< 2 Corinthians 13 >
1 This is the third time that I am coming to you. “Every accusation must be established by the evidence of two or three witnesses.”
Èyí ni ó dí ìgbà kẹta tí èmi ń tọ̀ yín wá. Ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fi ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀.
2 I have already said to those who sinned before and to all the rest when I was there the second time, and I say it again: When I come again, I will not spare them.
Mo ti sọ fún yín ṣáájú, mo sì ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀, bí ẹni pé mo wà pẹ̀lú yín nígbà kejì, àti bí èmi kò ti sí lọ́dọ̀ yín ní ìsinsin yìí, mo kọ̀wé sí àwọn tí ó ti ṣẹ̀ náà, àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn, pé bí mo bá tún padà wá, èmi kì yóò dá wọn sí.
3 I tell you this because you are looking for evidence that Christ is speaking through me. He is not weak toward you. Instead, he is powerful in you.
Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín.
4 For he was crucified in weakness, but he is alive by God's power. For we also are weak in him, but we will live with him by the power of God among you.
Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láààyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú jásí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.
5 Examine yourselves to see if you are in the faith. Test yourselves. Do you not realize this about yourselves that Jesus Christ is in you?—unless you have failed the test.
Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù.
6 And I trust that you will recognize that we have not failed the test.
Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù.
7 Now we pray to God that you may not do any wrong. I do not pray that we may appear to have passed the test. Instead, I pray that you may do what is right, although we may seem to have failed the test.
Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù.
8 For we are not able to do anything against the truth, but only for the truth.
Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́.
9 For we rejoice when we are weak and you are strong. We also pray that you may be made complete.
Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín.
10 I write these things while I am away from you, so that when I am with you I do not have to deal harshly with you in the use of my authority—which the Lord gave to me, so that I may build you up, and not tear you down.
Ìdí nìyí ti mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fi fún mí, láti mú ìdàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín ṣubú.
11 Finally, brothers, rejoice! Work for restoration, be encouraged, agree with one another, live in peace. And the God of love and peace will be with you.
Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.
12 Greet each other with a holy kiss.
Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.
13 All of the believers greet you.
Gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run níbi kí i yín.
14 May the grace of the Lord Jesus Christ, the love of God, and the fellowship of the Holy Spirit be with all of you.
Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa, àti ìfẹ́ Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ ti Èmí Mímọ́, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.