< 1 Samuel 17 >
1 Now the Philistines gathered their armies for battle. They were gathered at Sokoh, which belongs to Judah. They had encamped between Sokoh and Azekah, in Ephes Dammim.
Filistini kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ fún ogun ní Soko ti Juda. Wọ́n pàgọ́ sí Efesi-Damimu, láàrín Soko àti Aseka,
2 Saul and the men of Israel gathered and encamped in the Valley of Elah, and drew up their battle line to meet the Philistines.
Saulu àti àwọn ọmọ Israẹli wọ́n kò ara wọ́n jọ pọ̀, wọ́n sì pàgọ́ ní àfonífojì Ela, wọ́n sì gbé ogun wọn sókè ní ọ̀nà láti pàdé àwọn Filistini.
3 The Philistines stood on a mountain on one side, and Israel stood on a mountain on the other side with a valley between them.
Àwọn Filistini sì wà ní orí òkè kan àwọn ọmọ Israẹli sì wà ní orí òkè mìíràn, àfonífojì sì wà láàrín wọn.
4 A strong man came out of the Philistines' camp, a man named Goliath of Gath, whose height was six cubits and a span.
Ọ̀gágun tí a ń pè ní Goliati, tí ó jẹ́ ará Gati, ó wá láti ibùdó Filistini. Ó ga ní ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà àti ìnà ìka kan ní ìbú.
5 He had a helmet of bronze on his head, and he was armed with a coat of chainmail. The coat weighed five thousand shekels of bronze.
Ó ní àṣíborí idẹ ní orí rẹ̀, ó sì wọ ẹ̀wù tí a fi idẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọ̀n ẹ̀wù náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ṣékélì idẹ.
6 He had bronze armor on his legs and a javelin of bronze between his shoulders.
Òun sì wọ ìhámọ́ra idẹ sí ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àpáta idẹ kan láàrín ẹ̀yìn rẹ̀.
7 The staff of his spear was large, with a loop of cord for throwing it like the cord on a weaver's beam. His spear's head weighed six hundred shekels of iron. His shield bearer went before him.
Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ rí bí apásá ìhunṣọ, orí ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì wọn ẹgbẹ̀ta kilogiramu méje irin, ẹni tí ó ru asà ogun rẹ̀ lọ ṣáájú u rẹ̀.
8 He stood and shouted to the ranks of Israel, “Why have you come out to draw up for battle? Am not I a Philistine, and are you not servants of Saul? Choose a man for yourselves and let him come down to me.
Goliati dìde, ó sì kígbe sí ogun Israẹli pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi jáde wá, tí ẹ ṣe tò fún ogun? Ṣé èmi kì í ṣe Filistini ni, àbí ẹ̀yin kì í ṣe ìránṣẹ́ Saulu? Yan ọkùnrin kan kí o sì jẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi.
9 If he is able to fight with me and kill me, then will we be your servants. But if I defeat him and kill him, then you will be our servants and serve us.”
Tí òhun bá sì le jà tí ó sì pa mí, àwa yóò di ẹrú u yín, ṣùgbọ́n tí èmi bá lè ṣẹ́gun rẹ̀ tí mo sì pa á, ẹ̀yin yóò di ẹrú u wa, ẹ̀yin yóò sì máa sìn wá.”
10 Again the Philistine said, “I challenge the ranks of Israel today. Give me a man so we may fight together.”
Nígbà náà Filistini náà wí pé, “Èmi fi ìjà lọ ogun Israẹli ní òní! Ẹ mú ọkùnrin kan wá kí ẹ sì jẹ́ kí a bá ara wa jà.”
11 When Saul and all Israel heard what the Philistine said, they were discouraged and greatly afraid.
Nígbà tí Saulu àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Filistini, ìdààmú bá wọn.
12 Now David was the son of the Ephrathite of Bethlehem in Judah, whose name was Jesse. He had eight sons. Jesse was an old man in the days of Saul, very old among men.
Nísinsin yìí Dafidi jẹ́ ọmọ ará Efrata kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jese, tí ó wá láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda, Jese ní ọmọ mẹ́jọ, ní àsìkò Saulu ó ti darúgbó ẹni ọdún púpọ̀.
13 The three oldest sons of Jesse had followed Saul to the battle. The names of his three sons who went to the battle were Eliab the firstborn, second to him Abinadab, and the third Shammah.
Àwọn ọmọ Jese mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Saulu lọ sí ojú ogun, èyí àkọ́bí ni Eliabu, èyí èkejì ni Abinadabu, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣamma.
14 David was the youngest. The three oldest followed Saul.
Dafidi ni ó kéré jù nínú wọn. Àwọn àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì tẹ̀lé Saulu,
15 Now David went back and forth between Saul's army and his father's sheep at Bethlehem, in order to feed them.
ṣùgbọ́n Dafidi padà lẹ́yìn Saulu, láti máa tọ́jú àgùntàn baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu.
16 For forty days the Philistine strong man came near morning and evening to present himself for battle.
Fún ogójì ọjọ́, Filistini wá síwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn.
17 Then Jesse said to his son David, “Take to your brothers an ephah of this roasted grain and these ten loaves, and carry them quickly to the camp for your brothers.
Nísinsin yìí Jese wí fún ọmọ rẹ̀ Dafidi pé, “Mú ìwọ̀n efa àti àgbàdo yíyan àti ìṣù àkàrà mẹ́wàá lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ kí o sì súré lọ sí ibùdó o wọn.
18 Also bring these ten cheeses to the captain of their thousand. See how your brothers are doing and bring back some proof that they are doing well.
Kí o sì mú wàrà mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún adarí ogun tiwọn. Wo bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe wà kí o sì padà wá fún mi ní àmì ìdánilójú láti ọ̀dọ̀ wọn.
19 Your brothers are with Saul and all the men of Israel in the Valley of Elah, fighting the Philistines.”
Wọ́n wà pẹ̀lú Saulu àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli ní àfonífojì Ela, wọ́n bá àwọn Filistini jà.”
20 David got up early in the morning and left the flock in the care of a shepherd. He took the supplies and left, as Jesse commanded him. He came to the camp as the army was going out to the battlefield shouting the war cry.
Ní àárọ̀ kùtùkùtù Dafidi fi agbo ẹran rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùtọ́jú, ó di ẹrù, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n gẹ́gẹ́ bí Jese ti sọ fún un. Ó dé ibùdó bí àwọn ọmọ-ogun ti ń lọ láti dúró ní ipò wọn ní ojú ogun, wọ́n hó ìhó ogun.
21 Then Israel and the Philistines lined up for battle, army against army.
Israẹli àti Filistini lọ sí ojú ìjà wọ́n da ojú ìjà kọ ara wọn.
22 David left his belongings with the keeper of supplies, ran to the army, and greeted his brothers.
Dafidi sì kó ẹrù rẹ̀ ti àwọn olùtọ́jú ohun èlò, ó sì sálọ sí ojú ogun ó sì kí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
23 As he talked with them, the strong man, the Philistine of Gath, Goliath by name, and he came out of the ranks of the Philistines, and said the same words as before, and David heard them.
Bí ó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, Goliati akíkanjú Filistini tí ó wá láti Gati bọ́ sí iwájú ní ojú ogun, ó sì kígbe fún ìpèníjà, Dafidi sì gbọ́.
24 When all the men of Israel saw the man, they fled from him and were very afraid.
Nígbà tí àwọn Israẹli rí ọkùnrin náà, gbogbo wọn sì sá fún un ní ìbẹ̀rù bojo.
25 The men of Israel said, “Have you seen this man who has come up? He has come to challenge Israel. The king will give great riches to the man who kills him, and he will give his daughter to him in marriage, and will make his father's house free from taxation in Israel.”
Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli wí pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò rí i bí ọkùnrin yìí ṣe ń jáde wá? Ó jáde wá láti pe Israẹli níjà. Ọba yóò fún ọkùnrin tí ó bá pa á ní ọrọ̀ púpọ̀. Yóò tún fi ọmọ rẹ̀ obìnrin fún un ní ìyàwó, yóò sì sọ ilé e baba rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú sísan owó orí ní Israẹli.”
26 David said to the men who stood by him, “What will be done for the man who kills this Philistine and takes away the disgrace from Israel? Who is this uncircumcised Philistine that he should defy the armies of the living God?”
Dafidi béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Kí ni a yóò ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá pa Filistini yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Israẹli? Ta ni aláìkọlà Filistini tí ó jẹ́ wí pé yóò máa gan ogun Ọlọ́run alààyè?”
27 Then the people repeated what they had been saying and told him, “So it will be done for the man who kills him.”
Wọ́n tún sọ fún un ohun tí wọ́n ti ń sọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí wọn yóò ṣe fún ọkùnrin tí ó bá pa á.”
28 Eliab his oldest brother heard when he spoke to the men. Eliab's anger was kindled against David, and he said, “Why did you come down here? With whom have you left those few sheep in the wilderness? I know your pride, and the mischief in your heart; for you have come down here so that you might see the battle.”
Nígbà tí Eliabu ẹ̀gbọ́n Dafidi gbọ́ nígbà tí ó ń bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀, ó bínú sí i, ó sì wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi sọ̀kalẹ̀ wá síbí? Àti pé ta ni ìwọ fi àwọn àgùntàn kékeré tókù ṣọ́ ní aginjù? Èmi mọ ìgbéraga rẹ, àti búburú ọkàn rẹ: ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá nìkan láti wòran ogun.”
29 David said, “What have I done now? Was it not just a question?”
Dafidi wí pé, “Kí ni mo ṣe nísinsin yìí? Ǹjẹ́ mo lè sọ̀rọ̀ bí?”
30 He turned away from him toward another, and spoke in the same way. The people answered the same thing as before.
Ó sì yípadà sí ẹlòmíràn, ó sì ń sọ̀rọ̀ kan náà, ọkùnrin náà sì dáhùn bí ti ẹni ìṣáájú.
31 When the words that David said were heard, soldiers repeated them to Saul, and he sent for David.
Àwọn ènìyàn gbọ́ ohun tí Dafidi sọ wọ́n sọ fún Saulu, Saulu sì ránṣẹ́ sí i.
32 Then David said to Saul, “Let no man's heart fail because of that Philistine; your servant will go and fight with this Philistine.”
Dafidi sọ fún Saulu pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí Filistini yìí, ìránṣẹ́ rẹ yóò lọ láti bá a jà.”
33 Saul said to David, “You are not able to go against this Philistine to fight with him; for you are only a youth, and he a man of war from his youth.”
Saulu sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ kò tó láti jáde lọ pàdé ogun Filistini yìí àti láti bá a jà; ọmọdé ni ìwọ, òun sì ti ń jagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”
34 But David said to Saul, “Your servant used to keep his father's sheep. When a lion or a bear came and took a lamb out of the flock,
Ṣùgbọ́n Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀. Nígbà tí kìnnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó.
35 I chased after him and attacked him, and rescued it out of his mouth. When he rose up against me, I caught him by his beard, struck him, and killed him.
Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á.
36 Your servant has killed both a lion and a bear. This uncircumcised Philistine will be like one of them, since he has challenged the armies of the living God.”
Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Filistini yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà.
37 David said, “Yahweh rescued me from the paw of the lion and from the paw of the bear. He will rescue me from the hand of this Philistine.” Then Saul said to David, “Go, and may Yahweh be with you.”
Olúwa tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu wí fún Dafidi pé, “Lọ kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
38 Saul clothed David with his armor. He put a helmet of bronze upon his head, and he clothed him with a coat of chainmail.
Saulu fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ wọ Dafidi, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìhámọ́ra ogun, ó sì fi ìbòrí idẹ kan bò ó ní orí.
39 David strapped his sword on his armor. But he was not able to walk, because he had not trained with them. Then David said to Saul, “I cannot go out to fight with these, for I have not trained with them.” So David put them off.
Dafidi si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára. Ó sọ fún Saulu pé, “Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára.” Ó sì bọ́ wọn kúrò.
40 He took his staff in his hand and chose five smooth stones out of the brook; he put them in his shepherd's pouch. His sling was in his hand as he approached the Philistine.
Nígbà náà, ó sì mú ọ̀pá rẹ̀ lọ́wọ́, ó ṣá òkúta dídán márùn-ún létí odò, ó kó wọn sí àpò olùṣọ́-àgùntàn tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kànnàkànnà, ó sì súnmọ́ Filistini náà.
41 The Philistine came and approached David, with his shield bearer in front of him.
Lákòókò yìí, Filistini pẹ̀lú ẹni tí ń gbé ìhámọ́ra ààbò wà níwájú rẹ̀, ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ Dafidi.
42 When the Philistine looked around and saw David, he despised him, for he was only a boy, and ruddy, with a handsome appearance.
Nígbà tí Filistini náà sì wo Dafidi láti òkè délẹ̀, ó sì rí i wí pé ọmọ kékeré kùnrin ni, ó pọ́n ó sì lẹ́wà lójú, ó sì kẹ́gàn an rẹ̀.
43 Then the Philistine said to David, “Am I a dog, that you come to me with sticks?,” and the Philistine cursed David by his gods.
Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni? Tí o fi tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọ̀pá?” Filistini sì fi Dafidi bú pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.
44 The Philistine said to David, “Come to me, and I will give your flesh to the birds of the heavens and to the beasts of the field.”
Filistini náà sì wí Dafidi pé, “Wá níbí, èmi yóò fi ẹran-ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ àti fún àwọn ẹranko tí ó wà nínú igbó!”
45 David replied to the Philistine, “You come to me with a sword, a spear, and a javelin. But I come to you in the name of Yahweh of hosts, the God of the armies of Israel, whom you have defied.
Dafidi sì wí fún Filistini pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí ìwọ tí gàn.
46 Today Yahweh will give me victory over you, and I will kill you and remove your head from your body. Today I will give the dead bodies of the Philistine army to the birds of the heavens and to the wild beasts of the earth, so that all the earth may know that there is a God in Israel,
Lónìí yìí ni Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Filistini fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko igbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Israẹli.
47 and that all this gathering may know that Yahweh does not give victory with sword or spear. For the battle is Yahweh's, and he will give you into our hand.”
Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà; ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ wa.”
48 When the Philistine rose and approached David, then David ran quickly toward the enemy army to meet him.
Bí Filistini ṣe súnmọ́ iwájú láti pàdé e rẹ̀. Dafidi yára sáré sí òun náà láti pàdé e rẹ̀.
49 David put his hand in his bag, took a stone from it, slung it, and hit the Philistine in the forehead. The stone sank into the Philistine's forehead, and he fell on his face to the ground.
Dafidi ti ọwọ́ sí àpò rẹ̀, ó sì mú òkúta jáde wá ó sì fì í, ó sì jù ú sí ọ̀kọ́kán iwájú orí Filistini. Òkúta náà sì wọ̀ ọ́ níwájú orí, ó sì ṣubú ó sì dojúbolẹ̀ ní orí ilẹ̀.
50 David defeated the Philistine with a sling and with a stone. He hit the Philistine and killed him. There was no sword in David's hand.
Dafidi yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistini pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, láìsí idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó lu Filistini, ó sì pa á.
51 Then David ran and stood over the Philistine and took his sword, drew it out of the sheath, killed him, and cut off his head with it. When the Philistines saw that their strong man was dead, they fled.
Dafidi sì sáré ó sì dúró lórí rẹ̀. Ó sì mú idà Filistini, ó sì fà á yọ nínú àkọ̀ ọ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa á tan, ó sì gé orí rẹ̀ pẹ̀lú idà. Nígbà tí àwọn ará Filistini rí i wí pé akọni wọn ti kú, wọ́n yípadà wọ́n sì sálọ.
52 Then the men of Israel and of Judah rose with a shout, and chased after the Philistines as far as the valley and the gates of Ekron. The dead Philistines lay along the way to Shaaraim, all the way to Gath and Ekron.
Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Israẹli àti ti Juda súnmọ́ iwájú pẹ̀lú ariwo, wọ́n sì lépa àwọn ará Filistini dé ẹnu ibodè Gati àti títí dé ẹnu ibodè Ekroni. Àwọn tí ó kú wà káàkiri ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà Ṣaaraimu àti títí dé ọ̀nà Gati àti Ekroni.
53 The people of Israel returned from chasing the Philistines, and they plundered their camp.
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli sì padà láti máa lé àwọn ará Filistini, wọ́n sì ba ibùdó wọn jẹ́.
54 David took the head of the Philistine and brought it to Jerusalem, but he put his armor in his tent.
Dafidi gé orí Filistini ó sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn ohun ìjà Filistini sínú àgọ́ tirẹ̀.
55 When Saul saw David go out against the Philistine, he said to Abner, the captain of the army, “Abner, whose son is this youth?” Abner said, “As you live, king, I do not know.”
Bí Saulu sì ti wo Dafidi bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Filistini, ó wí fún Abneri, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Abneri, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?” Abneri dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.”
56 The king said, “Ask those who might know, whose son the boy is.”
Ọba sì wí pé, “Wádìí ọmọ ẹni tí ọmọdékùnrin náà ń ṣe.”
57 When David returned from killing the Philistine, Abner took him, and brought him before Saul with the head of the Philistine in his hand.
Kété tí ó dé láti ibi tí ó ti lọ pa Filistini, Abneri sì mú u wá síwájú Saulu, orí Filistini sì wà ní ọwọ́ Dafidi.
58 Saul said to him, “Whose son are you, young man?” David answered, “I am the son of your servant Jesse the Bethlehemite.”
Saulu béèrè pé, “Ọmọdékùnrin, ọmọ ta ni ọ́?” Dafidi dáhùn pé, “Èmi ni ọmọ ìránṣẹ́ rẹ Jese ti Bẹtilẹhẹmu.”