< Jonah 4 >
1 And it was vexing unto Jonah, with a great vexation, —and it angered him.
Ṣùgbọ́n ó ba Jona nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀.
2 So he prayed unto Yahweh, and said—Ah now! Yahweh! Was not, this, my word, while I was yet upon mine own soil? For this cause, did I hasten to flee unto Tarshish, —because I knew that, thou, art a GOD of favour and compassion, slow to anger, and abundant in lovingkindness, and art grieved over calamity.
Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà.
3 Now, therefore, O Yahweh, take, I pray thee, my life from me, —for it were better for me, to die, than, to live.
Ǹjẹ́ báyìí, Olúwa, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”
4 Then said Yahweh, Art thou rightly angry?
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”
5 But Jonah, went forth, out of the city, and abode on the east side of the city; and made for himself there, a hut, and sat under it, in the shade, until he should see what would become of the city.
Jona sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni òjìji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.
6 Now Yahweh God appointed a gourd, and caused it to come up over Jonah, that it might be a shade over his head, to deliver him from his vexation, —and Jonah rejoiced over the gourd, with great rejoicing.
Olúwa Ọlọ́run sì pèsè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jona; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jona sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà.
7 But God appointed a worm, at the uprisings of the dawn, the next day, —and it smote the gourd, that it withered.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ.
8 And it came to pass, at the breaking forth of the sun, that God appointed a sultry east wind, and the sun smote upon the head of Jonah, that he became faint, —and asked his life, that he might die, and said, It were better for me, to die, than, to live.
Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”
9 Then said God unto Jonah, Art thou rightly angry over the gourd? And he said, I am rightly angry, unto death.
Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?” Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”
10 Then said Yahweh, Thou, wouldest have spared the gourd, for which thou hadst not toiled, neither hadst thou made it grow, —which, as the off-spring of a night, came up, and, as the offspring of a night, perished;
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.
11 And was not, I, to spare Nineveh, the great city, —wherein are more than twelve times ten thousand human beings, who cannot discern between their right hand and their left, besides much cattle?
Ṣùgbọ́n Ninefe ní jù ọ̀kẹ́ mẹ́fà ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ìlú ńlá náà?”