< Exodus 39 >

1 Bezalel, Oholiab, and the other skilled workmen made the beautiful clothes for Aaron to wear while he did his work as a priest in the Holy Place. They made them from blue, purple, and red cloth, just as Yahweh had commanded Moses/me.
Nínú aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ibi mímọ́. Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
2 They made the sacred apron from fine white linen and from blue, purple, and red cloth.
Ó ṣe ẹ̀wù efodu wúrà, ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.
3 They hammered some thin sheets of gold and cut them into thin strips which they embroidered into the fine linen and into the blue, purple, and red cloth.
Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára, iṣẹ́ ọlọ́nà.
4 The apron had two shoulder straps, to join the front part to the back part at the shoulders.
Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù efodu náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so ó pọ̀.
5 A carefully-woven sash, which was made from the same materials as the sacred apron, was [sewn] onto the sacred apron. This was made exactly as Yahweh had commanded Moses/me.
Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù efodu ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
6 They cut two valuable onyx stones and enclosed them in a tiny gold frame, and a skilled gem-cutter engraved on the stones the names of the twelve sons of Jacob.
Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli.
7 They fastened the stones to the shoulder straps of the sacred apron, to represent the twelve Israeli tribes, exactly as Yahweh had commanded Moses/me.
Ó sì so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
8 They made the sacred chest pouch. They made it of the same materials as the sacred apron and embroidered it in the same way.
Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí ìgbàyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà. Ó ṣe é bí ẹ̀wù efodu: ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.
9 It was square, and the material was folded double, so that it was (9 in./22 cm.) long and (9 in./22 cm.) wide.
Igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé ìwọ̀n ìka kan ní ìnà rẹ̀, ìwọ̀n ìka kan ní ìbú rẹ̀, ó sì jẹ́ ìṣẹ́po méjì.
10 They fastened four rows of valuable stones onto the pouch. In the first row, they put a [red] ruby, a [yellow] topaz, and a [red] garnet.
Ó sì to ipele òkúta oníyebíye mẹ́rin sí i. Ní ipele kìn-ín-ní ní rúbì wà, topasi àti berili;
11 In the second row, they put a [green] emerald, a [blue] sapphire, and a [clear/white] diamond.
ní ipele kejì, turikuose, safire, emeradi àti diamọndi;
12 In the third row they put a [red] jacinth, a [white] agate, and a [purple] amethyst.
ní ipele kẹta, jasiniti, agate àti ametisiti;
13 In the fourth row, they put a [yellow] beryl, a [red] carnelian, and a [green] jasper. They set each of the stones in tiny gold frames.
ní ipele kẹrin, karisoliti, óníkìsì, àti jasperi. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn.
14 On each of the twelve stones they engraved the name of one of the sons of Jacob, to represent one of the twelve Israeli tribes.
Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá, ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.
15 They made two [chains] from pure gold and braided them like cords, to [attach] the sacred pouch [to the sacred apron].
Fún ìgbàyà náà, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n iṣẹ́ kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bi okùn.
16 They made two gold rings, and they attached them to the upper corners of the sacred pouch.
Wọ́n sì ṣe ojú ìdè wúrà méjì àti òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so àwọn òkúta náà mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà.
17 They fastened one end of each cord to one of the rings.
Wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì náà mọ́ àwọn òrùka náà ni igun ìgbàyà náà,
18 They fastened the other end of each cord to the two (settings/tiny frames) [that enclosed the stones]. Then they attached the sacred pouch to the shoulder straps of the sacred apron.
àti ní àwọn òpin ẹ̀wọ̀n tókù ni wọ́n fi mọ ojú ìdè méjèèjì, wọ́n so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà ní iwájú.
19 Then they made two more gold rings and attached them to the lower corners of the sacred pouch, on the inside edges, next to the sacred apron.
Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù efodu náà.
20 They made two more gold rings and attached them to the lower part of the front of the shoulder straps, near to where [the shoulder straps] were joined [to the sacred apron], just above the carefully-woven sash/waistband.
Wọ́n sì túnṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù efodu náà tí ó súnmọ́ ibi tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù efodu náà.
21 They tied the rings on the sacred pouch to the rings on the sacred apron with a blue cord, so that the sacred pouch was above the sash/waistband and would not come loose from the sacred apron.
Wọn so àwọn òrùka ìgbàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù efodu ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí ìgbàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù efodu náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
22 They made the robe that is to be worn underneath the priest’s sacred apron, using only blue [cloth].
Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù efodu gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ aláṣọ híhun,
23 It had an opening through which [the priest] would put his head. They sewed a border around this opening, to prevent the material from tearing.
pẹ̀lú ihò ní àárín ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya.
24 At the lower edge on the robe, they fastened [decorations that resembled] pomegranate fruit. The decorations were [woven from] blue, purple, and red yarn/thread.
Ó sì ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.
25 Between each of these decorations, they fastened a tiny bell made from pure gold, so there was a bell and a pomegranate, a bell and a pomegranate, alternating all around the hem of the robe
Ó sì ṣe agogo kìkì wúrà, ó sì so wọ́n mọ́ àyíká ìṣẹ́tí àárín pomegiranate náà.
26 for [Aaron to wear while] he did his work as a priest. They made all these things exactly as Yahweh had commanded Moses/me.
Ago àti pomegiranate kọjú sí àyíká ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
27 They wove long-sleeved tunics/gowns from fine white linen, for Aaron and his sons.
Fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ, wọ́n ṣe àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti ọ̀gbọ̀ dáradára tí iṣẹ́ aláṣọ híhun.
28 They also made a turban of fine linen [for Aaron to wear around his head]. They made the caps and the undershorts [for Aaron’s sons] from fine linen.
Àti fìlà ọ̀gbọ̀ dáradára, ìgbàrí ọ̀gbọ̀ àti aṣọ abẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.
29 They made the embroidered sash/waistband [for Aaron] from fine linen and from blue, purple, and red cloth, and they embroidered designs on it using blue, purple, and red yarn/thread, exactly as Yahweh had commanded Moses/me.
Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elése àlùkò àti òdòdó tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.
30 They also made the tiny ornament of pure gold and had a skilled workman engrave on it the words, ‘Dedicated to Yahweh’.
Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì: Mímọ́ sí Olúwa.
31 They fastened this to the front of the turban by a blue cord, just as Yahweh had commanded Moses/me.
Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
32 Finally they finished all the work to make the Sacred Tent. They brought to Moses/me all the things that they had made. They had made them exactly as Yahweh had commanded me.
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
33 They brought to him/me the Sacred Tent and all the things that were used with it: the hooks, the frames, the crossbars, the posts and their bases,
Wọ́n sì mú tabanaku náà tọ Mose wá: àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;
34 the coverings for the Sacred Tent that were made of tanned/dyed rams’ skins and goatskins, the curtains,
ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji aṣọ títa;
35 the sacred chest that contained the stone slabs [on which the commandments were written], the poles, the lid for the chest,
àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú;
36 the table with all the things that were used with it, the sacred bread [that was offered] to God,
tábìlì pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn;
37 the lampstand made of pure gold and all its lamps and all the things that were to be used to take care of it, the oil for the lamps,
ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà pẹ̀lú ipele fìtílà rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti òróró fún títanná rẹ̀;
38 the golden altar [for burning incense], the oil for anointing, the sweet-smelling incense, the curtain for the entrance to the Sacred Tent,
pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.
39 the bronze altar [for burning sacrifices] and its bronze grating, the poles [for carrying] it, and all the other things that were used with it, the washbasin and its base,
Pẹpẹ idẹ pẹ̀lú idẹ ọlọ, àwọn òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;
40 the curtains [that surrounded] the courtyard, the posts and bases that supported them, the curtain for the entrance to the courtyard and its ropes, the tent pegs, and all the other things that would be used in the Sacred Tent,
aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti àgbàlá, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá; ọ̀já àmùrè àti èèkàn àgọ́ fún àgbàlá náà; gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ fún àgọ́, àgọ́ àjọ náà;
41 the beautiful sacred clothes for Aaron to wear when he did his work in the Holy Place, and the special clothes for his sons to wear as they did their work as priests.
aṣọ híhun tí wọ́n ń wọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.
42 The Israeli people had done all this work exactly as Yahweh had commanded Moses/me.
Àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
43 Then Moses/I saw all the work that they had done. Truly, they had done everything exactly as Yahweh had commanded [that it should be done]. Then Moses/I [asked God to] bless them.
Mose bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Nítorí náà Mose sì bùkún fún wọn.

< Exodus 39 >