< 1 Thessalonians 3 >

1 Therefore, when we could no longer bear it, we thought it was good to be left behind at Athens alone.
Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Ateni.
2 We sent Timothy, our brother and fellow worker for God in the gospel of Christ, to strengthen and comfort you regarding your faith.
Awa sì rán Timotiu, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Ọlọ́run nínú ìyìnrere Kristi, láti fi ẹsẹ yín múlẹ̀, àti láti tù yín nínú ní ti ìgbàgbọ́ yín.
3 We did this so that no one would be shaken by these sufferings. For yourselves know that for this we have been appointed.
Láìsí àní àní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwọn tí ó gbàgbọ́, kí a má ba dààmú.
4 Truly, when we were with you, we told you in advance that we were about to suffer affliction, and that happened, as you know.
Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò dé. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́.
5 For this reason, when I could no longer stand it, I sent that I might know about your faith. Perhaps the tempter had somehow tempted you, and our labor was in vain.
Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba á mọ́, mo sì ránṣẹ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ìgbàgbọ́ yín, kí olùdánwò nì má ba à dán an yín wò lọ́nàkọnà, kí làálàá wa sì jásí asán.
6 But Timothy came to us from you and brought us the good news of your faith and love. He told us that you always have good memories of us, and that you long to see us just as we also long to see you.
Nísinsin yìí, Timotiu ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín ṣì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ ṣì ń rántí ìbágbé wa láàrín yín pẹ̀lú ayọ̀. Timotiu tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá.
7 Because of this, brothers, we were comforted by you because of your faith, in all our distress and affliction.
Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsin yìí pé, ẹ̀yin dúró gbọningbọnin fún Olúwa.
8 For now we live, if you stand firm in the Lord.
Nítorí àwa yè nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa.
9 For what thanks can we give to God for you, for all the joy that we have before our God over you?
Kò ṣe é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín.
10 Night and day we pray very hard that we may see your face and provide what is lacking in your faith.
Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí.
11 May our God and Father himself, and our Lord Jesus, direct our way to you.
À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jesu Kristi láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í.
12 May the Lord make you increase and abound in love one for another and toward all people, as we also do for you.
A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà.
13 May he strengthen your hearts, so that they will be blameless in holiness before our God and Father, at the coming of our Lord Jesus with all his saints.
Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.

< 1 Thessalonians 3 >