< Job 21 >

1 Then responded Job, and said: —
Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé,
2 Hear ye patiently my words, and let this be your consolation:
“Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi.
3 Suffer me, that, I, may speak, and, after I have spoken, thou canst mock!
Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo.
4 Did, I, unto man, make my complaint? Wherefore, then, should my spirit not be impatient?
“Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí? Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?
5 Turn round to me, and be astonished, and lay hand on mouth!
Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín, kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.
6 When I call to mind, then am I dismayed, and there seizeth my flesh a shuddering: —
Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí, ìwárìrì sì mú mi lára.
7 Wherefore do, lawless men, live, advance in years, even wax mighty in power?
Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?
8 Their seed, is established in their sight, along with them, yea their offspring, before their eyes;
Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn.
9 Their houses, are at peace, without dread, neither is, the rod of GOD, upon them;
Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.
10 His bull, covereth, and causeth not aversion, His cow safely calveth, and casteth not her young;
Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun.
11 They send forth—like a flock—their young ones, and, their children, skip about for joy;
Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.
12 They rejoice aloud as [with] timbrel and lyre, and make merry to the sound of the pipe;
Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu; wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.
13 They complete, in prosperity, their days, and, in a moment to hades, they sink down. (Sheol h7585)
Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà. (Sheol h7585)
14 Yet they said unto GOD, Depart from us, and, In the knowledge of thy ways, find we no pleasure.
Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’ Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.
15 What is the Almighty, that we should serve him? Or what shall we profit, that we should urge him?
Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?
16 Lo! not in their own hand, is their welfare, The counsel of lawless men, is far from me!
Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré.
17 How oft, the lamp of the lawless, goeth out, and their calamity, cometh upon them, Sorrows, apportioneth he in his anger;
“Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú? Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?
18 They become as straw before the wind, and as chaff, which the storm stealeth away.
Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ.
19 Shall, GOD, reserve, for his children, his sorrow? Let him recompense him so that he may know it;
Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.
20 His own eyes, shall see his misfortune, and, the wrath of the Almighty, shall he drink.
Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀, yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.
21 For what shall be his pleasure in his house after him, when, the number of his months, is cut in twain?
Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?
22 Is it, to GOD, one can teach knowledge, seeing that, he, shall judge, them who are on high?
“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀? Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.
23 This, man dieth, in the very perfection of his prosperity, wholly tranquil and secure;
Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀, ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá.
24 His veins, are filled with nourishment, and, the marrow of his bones, is fresh;
Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú, egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.
25 Whereas, this other man, dieth, in bitterness of soul, and hath never tasted good fortune:
Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun.
26 Together, in the dust, they lie down, and, the worm, spreadeth a covering over them.
Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.
27 Lo! I know your plans, and the devices, wherewith ye would do me violence!
“Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.
28 For ye say, Where is the house of the noble-minded? And where the dwelling-tent of the lawless?
Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé, àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’
29 Have ye not asked the passers-by in the way? And, their signs, can ye not recognise?
Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà? Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn,
30 That, to the day of calamity, is the wicked reserved, to the day of indignant visitation, are they led.
pé ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun. A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.
31 Who can declare—to his face—his way? And, what, he, hath done, who shall recompense to him?
Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?
32 Yet, he, to the graves, is borne, and, over the tomb, one keepeth watch;
Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.
33 Pleasant to him are the mounds of the torrent-bed, —and, after him, doth every man march, as, before him, there were without number.
Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn. Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.
34 How then should ye comfort me with vanity, since, as for your replies, there lurketh, [in them] treachery?
“Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán, bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”

< Job 21 >