas and left, after he was entrusted by the brothers to the grace of the Lord.
Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin.
41 Then he went through Syria and Cilicia, strengthening the churches.
Ó sì la Siria àti Kilikia lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.