< Leviticus 3 >
1 But, if a peace-offering, be his oblation, if, of the herd, he himself, be bringing near, —whether male or female, without defect, shall he bring it near before Yahweh.
“‘Bí ọrẹ ẹnìkan bá jẹ́ ọrẹ àlàáfíà, tí ó sì mú ẹran wá láti inú agbo màlúù yálà akọ tàbí abo, kí ó mú èyí tí kò ní àbùkù wá síwájú Olúwa.
2 Then shall he lean his hand upon the head of his oblation, and slay it at the entrance of the tent of meeting, —and the sons of Aaron the priests shall dash the blood against the altar round about,
Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.
3 Then shall he bring near out of the peace-offering, an altar-flame unto Yahweh, —the fat that covereth the inwards, and all the fat that is upon the inwards;
Láti ara ọrẹ àlàáfíà ni kí ẹni náà ti mú ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa, gbogbo ọ̀nà tí ó bo nǹkan inú ẹran náà àti gbogbo ọ̀rá tí ó so mọ́ wọn.
4 and the two kidneys, and the fat which is upon them, which is upon the loins, —and the caul upon the liver, upon the kidneys, shall he remove it.
Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti gbogbo ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.
5 Then shall the sons of Aaron make thereof a perfume at the altar, upon the ascending-sacrifice which is on the wood, which is on the fire, —an altar-flame of a satisfying odour unto Yahweh.
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
6 But, if out of the flock, be his oblation for a peace-offering unto Yahweh, whether male or female—without defect, shall he bring it near.
“‘Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù.
7 If a young sheep, he himself, be bringing near as his oblation, then shall he bring it near, before Yahweh.
Bí ó bá ṣe pé ọ̀dọ́-àgùntàn ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.
8 And he shall lean his hand upon the head of his oblation, and shall slay it before the tent of meeting, —and the sons of Aaron shall dash the blood thereof against the altar round about.
Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Aaroni wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.
9 Then shall he bring near out of the peace-offering, an altar-flame unto Yahweh, the fat thereof the fat-tail thereof entire close to the backbone, shall he remove it, —and the fat that covereth the inwards, and all the fat that is upon the inwards;
Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa; ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí; àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun.
10 and the two kidneys, with the fat that is on them, which is on the loins, —and the caul that is on the liver, on the kidneys, shall he remove it.
Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí o yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.
11 Then shall the priest make a perfume, at the altar, —the food of an altar-flame, unto Yahweh.
Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
12 But if a goat, be his oblation, then shall he bring it near, before Yahweh.
“‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.
13 And he shall lean his hand upon its head, and shall slay it before the tent of meeting, —and the sons of Aaron shall dash its blood against the altar, round about.
Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí. Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.
14 Then shall he bring near therefrom as his oblation an altar-flame unto Yahweh, —the fat that covereth the inwards, and all the fat that is upon the inwards;
Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ẹbọ sísun fún Olúwa, gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn.
15 and the two kidneys, and the fat that is on them which is on the loins, —the caul upon the liver, on the kidneys, shall he remove it.
Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.
16 Then shall the priest make a perfume at the altar, —the food of an altar-flame for a satisfying odour, —all the fat—unto Yahweh.
Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti Olúwa.
17 An age-abiding statute to your generations, in all your dwellings, —none of the fat nor of the blood, shall ye eat.
“‘Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ìran tó ń bọ̀, ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀.’”