< 1 Timothy 4 >
1 Now the Spirit clearly says that in later times some people will leave the faith and pay attention to deceitful spirits and the teachings of demons
Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.
2 in lying hypocrisy. Their own consciences will be branded.
Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó.
3 They will forbid to marry and to receive foods that God created for sharing with thanksgiving among those who believe and who know the truth.
Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́.
4 For everything created by God is good. Nothing that we take with thanksgiving is to be rejected.
Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á.
5 For it is sanctified by the word of God and prayer.
Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.
6 If you place these things before the brothers, you will be a good servant of Jesus Christ. For you are being nourished by the words of faith and by the good teaching that you have followed.
Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé.
7 But reject worldly stories loved by old women. Instead, train yourself in godliness.
Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.
8 For bodily training is a little useful, but godliness is useful for all things. It holds promise for this life now and the life to come.
Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀.
9 This message is trustworthy and worthy of full acceptance.
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo.
10 For it is for this that we struggle and work very hard. For we have hope in the living God, who is the Savior of all people, but especially of believers.
Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.
11 Proclaim and teach these things.
Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni.
12 Let no one despise your youth. Instead, be an example for those who believe, in speech, conduct, love, faithfulness, and purity.
Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.
13 Until I come, attend to the reading, to the exhortation, and to the teaching.
Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbaniníyànjú àti ìkọ́ni.
14 Do not neglect the gift that is in you, which was given to you through prophecy, with the laying on of the hands of the elders.
Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.
15 Care for these things. Be in them, so that your progress may be evident to all people.
Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn.
16 Give careful attention to yourself and to the teaching. Continue in these things. For by doing so, you will save yourself and those who listen to you.
Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.