< 2 Timothy 1 >

1 Paul, an apostle of Christ Jesus through the will of God, according to the promise of the life that is in Christ Jesus,
Paulu, aposteli ti Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kristi Jesu,
2 to Timothy, beloved child: Grace, mercy, and peace from God the Father and Christ Jesus our Lord.
Sí Timotiu, ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kristi Jesu Olúwa wa.
3 I thank God, whom I serve from my forefathers, with a clean conscience, as I constantly remember you in my prayers night and day.
Mo dá ọpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsimi lọ́sàn án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi.
4 As I remember your tears, I long to see you, that I may be filled with joy.
Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀.
5 I have been reminded of your genuine faith, which lived first in your grandmother Lois and your mother Eunice, and I am convinced that it lives in you also.
Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá ńlá rẹ, àti nínú Eunike ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó dá mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú.
6 This is the reason I am reminding you to rekindle the gift of God which is in you through the laying on of my hands.
Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi.
7 For God did not give us a spirit of fear, but of power and love and discipline.
Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro.
8 So do not be ashamed of the testimony about our Lord, nor of me, Paul, his prisoner. Instead, share in suffering for the gospel according to the power of God.
Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìyìnrere nípa agbára Ọlọ́run,
9 It is God who saved us and called us with a holy calling. He did this, not according to our works, but according to his own plan and grace. He gave us these things in Christ Jesus before times ever began. (aiōnios g166)
ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé, (aiōnios g166)
10 But now God's salvation has been revealed by the appearing of our Savior Christ Jesus. It is Christ who put an end to death and brought life that never ends to light through the gospel.
ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìyìnrere.
11 Because of this, I was appointed a preacher, an apostle, and a teacher.
Fún ti ìyìnrere tí a yàn mi láti jẹ oníwàásù àti aposteli àti olùkọ́.
12 For this cause I also suffer these things. But I am not ashamed, for I know him whom I have believed. I am persuaded that he is able to keep that which I have entrusted to him until that day.
Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí, nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.
13 Keep the example of faithful messages that you heard from me, with the faith and love that are in Christ Jesus.
Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu.
14 The good thing that God committed to you, guard it through the Holy Spirit, who lives in us.
Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.
15 You know this, that all who live in Asia turned away from me. In this group are Phygelus and Hermogenes.
Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Asia ti fi mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Figeliu àti Hamogene gbé wà.
16 May the Lord grant mercy to the household of Onesiphorus, for he often refreshed me and was not ashamed of my chain.
Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú.
17 Instead, when he was in Rome, he sought me diligently, and he found me.
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Romu, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi.
18 May the Lord grant to him to find mercy from him on that day. All the ways he helped me in Ephesus, you know very well.
Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkára rẹ sá à mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà ràn mí lọ́wọ́ ni Efesu.

< 2 Timothy 1 >