< Psalms 23 >
1 A Melody of David. Yahweh, is my shepherd—I shall not want:
Saamu ti Dafidi. Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2 In pastures of tender grass, he maketh me lie down, Unto restful waters, he leadeth me;
Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù, Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,
3 My life, he restoreth, He guideth me in right paths, for the sake of his Name.
Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò. Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.
4 Yea, though I walk through a valley death-shadowed, I will fear no harm, for, thou, art with me, Thy rod and thy staff, they, comfort me.
Bí mo tilẹ̀ ń rìn láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan, nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ, wọ́n ń tù mí nínú.
5 Thou spreadest before me a table, in face of mine adversaries, Thou hast anointed, with oil, my head, My cup, hath run over.
Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi. Ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
6 Surely, goodness and lovingkindness, will pursue me, all the days of my life, and I shall dwell in the house of Yahweh, evermore.
Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa títí láéláé.